You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Airbus A380: Ṣé o ti gbọ́ nípa bàálù tó n fi òróró ìsebẹ̀ fò? Mọ̀ nípa rẹ̀ níbí
Ileeṣẹ to n sẹ ọkọ ofurufu Airbus, ti sọ pe oun ti pari idanwo fun ọkọ ofurufu kan to n fi ororo isebẹ fò, dipo epo baalu.
Ninu ikede kan ti ileeṣẹ naa fi si ori ayelujara rẹ lọjọ kejidinlọgsn, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ni wọn ti sọ pe baalu naa, Airbus A380 n ṣamulo epo ti wọ̀n pe ni Sustainable Aviation Fuel, SAF.
Eyi to tumọ si pe epo to n lo ko le ṣe ijamba fun afẹfẹ ati ayika.
Ileeṣẹ Airbus sọ pe wọn ṣe epo SAF ọhun lati ara aloku ororo isebẹ ati awọn ọ́rá ororo miran.
Wọn ni nkan to ya epo SAF sọtọ ni pe wọn ko fi epo eleefin kankan kun.
Lasiko ti wọn dan baalu naa wo loju ofurufu, wakati mẹta lo fi fo lati papakọ ọkọ ofurufu Blagnac ni ilu Toulouse, de olu ileeṣẹ wọn to wa ni France lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta.
Wọn tun pada ṣe idanwo keji fun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, lati ilu Toulouse de Nice, lati mọ pato odinwọn epo SAF to le lati ibẹrẹ irinajo de opin.
Igba akọkọ re e ti iru idanwo balu bẹẹ yoo waye fun lilo ororo isebẹ lati ibẹrẹ irinajo rẹ titi de opin.
Ọkan lara awọn awakọ wọn, Wolfgang Absmeir sọ pe ọkọ balu Airbus A380 ọhun ni gbogbo amuyẹ.
To si ti pegede bọ si ipele ayẹwo ati afikun awọn imọ ẹrọ to ku fun.
Airbus sọ pe baalu naa n ṣamulo ẹyọkan ṣoṣo iru ẹnjinni ti ọkọ ayọkẹlẹ Rolls Royce Trent 900 n lo.
Ileeṣẹ naa sọ pe oun ni ireti pe baalu to n lo epo SAF yoo ri ontẹ gba ti yoo ba fi di ọdun 2030.
Ti wọn yoo si gbe sori atẹ fun tita lọdun 2035.
Wọn ni lilo epo SAF jẹ ọna kan gboogi lati fopin si eefin aṣe ijamba, ti yoo ba fi di ọdun 2050.