You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun mẹ́wàá tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa Raymond Dokpesi tó dolóògbé...
Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023 ni iroyin iku alaga ileeṣẹ iroyin AIT to fi mọ Daar Communications Limited jade laye.
Ninu atẹjade ti awọn mọlẹbi fi lede ni mọ ti fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni igi araba naa ti wo lulẹ.
Bakan naa ni wọn kede pe laipẹ ni awọn yoo fi lede igba ati akoko ti isinku rẹ yoo waye.
Amọ pupọ ninu awọn eniyan ni ko mọ nipa oloogbe naa.
Ohun mẹwaa ree ti wọn ko mọ nipa Dokpesi...
- Ọjọ Karundinlọgbọn, Osu Kẹwaa, ọdun 1951 ni wọn bi Dokpesi.
- Ileẹkọ alakọbẹrẹ Loyola ni ilu Ibadan lo lọ, ko to lọ si ileẹkọ Immaculate Conception College ni ilu Benin. Ileẹkọ giga fasiti Benin naa lo lọ. Ki o to lọ si oke okun fun imọ ẹkọ giga ni fasiti Wyzsza Szokta Gdynia ati fasiti Gdansk Sopok ni orilẹede Poland.
- O ṣiṣẹ ni ileeṣẹ Nigerian Ports Authority gẹgẹ ọmọogun ori omi ni ọdun 1969.
- Dokpesi ni ẹni akọkọ to kọkọ gba iwe aṣẹ lati ni ileeṣẹ redio aladani ni Naijiria pẹlu Raypower 100.5FM., ti ileeṣẹ amohunmaworan rẹ, Africa Independent Television si jẹ ileeṣẹ amohunmaworan ni ilẹ Afrika ti wọn yoo ma wo ni orilẹede Amẹrika.
- Bakan naa lo ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari awọn oṣiṣẹ ti Gongola State Government lati Osu Kẹwaa si Oṣu Kejila, ọdun 1983. O si tun di ipo adari ileeṣẹ African Ocean Line Limited lati ọdun 1984 si ọdun 1988.
- Ọdun 2016 ni ajọ EFCC fi ẹsun iwa ajẹbanu kan lori ẹsun pe o lọwọ ninu gbigba owo to le ni biliọnu meji naira ti wọn fi ẹsun kan Ọgagun Mohammed Sambo Dasuki pe o lu ni ponpo. Amọ ileẹjọ ni ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni ọdun 2021.
- Bakan naa lo ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ ijọba bii Ileeṣẹ to n risi eto irina loju popo ati ofurufu, ileeṣẹ to n risi ọrọ omi ni Nigerian Port PLC ni ọdun 1978-1983.
- Ni ọdun 2008 ni wọn fun Dokpesi ni ami ẹyẹ National Honour of the Officer of the Federal Republic (OFR).
- Oun naa lo kọkọ ni ileeṣẹ to n gbe ẹru lori omi ni Naijiria.
- O lugbadi aarun covid-19 lasiko ajakalẹ aarun naa to si jajabọ.
Alága iléèṣẹ̀ ìròyín AIT, Raymond Dokpesi ti jáde láyé
Oloye Raymond Dokpesi to ni ileeṣẹ Daar Communications ti jade laye.
Ninu atẹjade ti awọn mọlẹbi fi lede ni wọn ti fi iroyin naa lede.
Atẹjade naa ni Dokpesi to jẹ ọkan googi ninu ẹgbẹ osẹlu PDP, jade ni aye ni ileewosan ni ilu Abuja lo ti jade laye lẹyin to ṣe aisan rọpa-rọṣẹ.
Wọn fikun un pe Dokpesi jẹ eniyan nla to laanu awọn eniyan to si jẹ adari ileeṣẹ iroyin DAAR Communication fun ogun ọdun to ti kọja bayii.
Bakan naa ni wọn ni alaanu awọn eniyan ni, to jẹ baba rere, to si jẹ awokoṣẹ fun ọpọlọpọ eniyan.
Awọn mọlẹbi naa dupẹ lọwọ awọn araalu fun atilẹyin wọn, ti wọn si ni ki wọn tubọ maa ranti wọn ninu adura.
Wọn fi da awọn araalu loju pe awọn yoo fi lede laipẹ bi eto isinku naa yoo ṣe lọ.
Lasiko aawẹ Ramadan ni iroyin gbe pe Dokpesi ṣe aisan, ti o si n gba itọju, ki iroyin to jade ni oni pe o ti jade laye.