Ọkọ àfẹ́sọ́nà mi tẹ́lẹ̀ ló gbé fọ́nrán ìhòòhò mi jáde - Moyo Lawal

Gbajugbaja oṣere tiata, Moyo Lawal ti sọrọ sita lori fọnran kan to wa lorí ayelujara eyi to safihan ihoho rẹ ati ibalopọ rẹ pẹlu ọkunrin kan.

Lawal salaye pe ọkọ afẹsọna ohun tẹlẹ ni ọkunrin to gbe fọnran naa sita sori ayelujara.

"Mo fẹ jẹ ko di mimọ pe fọnran kan tí mo ṣe pẹlu ọkọ afẹsọna mi tẹlẹ ko ki i se nnkan to yẹ ko bọ sori ayelujara ati pe igbesẹ yii tabuku si mi "

Ninu ọrọ to gbe sori ayelujara, o salaye bí nnkan ṣe lọ lẹyin ti fọnran naa bọ si ori ayelujara.

"Nnkan ti mo le sọ fun yín to da mi loju ni pe nnkan ko yẹ ko ri bo se ri. Ẹ meji pere ni mo ni ibasepọ lọdun to kọja, ẹyọ kan nibẹ ni fọnran to bo sori ayelujara

"Mo gba ko ya fọnran yii nitori mo mọ pe ko gbe lorilẹede Naijiria.

"O sisẹ karakara lati jẹ ki n fi ọkan tan ohun fun ọpọlọpọ ọdun to jẹ pe a ti jọ lero lati ra ile, ṣe igbeyawo ati awọn nnkan mii."

Lawal tun mu ẹnu bọ ọrọ kan to wa lori ayelujara pe oun gan gan lo gbe fọnran naa jade.

"Fun awọn to ni ẹmi ni mo mọ mọ gbe fọnran naa jade, n ko ni nnkan ti mo fẹ sọ fun yin.

"Wọn ní nnkan ti ko ba pa eeyan ma mu eeyan la gbára sì ni. Gbogbo awọn to ṣe eyi, mo fẹ sọ fun yín pe n ko ti sọ ireti nu. Mo duro digbi "