Ẹ̀yin aráàlú ẹ ṣọ́ra fún mímu Sprite 50cl, a rí àbàwọ́n nínú rẹ̀ – NAFDAC

Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati idabobo ounjẹ fun awọn araalu, NAFDAC ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun mimu ohun ẹlẹrindodo Sprite 50cl to n kaakiri ni orilẹede Naijiria.

NAFDAC oni ohun ẹlẹrindodo naa ni awọn ri pe o ti ni abawọn lẹyin ti onibara kan fi ẹsun kan, ti awọn si sewadii ẹsun naa.

Ajọ naa ni iwadii awọn fihan pe crate to le ni marun un ninu Sprite 50cl ti wọn ko jade nigba naa ni o ni idọti ninu rẹ.

A ti sewadii awọn eleyii ti ko dara nibẹ ni awọn ileeṣẹ wa to si fidi mulẹ pe abawọn wa ninu awọn kọọkan.

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn ti kesi awọn adari ni ipinlẹ kọọkan lati se ayẹwo awọn Sprite 50cl to wa ni agbegbe wọn.

NAFDAC kede pe awọn ti kesi ileeṣẹ Coca -Cola lati kyisi iye ti ileesẹ imọ ẹrọ Abuja Plant pẹlu ami idanimọ AZ6 22:32.

O fikun un Ọjọ Kẹta, Osu Kẹrin odun yii ni wọn se awọn Bitter Lemon to ni abawọn naa.

NAFDAC wa kesi awọn ọlọja ati onibara lati se suuru , ki wọn si wo finifini ki wọn to mu Sprite.

‘’Ẹ gbọdọ yẹ ara rẹ wo daradara, ki ẹ sim ọ pe kii se eleyii yi ti ko dara.

Bakan naa ni wọn kesi ẹni to b ani eleyii ti ko dara yii lọwọ, ki o gbelọ si ileesẹ ajọ NAFDAC to ba sun mọ wọn.

Ajọ NAFDAC warọwa si awọn araalu ti wọn ba ti mu Sprite yii, ti o si ti gbodi lara wọn, ki wọn lọ si ilewosan fun itọju to peye.