Ẹlẹ́sìn Aghoris: Wọ́n ń jẹ ènìyàn, wọn a sì fi orí rẹ̀ mumi

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń tẹ̀lẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá òkú lòpò yíí, tí wọ́n sì ń jẹ ẹran ara ènìyàn.

Awọn ẹlẹsin Hindu yii ma n woye bii nkan yoo ṣeri pẹlu arojinlẹ,ti wọn si maa n jẹun, sun ati ni ibalopo laarin awọn oku ti wọn n jo ni ina ni itẹ iboji.

Awọn wọnyii maa n rin kaakiri lai wọ asọ, wọn maa n jẹ ẹran ara eniyan ti wọn a si ma a fi agbari eniyan ṣe igba imumi ati ti ounjẹ, ati pe oogun oloro marijuana ki n wọ́n lọwọ wọn lasiko naa.

Asiko ọdun iwẹ awọ̀n elesin Aghoris nikan ni wọn máa n jade ni Ọjọ Kẹẹdogun, osu kini, odun ni orilẹ-ede India ti wọn n pe ni ọdun Kumbh Mela.

Ọ̀pọlọpọ̀ eniyan lo n tẹle awọn okunrin ti wọn ba oku lọpọ yii, ti wọn si n jẹ ẹran ara eniyan.

Ni ede Sanskrit, ohun ti orukọ Aghori duro fun ni ‘ẹni ti ki n ba eniyan lẹru’, amọ awọn ohun ti o n banilẹru ti wọn n gbọ nipa wọn maa n fa ibẹrubojo ati irira nipa wọn fun awọn eniyan.

Ohun to yẹ ko o mọ nipa awọn ẹlẹsin Aghoris ni India

  • Ihuwasi wọn da bi ẹni wi pe wọn sẹṣẹ bẹrẹ ẹsin naa ni saa nkan bii ẹgbẹrun un ọdun mejidinlogun (18th century) sẹyin ni.
  • Ohun ti wọn gbagbọ ni wi pe eniyan ko gbọdọ bẹru iku tabi oku ni wọn se n jẹ eniyan lati bori ibẹru iku.
  • Iwadii fihan wi pe awọn ko gbagbo nipa ikorira ọmọlakeji.
  • Awọn ti wọn n se ẹsin yii ko pọ rara. Wọn fikun un pe awọn ti wọn n darapọ mọ ọdun Kumbh Mela kii se awọn ti o jinlẹ ninu ẹsin naa.
  • Bakan naa ni wọn maa n sisẹ ilu nipa titọju awọn oni warapa ni itẹ ti wọn maa n gbe oku si ati ile iwosan wọn.
  • Amọ wọn korira ibalopọ laarin akọ si akọ, wọn rii gẹgẹ bi ohun irira.