You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Subsidy removal in Nigeria: Kí ni ìtumọ̀ ‘Subsidy’ àti pé kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí ìjọba bá yọ ‘Subsidy?’
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kede pe ijọba oun yoo yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro 'Subsidy' ni kete to gba ọpa aṣẹ .
Lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ fun igba akọkọ gẹgẹ bii Aarẹ Naijiiriani gbagede Eagles Square niluu Abuja, Tinubu ni "Ko si subsidy mọ."
O fi kun ko si ipese fun afikun owo epo naa ninu eto iṣuna ọdun yii.
Ẹwẹ, ọpọ awọn araalu lo ti n bere pe ki ni 'subsidy' gan an?
Ati pe ki ni yoo ṣẹlẹ ti opin ba de 'subsidy' ni Naijiria.
- Fuel Subsidy Removal- Ẹ̀yin aráàlú ẹ farabalẹ̀, kìí sẹ ní kíákíá ní a ó yọ ìrànwọ́ epo – Bola Tinubu
- Owó oṣù- Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun daṣẹ́ sílẹ̀
- Bí èèyàn fi màlúù ránṣẹ́ tí mo bá sè é yóò kan, mọ́tò ni kí ẹ rà fún mi báyìí – Iya Gbonkan
- Ohun mẹ́wàá tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa Raymond Dokpesi tó dolóògbé..-
- Ó dìgbà tí a bá ń lo ọ̀nà ìṣẹ̀ǹbáyé láti fi sèbúra ní àwọn adarí wa yóò tó dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́- Baba Ẹlẹbuibọn
Ki ni itumọ 'subsidy?'
'Subsidy' n tumọ si igba ti ijọba ba n san lara owo to yẹ ki awọn araalu maa san fun nnkankan, bii ile gbigbe, epo bẹntiro, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni Naijiria, ijọba apapọ lo n san awọn ida kan lara owo epo bẹntiro ti awọn araalu n ra lawọn ile epo, bi bẹẹ kọ, o yẹ ki jala epo bẹntiro kan wọn ju iye ti awọn araalu n ra a lọ.
Fun apẹrẹ, ti awọn araalu ba n ra jala epo kan ni ₦185, o n tumọ si pe ijọba apapọ ti san iye kan lara iye gan to yẹ ki owo epo naa gan jẹ ni san an. O le jẹ ₦185 to jẹ ilaji, ju bẹẹ lọ tabi ko kere si iye yii, ṣaaju ki epo naa to de ile epo ọhun.
Iyẹn ni pe iye to yẹ ki wọn maa ta jala epo ni Naijiria lai si 'subsidy' nibẹ lee to ₦370 tabi ju bẹẹ lo gan.
Ki ni itumọ pe ijọba yọ 'subsidy?'
Ni kete ti ijọba ba ti fopin si 'subsidy,' iyẹn ni pe ijọba yoo dẹkun ati maa san owo to n san fun awọn alagbata epo ṣaaju ki wọn to maa pin kaakiri awọn ile epo.
Lai fa ọrọ gun, iye ti awọn araalu yoo maa ra epo yoo fo lati ₦185 si ₦370 tabi ju bẹẹ lọ.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba ti yọ 'subsidy' tan?
Yiyọ owo iranwọ ori epo n tumọ si pe awọn araalu yoo maa ra epo bẹntiro ni iye owo ti wọn n ra a tẹlẹ lọ, tabi ki a kuku ni wọn yoo maa ra epo ni ọwọngogo.
Ni ida keji, nnkan yoo wọn gogo, koda epo ati owo ọkọ ti bẹrẹ si n wọn lawọn ipinlẹ kan bayii bii ipinlẹ Eko, bẹẹ ni ọpọ ero lo ti n to sile epo lati tete ra epo pamọ.
Yatọ si epo ti yoo wọn, owo ọkọ, owo ounjẹ, owo ile, owo asọ, atawọn nnkan mii ni yoo wọn nitori ori ọwọngogo epo ni awọn eeyan yoo maa di ẹbi ọrọ naa le.
Amọ ṣa, ijọba ti sọ pe yiyọ owo iranwọ ori epo naa yoo ṣeranlọwọ fun ọrọ aje Naijiria, bẹẹ si ni ijọba yoo lo owo naa lati fi sẹ awọn ohun meremere atawọn ohun amayedẹrun saarin ilu.
Wayi o, ero awọn ọmọ Naijiria ṣ'ọtọtọ lori igbesẹ ijọba Tinubu lati yọ 'subsidy,' bi awọn kan ṣe faramọ igbesẹ naa lawọn mii n sọ pe ọpalamba iya ni yoo jẹ awọn ọmọ Naijiria.
Ṣe aisi ibudo ipọnpo to n ṣiṣẹ ni Naijiria lo fa Subsisy sisan ni?
Ọpọ lo n sọ pe nitori pe ko si eyikeyi ibudo ifọpo (refinery) kankan to n ṣiṣẹ ni Naijiria eyi to mu ki a maa ko epo rbi lọ si ilẹ okeere, fi ra afọmọ epo bii bẹntiro, disu, kerosini ati bẹẹ lọ lo fa sisan owo iranwọ ori epo.
Irọ to jina si otitọ ni eyi.
- 'Ọdún 500 sẹ́yìn ni ọmọ Ọba Aláàfin Oyo tẹ ìlú Ondo dó'
- Ẹ̀yin tẹ́ẹ fẹ́ máa ṣe -prank- pa owó bíi tèmí, ẹ má dán an wòo torí adúrú ìyà tó ń jẹ mi yìí - Trinity guy
- Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá -Part 2 Ti Oluwa Nile- dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé- Baba Wande
- Ìpọ̀njú àti ikú ọkọ mí ló sún mí dé ìdí bàtà ṣíṣe- Monsurat Oyedeji
- Kí ni ìwọ mọ ''Perfume'' sí lédè Yorùbá
Lasiko ti awọn ibudo ifọpo wọnyi n ṣiṣẹ ni ijọba ti n san owo subsidy yii. Iyatọ to wa nibẹ kan ni wi pe, nigba naa, ileeṣẹ epo rọbi Naijiria to n ṣe akoso awọn ibudo ifọpo rọbi naa ni wọn n san an fun.
Iyatọ to wa nibẹ lasiko yii to jẹ pe ilẹ okeere la ti n ra epo wale ni wi pe iye owo naa yoo pọ sii
Nitori pe awọn oniṣowo epo to n ra epo wọle yoo ṣiro owo ti wọn fi ra epo ni ilẹ okeere, owo ọkọ ojuomi alagba nla ti wọn fi ko o wa si Naijiria pẹlu owo ibudo ikepopamọ si (Jetty) ti wọn yoo koo si nigba to ba de Naijiria.
Gbogbo eyi ni wọn yoo ṣiro pọ lati fi ṣe odinwọn iye ti wọn yoo ta jala epo kan. Ẹ maa gbagbe pe gẹgẹ bi oniṣowo, awọn naa a fi ere si ori rẹ. Ilaji iye ti wọn ba wa pe owo epo lẹyin ti wọn ba ṣiro gbogbo nnkan wọnyii ni ijba yoo ti wa san iye idan kan lara rẹ.