You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbẹjọ́rò ‘Tani Olohun?’ kùnà láti farahàn níléẹjọ́ láàrín awuyewuye ikọ̀ aṣojú rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́
Aifarahan Ademola Banks ti o jẹ ọkan lara awon agbẹjọro Abdulazeez Adegbọla ti inagi jẹ rẹ jẹ Tani Ọlọhun, ni ile ẹjọ Majisireeti loni ọjọbọ ti sokun fa, idaduro fun gbigba beeli tabi oniduro fun onisẹse naa
Tẹ o ba gbagbe ni igbẹjọ to kọja, Adajọ, Magistrate Muhammed Ibrahim sọ pe Tani-Ọlọhun yoo ni lati tọka si agbẹjọro rẹ gangan ninu Muftau Olobi ati Ademola Banks
Ni ibẹrẹ igbẹjọ toni, Olobi jẹ ko di mimọ fun ile ẹjọ lori bi Banks ko ṣe si ni ibi igbẹjọ naa
Magistrate Ibrahim koro oju si ọrọ náà, o si sun igbẹjọ si ọla, ogunjọ osu yii ti awon agbẹjọro mejeji yoo wa ni ijoko, ti olujẹjọ naa yoo si sọ ẹni to fẹ ko tẹsiwaju lori ẹjọ ohun.
Ẹ̀fú n béèdì? Àwọn agbẹjọ́rò ‘Tani Ọlọhun’ méjèèjì tako ara wọn níléẹjọ́
Kayefi nla ni ọrọ jẹ ni ileẹjọ Majisireeti to kalẹ si'luu Ilọrin lọjọ Iṣẹgun lori bi awọn agbẹjọro meji to jade fun gbajumọ agbẹsin ibilẹ ga ni, Abdulazeez Adegbọla ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Tani Ọlọhun?’ se bẹrẹ si ni i tako ara wọn niwaju ile ẹjọ ọhun.
Agbẹjọro Muftau Olobi lo fi iwe kan sọwọ si ile ẹjọ lorukọ ‘Tani Ọlọhun’ ninu eyi to ti ṣalaye pe, olujẹjọ naa ti bẹ awon ti fidio to fi si ori ayelujara ta ẹrẹ ba.
Agbẹjọro naa si ni oun n bẹbẹ fun beeli fun ‘Tani Ọlọhun’ labẹ igbesẹ tuntun yii.
Ileẹjọ kọ lati gba ẹbẹ fun beeli naa.
Ohun ti ile ẹjọ naa sọ ni pe, oun tun ri iwe miran gba lọwọ agbẹjọro Ademola Bank ti oun pẹlu n ṣoju fun olujẹjọ naa, pe ko si igba kankan to beere fun aforiji lọwọ ẹnikẹni tabi ẹgbẹjẹgbẹ kankan.
Adajọ ile ẹjọ Majisireeti ọhun, Muhammed Ibrahim sọ pe iwe atako naa tumo si pe, ileẹjọ ohun ko ni agbara ati asẹ lati gbọ ẹjọ naa ti o n lọwọ.
O ni ohun ti ofin sọ ni pe ki ile ẹjọ kọkọ joko lori iwe atako to ba wa ni iwaju rẹ naa ki wọn to gbọ ẹbẹ fun beeli, tabi ki ‘Tani Ọlọhun’ fun ara rẹ wa si ileẹjọ ko si fi ẹnu ara rẹ sọ agbẹjọro to fẹ ko tẹsiwaju lati ṣoju fun oun ninu awon agbẹjọro mejeeji.
Adajọ Ibrahim wa sun igbẹjọ miran si ọjọbọ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹwaa.
Ọgbẹni Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si ‘tani ọlọhun?’ ti lo ọjọ mejilelọgọta ni ahamọ lẹyin ti wọn pe e lẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti awọn ẹgbẹ kan nilu Ilọrin pe e.
Ile ẹjọ majisireeti ni ilu Ilọrin yoo joko lori lonii ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa lori iwe ẹbẹ ti Tani Ọlọhun kọ si awon to pe e lẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Ni ọjọ kẹfa oṣu ti a wa yii ni Tani Ọlọhun fi ọwọ ara rẹ kọ iwe ẹbẹ kan to buwọlu, o si tun paṣẹ fun agbẹjọro rẹ Muftau Olobi lati kọ iwe ẹbẹ omiran ni orukọ rẹ ti wọn si fi ransẹ si agbẹjọro awọn olupẹjọ, Usman Saad Imam.
Olobi jẹ agbẹjọro akọkọ to duro fun Tani Ọlọhun ni ọjọ kẹtadinlogun osu kẹjọ nigba ti wọn kọkọ gbe wa sile ẹjọ.
Ninu iwe ẹbẹ ti o kọ, o darukọ ẹgbẹ ti a mo si Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin, Ogo Ilorin ati gbogbo awọn ẹlẹsin musulumi lagbaaye wi pe ki wọn foriji onibara oun.
Ti ẹ o ba gbagbe, mama olujẹjọ ọun, Nafisat Adegbọla ti kọkọ rawọ ẹbẹ si awọn olupẹjọ pẹlu omije loju wi pe ki wọn fi ọmọ oun silẹ ni alaafia.
Lonii la o mọ boya awọn olupẹjọ ti ṣetan lati foriji in tabi wọn yoo fariga lori ẹjọ naa.