Ṣé o fẹ́ kí ọpọlọ ọmọ rẹ̀ jì pépé? Jẹ́ kí a kọ ẹ

Oríṣun àwòrán, Anthony Asael/Art in All of Us
- Author, Lati ọwọ Ahmen Khawaja
- Role, BBC World Service
Ìwádìí kan fihàn wí pé ó ní àwọn nnkán tí òbí lè ṣe àwọn ọmọ wọn bàa le jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé.
Ni ọdun 1968 ni onimọ ijinlẹ kan ninu imọ ẹkọ Psychometrics, Julian Stanley, ṣe alabapade ọmọ ọdun mejila kan ti o n kọ ẹkọ nipa ẹrọ ayarabiaṣa yunifasiti John Hopkins l'orilẹ-ede Amerika.
Ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Josph Bates mọ iwe daada sugbọn oun ti wọn n kọ ti ṣuu.
Idi ni wi pe imọ to ni ti tayọ tawọn akẹgbẹ rẹ.
Odọmọde yi jẹ iwuri fun Stanley, ti o si tori rẹ bẹrẹ iwaadi ti o gba a ni ọdun márùndínláàdọ́ta lori idagbasoke awọn ọmọ ọlọpọlọ pipe lara awọn ti a ti ri Mark Zukerberg ti o da Facebook silẹ ati gbajugbaja akọrin, Lady Gaga.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo wa pada sẹlẹ si Joseph Bates? O se daada ninu ẹkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, LinkedIn
O tẹsiwaju pẹlu ẹkọ rẹ, o si gba oye ọmọwe. O bẹrẹ si ni kọ awọn akekọ fasiti, ti o si jẹ ogunna gbongbo ninu awọn to nimọ nipa ẹkọ atọwọda ti a mọ si ''artificial intelligence".
Stanley bẹrẹ eto kan ni yunifasiti ẹka to n moju to awọn ọdọ to ni ẹbun ni ilu Baltimore, eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni ''imọ awọn ọdọ to ja fafa ninu isiro, ti o si se iwadi igbesi aye awọn ọdọ to le ni ẹgbẹrun marun ti wọn pegede.
Nipasẹ iwadi yi ni Stanley ti sọ awọn nnkan pataki to yẹ ki eeyan ṣe ti o ba fẹ ki ọpọlọ ọmọ rẹ ji pepe.

Oríṣun àwòrán, Eric Lafforgue/Art in All of Us
1) Jẹ ki ọmọ rẹ ni orisirisi iriri
Awọn ọmọ to mọwe daada ṣaba maa n nilo iriri tuntun lati tunbọ sọ ọpọlọ wọn ji.
Ti eeyan ba si aye silẹ fun ọmọ lati ni iriri l'orisirisi,a ma fun ọmọ ni anfaani lati koju ipenija to ba ba pade.
Awọn onimọ ijinlẹ ni lootọ lo dara ki eniyan koju mọ oun to mọ, sugbọn igboya naa se pataki ti ọmọ ba fẹ ṣe nnkan tuntun.

Oríṣun àwòrán, Anthony Asael/Art in All of Us
2) Ṣe awari ohun ti wọn fẹran ki o si ranwọn lọwọ pẹlu rẹ
Bo ṣe ere idaraya tuntun ni tabi kikopa ninu kilasi ere itage,ti ẹ ba fun awọn ọmọ laaye lati dan nnkan tuntun wo, eyi a ma jẹ ki wọn ni ifarajin lọjọ iwaju.
Ẹ ma ṣe fi ipa mu wọn lati ṣe ohun ti ko wu ọkan wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3) Ṣe atilẹyin fun ọmọ rẹ ninu eto ẹkọ rẹ ati awọn ipenija miran to ba n doju kọ.
Ilakaka lati ni imọ sii jẹ atọna lati kọ ẹkọ.
Awọn ọmọde a ma saba bere ibeere ki wọn to bẹrẹ ile ẹkọ. O ṣeeṣe ki o fẹ su ọ sugbọn, o ṣe pataki lati fi suuru ma dahun gbogbo ibeere wọn.
Ọmọ ti ko dakẹ ibeere saba maa n ṣe daada ninu ẹkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Eric Lafforgue/Art in All of Us
4)Ku iṣẹ lo n mu ori oniṣẹ ya
Ran awọn ọmọde lọwọ nipa kiki wọn ku isẹ yatọ si mimu abaabọ iṣẹ ni pataki.
Awọn ọmọde a ma wo awokọṣe lara obi wọn.
Ti ọmọ ba n gbiyanju lati kọ ẹkọ, apẹẹrẹ pe yoo ṣe daada ni yi. O si yẹ ki awọn obi maa mu ori wọn wu.

Oríṣun àwòrán, Anthony Asael/Art in All of Us
5)Ijakulẹ kii ṣe ohun ti o gbodọ maa bẹru.
Bi eniyan ko ba ṣina, ko le mọ ọna.
A gbọdọ ri ẹkọ kikọ gẹgẹ bi anfaani lati ran ọmọ lọwọ, ki wọn le mọ bi wọn yoo ti ṣe koju ipenija nigba miran.

Oríṣun àwòrán, Frédéric Soltan
6) Ẹ ma fi ọmọ kan we ikeji
Fifi ọmọ we ọmọ a ma mu ipinya wa laarin awọn ọmọde.
Ko da, o le ṣe okunfa ki awọn ọmọ kan ma dunkoko mọ awọn ọmọ miran.
A si tun ma jẹ ki wọn fọkan si pe awọn le ṣe aṣiṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
7) Ẹ pawọ pọ pẹlu awọn oluko ọmọ yin
Awọn akẹkọ ti wọn loye ati imọ a ma nilo iranwọ ohun elo ẹkọ ti yoo mu wọn peregede, yala lati ọdọ oluko tabi obi wọn.
Pipawọ pọ nipa ṣiṣe amulo eto ẹkọ to wa ni itosi wọn ṣe pataki.

Oríṣun àwòrán, Frédéric Soltan
8) Ri wi pe o ṣe idanwọ fun ọmọ rẹ lati mọ bo ti ṣe mowe si
Igbesẹ yii le ran obi lọwọ lati beere fun afikun tabi adinku iye iṣẹ ti ọmọ wọn yoo se.
Eleyi si le ranwon lọwọ lati mọ awọn ipenija yowu ti ọmọ wọn ba ni.

Bawo lo sẹ le mọ wi pe ọmọ jẹ ọlọpọlọ pipe?
Wọnyi ni awọn atọna ti yoo jẹ ki o mọ pe ọmọ rẹ ni ẹbun iwe:
• Kii gbagbe nnkan
• Ki ọmọ tete bẹrẹ si ni kawe
• Iru ọmọ bẹẹ yoo yan ere tabi ki o ni imọ ijinlẹ nipa awọn ẹka ẹkọ kan to yatọ si tẹgbẹ rẹ
• Ọmọ rẹ yoo nimọ nipa iselẹ jakejado agbaye
• Ko ni ye ma bere ibeere
• Irufẹ ọmọ bẹ yoo ni ọyaya
• Yoo fẹran orin
•A maa wu ko le iwaju
•A ma ṣe agbekalẹ ọfin tirẹ fun ere idaraya to ba n ṣe













