Àwọn aláṣẹ n wa àwọn tó ṣalabapade Mínísítà féto ìlera ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó lùgbadì Coronavirus

Aisan Coronavirus ko mọ olowo, ko mọ talaka, koda awọn to dipo ijọba mu gaan ko ribi bọ lọwọ ajakalẹ yi.

Nilẹ Gẹẹsi o ti mu Minisita feto ilera Nadine Dorries.

Nadine Dorries ni ọmọ ile aṣofin akọkọ ti yoo ko aisan yi ninu awọn eeyan ejilelọgọrinlelọọdurun ti wọn funra si pe o ni aisan naa.

Minisita Nadine ni oun ti n gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ati pe oun ko jade sita ni bamu pẹlu imọran awọn eleto ilera.

Ikede yi n waye lẹyin ti eeyan ẹlẹkẹfa gba ti ọwọ aisan yi ku ta si gbọ pe baba agbalagba ẹni ọdun ọgọrin lẹni to ku kẹyin.

Ẹwẹ, ajọ to n mojuto eto ilera nilẹ Gẹẹsi NHS ni awọn ti n ṣafikun agbara lati le ṣe ayẹwo fawọn eeyan pẹlu bi iye awọn to nko Coronavirus ṣe n pọ si.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe wọn yoo ma ṣe ayẹwo ẹgbẹrun mẹwa lojumọ ni iyatọ si ẹgbẹrun meji din diẹ ti wọn n ṣe tẹlẹ.

Wọn yoo jẹ ki esi naa ma tete jade bayi ti o si ṣeeṣe ki awọn eeyan ma mọ esi ayẹwo laarin wakati mẹrinlelogun