Juliet Ukah, obìnrin ọlọ́pàá tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà lágbáyé

Juliet Ukah, obìnrin ọlọ́pàá tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà lágbáyé

Ọlọpaa Naijiria ni arabinrin Juliet Ukah ṣugbọn ti o tun n ja ẹṣẹ pẹlu.

Ere idaraya afẹṣẹ ati ipa ja ti awọn oyinbo n pe ni Mixed Martial Art ni o yan laayo lẹnu iṣẹ rẹ.

Juliet kọkọ gbiyanju ere sisa ṣugbọn ti ko ṣ'ẹnuure fun un ki o to ya bara si ẹṣẹ ati ipa jija.

"Nigba ti mo wa ni kekere, mo maa n wo awọn eekan bii Ajunwa ati Sunday Bada, ti wọn jẹ ọlọpaa ti wọn si tun jẹ elere idaraya. Eyi jẹ iwuri fun mi to si jẹ ki emi naa sọ pe bi awọn eeyan wọnyi ba le ṣe e, emi naa a le ṣe e."

Ija mẹfa lo ti ti kopa ninu rẹ, mẹfẹẹfa lo si ti bori.

O ni oun n lo irinajo oun lati ṣe koriya fun awọn obinrin ki wọn lee maa gbaradi daadaa fun awọn ọna lati daabo bo ara wọn lọwọ ewu ati ipalara.