You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbankọgbì ọ̀rọ̀ tí Tunde Bakare sọ nípa ìbò 2023 tó da orí ayélujára rú
Lati alẹ ọjọ Aiku, ni olori ijọ Citadel Global Community Church, to tun jẹ oludije ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu Apc fun ipo aarẹ 2023, Pasitọ Tunde Bakare,
Eyi ko ṣẹyin awọn ọrọ kan to sọ nipa eto idibo gbogboogbo ọdun 2023.
Awọn ọrọ naa jẹyọ ninu ọrọ to ba ‘gbogbo ọmọ Naijiria’ sọ nile ijọsin rẹ to wa ni agbegbe Ikeja, nipinlẹ Eko.
Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to pe akọle rẹ ni “didi alafo to wa laarin oṣelu ati ijọba”,
Tunde Bakare ṣapejuwe oṣelu to n tuka, ẹ̀tàn, alọnilọwọ gba, iyanjẹ, ọdalẹ, ibanilorukọ jẹ, didẹru ba ni, ipaniyan ati imọtara ẹni nikan, gẹgẹ bi oṣelu buruku.
‘Iwa imọta ẹni nikan ni oṣelu Emi lo kan’
Pasitọ Tunde Bakare sọ pe oṣelu lati fi agidi de ipo, bo tilẹ jẹ pe ko bojumu, kii ṣe oṣelu gidi.
O ni oṣelu dandan ni ko jẹ emi, tun ma n farahan ninu ki eeyan ma a dije fun aimọye igba, lai ni erongba lati sin ilu, ṣugbọn nitori ati tẹ ifẹ ara ẹni lọrun.
“O tun le farahan ninu ki eeyan fẹ ipo oṣelu gẹgẹ èrè fun oore manigbagbe ti ẹnikan ro pe oun ṣe fun orilẹ-ede.
“Awọn oloṣelu to ni eero Emi lo kan, lo ma n sa fun itakurọsọ lori ọrọ oṣelu – nitori pe wọn biba araalu sọrọ ko ṣe pataki si wọn.”
Bakare tẹsiwaju pe iru oṣelu bẹẹ yoo bí ijọba apaṣẹ wa a , ti ko ni i sunmọ araalu, ti yoo si ma a sa fun ojuṣe rẹ tabi ni akoyawọ si awọn eeyan.
Bo tilẹ jẹ pe tunde Bakare ko darukọ oloṣelu kankan ninu ọrọ to sọ.
ọpọ ọmọ Naijiria paapaa lori ayelujara Twitter, lo ti n sọ oko eebu si oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bola Ahmed Tinubu.
Eyi ṣeeṣe ko jẹ nitori pe oun lo da aṣa ‘Emi lo kan’, lasiko to n polongo fun idibo abẹle ẹgbẹ APC, lọdun 2022.
Awọn nkan mii ti Pasitọ Bakare tun sọ ninu fidio naa lo fi n beere ibeere lori ẹni to pa awọn oloṣelu
Bii Funsho Williams, oludije sipo gomina ipinlẹ Eko lọdun; Harry Marshall, igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu ANPP ti wọn pa lọdun 2003;
Ati Victori Chintex olori obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, ti awọn agbebọn pa nipinlẹ Kaduna, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2022.