You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbogbo àkànṣe iṣẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ ní sáà àkọ́kọ́ ni mà á parí ní sáà kejì yìí - Gómìnà Abdulrasaq
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ búra wọlé fún fún sáà ìkejì ti ní gbogbo àkànṣe iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ ni òun máa parí ní sáà kejì yìí.
Abdulrasaq sọ èyí ní kété tí wọ́n búra wọlé fún un tán gẹ́gẹ́ bí gómìnà Kwara fún sáà ọdún mẹ́rin mìíràn bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún ọdún 2023 títí di ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún ọdún 2027.
Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Kwara, Abiodun Adewara ló ṣe ìbúrawọlé fún gómìnà àti igbákejì rẹ̀, Kayode Alabi ní ilé ìjọba tó wà ní agbègbè GRA, ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.
Lẹ́yìn ìbúrawọlé náà ni gómìnà Abdulrasaq tọwọ́bọ ìwé ẹ̀rí mo yege gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara fún ọdún mẹ́rin.
Láàárín aago mẹ́jọ àárọ̀ sí aago mẹ́sàn-án ni ètò ìbúrawọlé náà fi wáyé nítorí gómìnà fẹ́ kópa níbi ayẹyẹ ìbúrawọlé fún Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tuntun fún Nàìjíríà.
Ilé iṣẹ́ ìránṣọ, ilé iṣẹ́ ṣúgà, afárá Tunde Idiagbon tó ń lọ lọ́wọ́ ni mà á parí
Gómìnà Abdulrasaq ṣàlàyé pé gbogbo àkànṣe iṣẹ́ tí ìṣèjọba òun bẹ̀rẹ̀ lásìkò sáà àkọ́kọ́ ni àwọn máa parí ní sáà kejì yìí.
Ó ní ilé ìránṣọ àti afárá Tunde Idiagbon tó ti fẹ́ ẹ parí ni àwọn máa ṣe ìfilọ́lẹ̀ láìpẹ́.
Bákan náà ló ní pé iṣẹ́ ń lọ takuntakun láti ri dájú pé awon ilé iṣẹ́ ṣúgà, innovation hub àti àwọn àkànṣe iṣẹ́ mìíràn tó ń lọ lọ́wọ́ ni yóò parí kí sáà kejì òun tó wá sópin.
Gómìnà ní èròńgbà wà wí pé àwọn àkànṣe iṣẹ́ yóò mú ìrúgọ́gọ́ bá ètò ọrọ̀ ajé àti àwọn ohun amáyédẹrùn mìíràn fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kwara.
Ó fi kun pé òun ti tọwọ́bọ ìsinmi oṣù mẹ́fà fún àwọn obìnrin tó bá bímọ ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Gómìnà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kwara fún bí wọ́n ṣe dìbò yan òun fún sáà ìkejì àti pé òun kò ní já wọn kulẹ̀ lórí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú òun.
Láàárín aago mẹ́jọ àárọ̀ sí aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ yìí, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún ni ètò náà yóò fi wáyé.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí gómìnà fẹ́ lọ kópa níbi ètò ìbúrawọlé fún Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, èyí tí yóò wáyé nílùú Abuja lónìí bákan náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lóọ́kọ lóókì tó fi mọ́ àwọn ọba aládé, ọrùn ilẹ̀kẹ̀ ló ti ń balẹ̀ sínú gbọ̀ngàn tí ayẹyẹ náà ti wáyé
Gbogbo ètò ti ń tò ní ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fún ayẹyẹ ìbúrawọlé sáà kejì gómìnà Abdulrahman Abdulrasaq