“Lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n fi ipá bá ọmọ mi ọmọ odún mẹ́ta lòpọ̀, mò ń wá ìdájọ́ òdodo”

    • Author, Tyson Conteh & Tamasin Ford
    • Role, BBC Africa Eye, Makeni & London

Ọdun 2019 ni Aarẹ Sierra Leone, Julius Maada Bio, kede ilu ofararọ lẹyin iṣẹlẹ ifipabanilopọ kan nibẹ.

Ọdun marun un lẹyin iṣẹlẹ naa, ẹka BBC Africa Eye ṣewadii boya awọn ti ọrọ ifipabanilopọ kan ti ri idajọ ododo gba.

Ikilọ: Awọn nnkan to wa ninu iroyin yii le ba ọ ninu jẹ.

Ni ilu Makeni, to jẹ nnkan bii wakati mẹta si ilu Freetown, to jẹ olu ilu orilẹede naa ni obinrin kan wa pẹlu ọmọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹta pere.

Obinrin ọhun, Anita (kii ṣe orukọ abisọ rẹ) ṣapejuwe bo ṣe ba ọmọ rẹ kekere jojolo pẹlu ẹjẹ ninu awọtẹlẹ rẹ.

Lasiko to n ṣalaye bo ṣe fi ọmọ rẹ silẹ pẹlu obinrin to gba a siṣẹ ati ọmọ obinrin naa to jẹ ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun o ni “Mo n ṣiṣẹ fun obinrin kan, o si ranmi niṣẹ laarọ ọjọ Abamẹta pe ki n lọ si ọja’

“Ọmọ rẹ ọkunrin naa gbe ọmọ mi, o si sọ pe oun fẹ lọ ra ipapanu fun, ṣugbọn irọ ni.”

Lẹyin ti Anita pada de lati ọja lo ba ọmọ rẹ ọhun ninu agbara ẹjẹ to si gbe digabdigba lọ sile iwosan.

Ile iwosan naa ni awọn dokita ti sọ pe wọn ti fi ipa ba ọmọde naa lopọ.

Anita lọ fi ọrọ naa sun ni agọ ọlọpaa, amọ afurasi ọhun na papa bora, ọlọpaa ṣi n tọpinpin rẹ, wọn ko si tii ri mu lati ọdun kan sẹyin.

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ orilẹede naa ti ṣe ofin to wọn ijiya nla fun ẹnikẹni to ba ni ibalopọ pẹlu ọmọde, Anita ni inu oun bajẹ pe ẹni to fi ipa ṣi aṣọ ọmọ oun wo ko tii jiya to tọ labẹ ofin.

Iroyin bi wọn ṣe fi ipa ba ọmọde mii lopọ tun migboro titi nilẹ naa lọdun 2018.

Iroyin sọ pe apa kan ọmọde naa rọ ti ko si le rin mọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun, eyii to bi awọn araalu ninu.

Lẹyin ti Aarẹ kede ilu ofararọ fun odidi oṣu mẹrin nitori ifipabanilopọ, ile aṣofin ṣe atunṣe ofin ilẹ ọhun lati fi ọpalamba iya jẹ ẹni to ba dna iru nnkan bẹẹ wo.

Pẹlu ofin tuntun ọhun, ẹni ti ọrọ naa ba ṣi mọ lori le ṣẹwọn ọdun mẹẹdogun, tabi ko ṣẹwọn gbere to ba jẹ pe ọmọde ni wọn ba lopọ.

Wayi o, iroyin ni iṣẹlẹ ifipabanilopọ ti dinku ni ida 17% laarin ọdun 2018 si 2023.

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ‘Rainbo Initiative’ ida 2% ninu ifipabanilopọ 2,705 pere lo de ile ẹjọ to ga julọ.

Ni agọ ọlọpaa ti Anita ti lọ fi ọrọ ọmọ rẹ lọ, awọn ọlọpaa to wa nibẹ sọ pe ẹjọ bẹẹ bii mẹrin lo maa n de ọdọ awọn laarin ọsẹ kan.

Ṣugbọn wọn ni iṣoro ti awọn n koju ni pe ko si ọkọ ti awọn yoo gbe lọ lati lọ mu afurasi.

Ọlọpaa to ba BBC sọrọ nibẹ, ti agọ ọlọpaa meje wa labẹ rẹ ṣalaye pe ko si eyi to ni ọkọ ninu agọ ọlọpaa mejeje ti oun n ṣakoso.

Nigba ti BBC kan si minisita eto iroyin, Chernor Bah, o ni awọn ko tii tan iṣoro ifipabanilopọ nilẹ naa amọ awọn n sa ipa awọn.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn kan ko tii ri idajọ ododo gba, awọn n ṣe aṣeyọri lori awọn igbesẹ ti ijọba n gbe lori ọrọ ọhun.

Ni ti Anita, o ti le lọdun kan ti wọn fi ipa ja ibalẹ ọmọ rẹ kekere ọmọ ọdun mẹta.

Lẹyin ti ko ni ireti kankan lati ọdọ awọn ọlọpaa, o ti bẹrẹ si n fi aworan afurasi naa lede loju opo Facebook funra rẹ.

O ni “mo n fẹ ki awọn eeyan ba mi wa ọmọkunrin naa ri, inu mi ko dun rara, inu ibanujẹ ni mo wa.

“Nnkan to ṣẹlẹ si ọmọ mi, mi o fẹ ko ṣẹlẹ si ọmọ ẹlomiran.”