Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Gómìnà Edo, Okpebholo fi ní kí Peter Obi má wọ ìpínlẹ̀ náà, èyí tó ń fa awuyewuye lórí ayélujára

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Láti bíi ọjọ́ méjì báyìí ni awuyewuye ti ń wáyé láàárín gómínà ìpínlẹ̀ Edo, Monday Okpebholo àti olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi.

Gómìnà Okpebholo ti wá jáde báyìí pé òun kò dúnkokò mọ́ Peter Obi látàrí àbẹ̀wò tó ṣe sí ìpínlẹ̀ Edo báwọn ìròyìn kan ṣe ń gbe.

Ní ọjọ́ Keje, oṣù Keje ọdún 2025 ni Peter Obi ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn ìkọ́ni St Philomena Hospital School of Nursing Sciences tó sì fún wọn ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún náírà (₦15m) láti fi parí àkànṣe iṣẹ́ tó ń lọ nílé ẹ̀kọ́ náà.

Àmọ́ gómìnà Edo, Monday Okpebholo bu ẹnu àtẹ́ lu àbẹ̀wò Peter Obi náà tó sì tẹmpẹlọmọ pé àbẹ̀wò rẹ̀ ṣokùnfà àwọn ìwà ìpáǹle ní ìpínlẹ̀ náà.

Lẹ́yìn náà ló ṣèkìlọ̀ fún Peter Obi pé kò gbọdọ̀ wọ ìpínlẹ̀ ọ̀hún mọ́ láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba tàbí kó fojú winá òfin.

Falana, ADC bu ẹnu àtẹ́ lu Okpebholo

Ọ̀rọ̀ tí Okpebholo sọ yìí fa awuyewuye, táwọn èèkàn ìlú sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu Okpebholo fún ọ̀rọ̀ náà pé níṣe ló ń dúnkokò mọ́ ẹ̀mí Peter Obi àti pé kìí ṣe ohun tó dára fún ìsèjọba àwaarawa.

Lára àwọn tó bu ẹnu àtẹ́ lu gómìnà Okpebholo ni gbajúmọ̀ agbẹjọ́rò Femi Falana, tó sì rọ Peter Obi láti gbé ìgbésẹ̀ òfin tako gómìnà náà.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Falana fi léde lọ́jọ́ Àìkú wòye pé ìdúnkokò tí gómìnà Okpebholo ṣe sí ẹ̀mí Peter Obi tako abala kẹtàlélọ́gbọ̀n ìwé òfin Nàìjíríà tọdún 1999.

"Tí Gómìnà Okpebholo kò bá kó ìdúnkokò sí ẹ̀mí Peter Obi tó ṣe, Peter Obi nílò láti gba ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Edo láti bèèrè fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn rẹ̀.

"Obi gbọdọ̀ tètè gbé ìgbésẹ̀ náà ní kíákíá pẹ̀lú gbogbo báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn, tí wọ́n máa pa èèyàn bó ṣe wù wọ́n," Falana sọ.

Bákan náà ni akọ̀wé ìpolongo fẹ́gbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC Bolaji Abdullahi nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé irú ìgbésẹ̀ Okpebholo ti ń wọ́pọ̀ láàárín àwọn gómìnà tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé ohun tí ẹgbẹ́ òṣèlú náà ń sọ fún àwọn èèyàn Nàìjíríà ni pé wọn kò ní ẹ̀tọ́ láti rìn sí ibi tó bá wù wọ́n ní Nàìjíríà.

"Èyí kìí ṣe ìjọba àwaarawa, ó sì jẹ́ ohun tó burú. Orílẹ̀ èdè tó yẹ kí èèyàn tí ni òmìnira ní Nàìjíríà, oníkálukú ló sì lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ sí ibikíbi tó bá wù wọ́n ní orílẹ̀ èdè yìí.

"A ò nílò láti gba físà ní orílẹ̀ èdè wa. A ò nílò àṣẹ ẹnikẹ́ni láti lọ sí ibi tó bá wù wá ní apa ibikíbi ní Nàìjíríà."

Abdullahi fi kun pé nígbà tí APC kò rí Nàìjíríà sọ di orílẹ̀ èdè ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan ṣoṣo ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dúnkokò mọ́ àawọn èèyàn láti má dè é ìpínlẹ̀ kan tàbí òmíràn.

Wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ gómìnà tú ni - ìjọba Edo

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Edo ti wá fèsì sáwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kàn wọ́n lórí ọ̀rọ̀ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ gómìnà Okpebholo, Fred Itua fi síta ṣàlàyé pé ohun tí gómìnà ń jà fún ni ètò ààbò tí kò sì dúnkokò mọ́ ẹnikẹ́ni.

Ó ní kò yẹ kí ẹnikẹ́ni tú ọ̀rọ̀ náà sí ìdúnkokò àti pé onírúurú ìtumọ̀ láwọn èèyàn ń fún ọ̀rọ̀ tí gómìnà sọ lórí àbẹ̀wò Peter Obi sí ìpínlẹ̀ Edo.

"Ó pọn dandan láti ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé gómìnà kò dúnkokò mọ́ Peter Obi bíkòṣe pẹ ìjọba ń tẹmpẹlẹmọ pé àwọn èèkàn ìlú pàápàá àwọn tó bá ti wà lágbo òṣèlú nílò láti gba ìyọ̀nda ìjọba pàápàá lórí ààbò kí wọ́n tó ṣe ìpàdé ìtagbangba.

"Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà fún ètò ààbò, òjuṣé gómìnà ni láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá fún gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ náà tó fi mọ́ àwọn àlejò.

"Ojúṣe yìí kún ṣíṣe àrídáju rẹ̀ pé àwọn ìpèsè ohun ààbò tó yẹ wà nílẹ̀ nígbà táwọn èèkàn ìlú bá fẹ́ ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ náà tàbí ayẹyẹ ńlá tí èrò máa pọ̀ níbẹ̀."

Itua fi kun pé ipò gómìnà kò ṣẹ̀yìn ìkọlù tó ń peléke si ní ìpínlẹ̀ Edo àti bí wọ́n ṣe ń jí àwọn èèyàn gbé ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó sọ pé bó ṣe jẹ́ pé pípèsè owó fáwọn ilé ìjọsìn, ilé ìwòsàn àtàwọn àjọ jẹ́ ìwà tó dára, ó gba ṣíṣe pẹ̀lú ọgbọ́n àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti títẹ̀lé àwọn ìlànà tó yẹ láti ri pé wọn kò kó àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn sínú ewu.

"Gómìnà Okpebholo kìí ṣe Peter Obi tó fi gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai sí àhámọ́ nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra.

Ṣùgbọ́n adarí ikọ̀ Obidient Movement Yunusa Tanko sọ pé kìí ṣe Peter Obi ló fi El-Rufai sí àhámọ́ nígbà náà bíkòṣe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Àwọn ìgbà tí wọ́n ní kí èèkàn ìlú má wọ ìpínlẹ̀ kan

Ọdún 2022 ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Nasir El-Rufai fẹ̀sùn kan Peter Obi pé nígbà tó wà nípò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra lọ́dún 2013 sọ pé kí wọ́n fi òfin gbé òun tí òun sì wà ní àhámọ́ fún ọjọ́ méjì.

El-Rufai ní Peter Obi tó jẹ́ gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Grand Alliance (APGA) nígbà náà ní òun lọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lásìkò náà ni Peter Obi ní kí wọ́n fi òun sí àhámọ́ ní yàrá ilé ìtura tí òun wà.

Àmọ́ Tanko jiyàn ẹ̀sùn náà pé òun wà ní Anambra nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé àti pé ẹgbẹ́ òṣèlú ló wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé wọ́n rò pe El-Rufai kówó wọ ìpínlẹ̀ Anambra nígbà náà láti fi ṣi àwọn olùdìbò lọ́kàn ni.

Bákan náà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi fòfin de ṣíṣe àpéjọ ìtagbangba ní oṣù Kẹrin nígbà tí Sẹ́nétọ̀ Natasha Akpoti-Uduaghan fẹ́ ṣe ayẹyẹ ọdún ìtunu àwẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi, Kingsley Fanwo fi síta nígbà náà sọ pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí ààbò ni.

Ìgbésẹ̀ náà ló wáyé lásìkò tí Natasha ń ní ìfaǹfà pẹ̀lú ilé aṣòfin àgbà tí wọ́n sì ní kó lọ rọ́kún nílé.

Natasha nígbà náà ló ọkọ̀ òfurufú láti kópa níbi àpéjọ náà nígbà tí wọ́n kò jẹ́ kó rí ọ̀nà gbà kọjá.