Adéfẹ́mi Olúbáyọ̀ jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú ikọ̀ ‘Super Eagles’

Olúbáyọ̀ Adéfẹ́mi

Oríṣun àwòrán, NFF

Àkọlé àwòrán, Igba maarun ọtọọtọ lo gba bọọlu fun Super Eagles ki o to jade laye

Ọjọ́ọ̀rù, ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹ́rin ló pé ọdún méje tí ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn agbábọ̀ọ̀lù Super Eagles, Olúbáyọ̀ Adéfẹ́mi, jáde láyé.

Olubayọ Adefẹmi, wa lara awọn ọdọ agbabọọlu orilẹede Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtalelogun ls ti wọn gba ami ẹyẹ fadaka nibi idije Olimpiiki lọdun 2008.

Ikọ̀ Super Eagles duro iduro ẹyẹ fun Adefẹmi

Oríṣun àwòrán, @oluwashina

Àkọlé àwòrán, Inú ìjàmbá ọkọ̀ kan ni Adéfẹ́mi ti kú ní orílẹ̀èdè Greece

Ṣaaju lo ti wa pẹlu ikọ awọn ọdọ agbabọọlu orilẹede Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ ti wọn gba ami ẹyẹ fadaka ni idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2005.

Igba maarun ọtọọtọ lo gba bọọlu fun Super Eagles ki o to jade laye ninu ijamba ọkọ kan ni orilẹede Greece.

Adefemi n mura ati yanju eto igbeyawo rẹ lọwọ nigba naa ni ọlọjọ de.