You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n gé ọwọ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ yìí láti fi ṣí sàárè àtijọ́ kan ní Egypt nítorí ẹ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mbáyé
- Author, Hisham Almayany
- Role, BBC Arabic News
Awọn eeyan orilẹede Egypt banujẹ gidi lẹyin ti awọn kan gbẹmi ọmọ ọdun mẹjọ kan to jẹ ọkunrin, ti wọn tun ge apa rẹ mejeji.
Baba ọmọdekunrin ọhun, Issam Abu al-Wafa lo ri oku rẹ layika ibi kan ti wọn ti n da oko lagbegbe Upper Egypt, lẹyin ti wọn ti n wa fun odidi ọjọ mẹrin.
Ọlọpaa ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin mẹta ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa lori ẹsun ọhun.
Ọkunrin meji kan ti jẹwọ pe awọn ni wọn gbẹmi ọmọ naa lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ wọn.
Wọn ni awọn ge ọwọ ọmọ naa lati ta a fun awọn to maa n wu awọn ohun alumọ Egypt ninu ilẹ.
‘Mo jokoo, ti mo si n danikan wa ẹkun mu’
Abu al-Wafa, to n ṣiṣẹ awakọ sọ fun ileeṣẹ iroyin BBC Arabic pe “Mo ranti awọn akoko ti emi ati ọmọ mi Mohammed lo papọ, ni gbogbo igba ti mo ba ti danikan joko, mo maa n sunkn nitori mi o le farada ohun to ṣẹlẹ si.
“Ojojumọ lo maa n joko de mi ti mo ba ti n pada bọ lati ibiṣẹ.”
Abu al-Wafa ṣalaye siwaju sip e “ko lero pe ohun buburu kankan le ṣẹlẹ si Mohammed nitori gbogbo eeyan abule lo mọ ọ.”
“Iroyin naa ba mi lojiji bii igba ti ara ba san nigba ti iwadii ọlọpaa fi han pe awọn to jẹ mọlẹbi mi ti wọn maa n ba ọmọ naa ṣerẹ, ti wọn tun n ba mi wa nigba to sọnu lo wa nidi iku rẹ.”
Awọn araalu n bere fun idajọ ododo ati abo lori ayelujara
Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi ibinu wọn han lori ayelujara lẹyin iku ọmọdekunrin naa.
Awọn araalu naa bẹ ijọba ko fi imu gbogbo awọn to lọwọ ni iku ọmọ ọhun danrin lati ṣe arikọgbọn fun ọdaran to ba ni irufẹ iwa bẹẹ lọkan.
Nigba ti awọn mii n rọ awọn obi lati fi ọwọ pataki mu abo ọmọ wọn.
Awọn iṣẹlẹ to waye ṣaaju
Kii ṣe igba akọkọ ti irufẹ nnkan bayii yoo waye ni Egypt ree.
Ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2021, awọn ileeṣẹ iroyin jabọ pe wọn ṣekupa ọdọkunrin kan, ti wọn si ge ẹya ra rẹ wẹlẹwẹlẹ ni Upper Egypt.
Gẹge bii ohun ti iroyin sọ, ẹgbọn baba rẹ ọkunrin, ẹgbọn baba rẹ obirin atawọn ibatan rẹ mii jẹwọ pe awọn lo ṣekupa a lọna ati fi ṣerubọ ninu iboji ọjọ pipẹ kan.
Lọdun 2023, wọn fi tipatipa ba ọmọdebinrin kan lopọ niwaju baba rẹ nile wọn to wa ni Giza Governorate.
Nigba ti ọwọ agbofinro afurasi to wu iwa naa, o ni ẹmi kan lo ni ki oun ṣe bẹẹ lọna ati ṣi iboji atijọ to wa labẹ ile wọn.
Amọ afurasi naa jade laye ṣaaju idajọ rẹ.
Awọn Sheikh eke ati ojukokoro
Iwa fifi eeyan rubọ lọna ati wa awọn nnkan meremere atijọ ni Egypt kii ṣe ohun tuntun.
Igbagbọ wa pe wọn gbọdọ ṣi iboji atijọ naa niwaju “sheikh” ki wọn le ni anafani si agbara Pharao.
Awọn “sheikh” naa lawọn ti wọn ni awọn lagbara lati pe awọn ẹmi to n ṣọ irufẹ iboji bẹẹjade.
Lọna ati ṣe eyii, wọn maa n bere owo gọbọi ati ẹjẹ fun irubọ.
Bo tilẹ jẹ pe ẹjẹ ẹranko ni wọn maa n lo lọpọ igba, nigba mii, wọn maa n bere ẹjẹ eeyan, paapaa, ẹjẹ ọmọde.
‘Eyii kii ṣe aṣa Egypt’
Ahmed Badran, to jẹ Ọjọgbọn nipa imọ ‘archeology’ ati imọ nipa nnkan atijọ Egypt ni fasiti ilu Cairo ni awọn to n wu irufẹ iwa bẹẹ kan n wa ọna lati kanju wa owo ni.
O ni awọn ‘Sheikh onijibi’ maa n tan awọn eeyan jẹ pe ohun alumọni olowo iyebiye atijọ wa ninu iboji labẹ ile wọn, wọn si gbọdọ gbe owo nla kalẹ ati ẹjẹ fun irubọ ki wọn to le wu iboji naa.
Ọjọgbọn Badran tesiwaju pe “awọn baba nla Egypt atijọ ti fi awọn iboji ti awọn nnkan meremere wa ninu rẹ pamọ ki awọn alọ kolohun kigbe ma baa mọ ibi to wa.”
O fi kun pe gbogbo awọn nnkan meremere ti awọn eeyan ti wu jade ṣaaju asiko yii ni ko la ẹbọ tabi etutu ti wọn n fi ẹjẹ eeyan ṣe lọ.
Lẹyin naa lo ke si ijọba lati gbe ofin kalẹ ti yoo da seria fun awọn to ba n ṣe irufẹ nnkan bẹẹ.
O tun ke si ijọba lati maa fi ọpalamba iya jẹ ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o ṣe nnkan bẹẹ.