You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Election 2023: Tani Rabiu Kwankwaso tó ń díje dupò ààreͅ ní eͅgbéͅ òsͅèlú NNPP?
Rabiu Musa Kwankwaso to jeͅ eͅni oͅdun meͅrindinlaadoͅrin lo n dije du ipo lati di ipo aareͅ mu lorileͅede Naijiria ni idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Oͅjoͅ Karundinloͅgbon, Osu Keji, oͅdun 2023.
Kwankwaso jeͅ eniyan to feͅran lati maa woͅ fila pupa ni gbogboogbo igba, lati fi asͅeyoͅri reͅ han.
o fi igba kan jeͅ minisita teͅleͅri fun eͅka Ologun, o ti jeͅ seͅnatoͅ ri fun igba meji ati gͅgͅbi gomina ipinleͅ Kano ni eemeji.
Rabi'u Musa Kwankwaso darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP), ni ọdun 1992, ti wọn si dibo yan an gẹgẹ bi aṣoju ni Ile Igbimọ Aṣofin to n ṣoju ẹkun Madobi.
Lẹyin naa lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Democratic Party of Nigeria (DPN) lasiko iṣejọba Ọgagun Sani Abacha.
Ọdun 1998 ni Kwankwaso darapọ mọ PDP, to si jẹ gomina ipinlẹ Kano ni May 29, 1999 si May 29, 2003, to tun wọle pada ni ẹlẹẹkeji ni ọdun 2011.
Ni ọdun 2013 lo yapa kuro ni PDP lọsi APC, amọ to kuna ninu idibo abẹle fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa.
Ni ọdun 2018 ni Kwankwaso pada si PDP amọ to tun fidirẹmi ni idibo abẹle sipo oludije aarẹ ni ẹgbẹ naa, eleyii ti Atiku Abubakar bori.
February 22, 2022 ni o lọ da ẹgbẹ tuntun kalẹ, New Nigeria Peoples Party, to si bori gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu naa.
Amoͅ onimoͅ nipa eto oselu , Chisom Ugbari ni Kwankwaso nilo lati ni awoͅn alatileͅyin ni guusu Naijiria lati le di ipo aareͅ mu.
Bakan naa ni woͅn gba Kwankwaso ni imoͅran lati darapoͅ moͅ Peter Obi ti Labour Party ki woͅn le da ero woͅn pada.
Amoͅ Kwankwaso lasiko to n ba BBC soͅroͅ ni Peter Obi kere si oun ninu oͅroͅ osͅelu, nitori oun ti pe ninu oͅroͅ oselu.
Asͅeyoͅri ni eto eͅkoͅ…
Ninu oͅroͅ reͅ alatileͅyin Kwankwaso, Ibrahim Sharada ni okiki Kwankwaso kii se ni ila oorun Naijiria nikan.
Bakan naa lo ni Kwankwaso peͅlu awoͅn oludije meͅrin to pegede juloͅ ni Naijiria, to si seese ko gbe igba oroke bii oͅdun 1999 to di ipo gomina mu ni ipinleͅ Kano.
Asiko yii ni opin de ba ijoͅba Ologun ni Naijiria, amoͅ ti ko I tii beͅreͅ si ni de fila pupa reͅ nigba naa loͅhun.
Igba isejoͅba aareͅ Obasanjoͅ lo fi si ipo Minisita fun ileesͅeͅ Ologun, leͅyin to kuna idibo sipo gomina ni oͅdun 2003.
Ipo yii lo di mu titi di oͅdun 2007, ti alaafia job ani Naijiria.
Oͅkan lara awoͅn ohun ti Kwankwaso soͅ pe oun yoo se ni lati fopin si igbesunmoͅmi ati eto aabo to meͅheͅ ni Naijiria.
Leͅyin to kuro ni isejoͅba tan lo pada si eto oselu ni ipinleͅ Kano, to si beͅreͅ igbimoͅ Kwankwasiyya movement, eleyii to se ni ateͅle ajijagbara loͅwoͅ awoͅn afinise owo eͅru nigba naa loͅhun, Malam Aminu Kano.
Awoͅn alaileͅyin reͅ yii ma n woͅ fila pupa peͅlu asͅoͅ fufu , ti o si ma n fi aidoͅgba han ni awujoͅ, paapaa ai kii bu oͅla fun awoͅn obinrin ni awujoͅ woͅn
Kwankwaso ni gbogbo awoͅn ileri yii ni oun musͅeͅ lasiko ti oun w ani ipo gomina ni Kano, paapaa eto eͅkoͅ to muna doko.
O mu eto eͅkoͅ deͅrun fun awoͅn ara ilu nipa ipese eto eͅkoͅ oͅfeͅ fun awoͅn araalu.
Amoͅ, awoͅn oͅmoͅ bibi ipinleͅ Kano nikan ni anfaani yii wa fun nitori woͅn yoo safihan sabuke to soͅ wi pe ipinleͅ Kano ni woͅn ti wa, ki woͅn to le jeͅ ere eto eͅkoͅ oͅfeͅ.
''Kete to de ipo gomina lo kede eto oͅfeͅ fun awoͅn araalu, to si beͅreͅ si ni fun awoͅn oͅmo ileeͅkoͅ ni ounjeͅ oͅfeͅ.
Ninu oͅroͅ reͅ, Kwankwaso ni eto eͅkoͅ jeͅ oun lokun nitori o poͅn dandan fun awoͅn oͅmoͅ lati loͅ si ileeͅkoͅ
Eyi ko sͅeͅyin bi oun fun ara reͅ se pegede ninu eto eͅkoͅ to si loͅ si fasiti, to si tun keͅkoͅ imoͅ onimoͅ eͅroͅ lori omi ni Ileͅ Geͅeͅsi to fi moͅ India.
O pada si enu isͅeͅ ni eͅka naa ni ipinleͅ Kano, ki o to wo inu eto oselu loͅ ni Naijiria.
Eͅsun lilu owo ifeͅyinti awoͅn araalu ni ponpo
Bi awoͅn oloselu miran ni Naijiria, woͅn ti fi eͅsun jeͅgudujeͅra kan Kwankwaso.
Ni oͅdun 2021 leͅyin o pari saa reͅ geͅgeͅ bi seͅnetoͅ ni ajoͅ EFCC pe lori ͅeͅsun pe o lu owo ifeͅyinti awoͅn araalu ni ponpo lasiko to w ani ipo gomina.
Amoͅ Kwankwaso ni ko si otitoͅ ninu eͅsun naa ati pe awoͅn oͅbayejeͅ ninu oselu ni woͅn feͅ ba orukoͅ oun jeͅ, ti eͅsun naa si pari sibeͅ.
Kwankwaso to ti feͅ iyawo to si bi oͅmoͅ meͅfa ni iseͅ oselu ye oun yekeyeke.
O jeͅ eniyan to feͅran lati maa ni ipa rere lai teͅle eͅnikeͅni, oun lo jeͅ ki aworan reͅ kaakiri gbogbo ipinleͅ Kano.
Bakan naa ni orukoͅ reͅ , Kwankwasiyaa wa lara gbogbo awoͅn ile nla nla to koͅ si ipinleͅ Kano lasiko ijoͅba rͅ, to si ni pe oun ko feͅ ki eͅnikeͅni gbagbe oun.