You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pakistan new rape law: Ìjọba yóò fààye gba fífi kẹ́míkà tẹ ọkùnrin lọ́dàá
Aarẹ orilẹ-ede Pakistan ti buwọlu ofin tuntun ti yoo ma rii daju pe wọn tete n ṣe idajọ ẹni to ba fi ipa banilopọ.
Pẹlu iranlọwọ ofin tuntun yii, wọn yoo ṣe idasilẹ akọsilẹ orukọ awọn to ba fi ipa banilopọ; wọn ki yoo pa aṣiri mọ nipa ẹni ti wọn fi ipa balopọ.
Ko tan sibẹ o, ofin naa tun faaye gba pe ki wọn o fi kẹmika tẹ ẹni to ba fi ipa ba eeyan lopọ lọdaa.
Fun ile ẹjọ, ofin tuntun yii yoo mu ki ile ẹjọ tete ma a gbọ ẹsun ifipabanilopọ. Eyi tumọ si pe ile ẹjọ gbọdọ pari igbẹjọ laarin oṣu mẹrin.
- Bíbéèrè fún ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà sọ ìyàwó ilé dèrò ilé ìwòsàn
- Ẹ wo ìṣẹ̀lẹ̀ nípa ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan D'banj ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé
- 'Ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn ko pọ ju fun afipabanilopọ'
- Ìpínlẹ̀ Bauchi àti Kaduna láti máà tẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá
- Ó ti di ẹ̀ṣẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ fún afipábánilòpọ̀ nípìnlẹ̀ Ekiti- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti
- "Grandpa àti Uncle mi, ń fipá bá mi lòpọ̀ láti ọmọ ọdún mẹ́rin"
Ijọba buwọlu ofin tuntun yii lẹyin awuyewuye to waye lẹyin ti awọn ọkunrin kan fi ipa ba obinrin kan lopọ nita gbangba nilu Lahore.
Oju ọna to wọ inu ilu naa ni awọn ọkunrin ọhun ti fi ipa ba obinrin naa lopọ niwaju awọn ọmọ rẹ mejeeji.
Amọ Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Lahore sọ ni ọjọ keji ti iṣẹlẹ naa waye obinrin naa ni ẹbi lori iṣẹlẹ naa.
Oṣu to kọja ni Olootu ijọba, Imran Khan ati awọn ọmọ igbimọ rẹ buwọlu aba ofin yii, ki Aarẹ Arif Alvi to sọ ọ di ofin lọjọ Iṣẹgun.
Ọgọfa ọjọ si ni ijọba ni lati gbe igbesẹ ko ile aṣofin le buwọlu.
Amọ, awọn eeyan ti bu ẹnu ẹtẹ lu ofin naa pe o ti l'agbara ju, ati pe awọn awọ̀n alaṣẹ ijọba ko tẹle ilana to yẹ.