You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
ASUU Strike: Ìjọba pàrokò ìkìlọ ránṣẹ sẹ́gbẹ́ olùkọ́ fásitì, bó ṣe pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
Fakinfa laarin ijọba apapọ Naijiria ati ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti Naijiria ti gba ọna miran yọ bayii.
Eyi ko si ṣẹyin bi ẹgbẹ naa ṣe wọ ijọba lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun ni itako idajọ to ni ki wọn wọle pada sẹnu iṣẹ.
Wọn ni idajọ ti ile ẹjọ to n risi ọrọ laarin oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ gbe kalẹ ni Abuja ko ba awọn lara mu.
Bẹẹ naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ fidi rẹ mulẹ pe adajọ to gbe idajọ yi kalẹ kuna nipa idajọ to gbe kalẹ nitori ko
- Kò tán o! Ilé ẹjọ́ tún sún ìgbẹ́jọ́ láàrin ìjọba àti ASUU síwájú
- Ààrẹ Iran kọ láti yọjú sí Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn CNN nítorí ko lo ìbòrí
- Iléẹjọ́ tí rán Ọlọ́pàá tó ṣekúpa Kolade Johnson lọ sí ẹ̀wọ̀n igbere
- Amotekun àtàwọn ẹsọ àláàbò míì kò ní kópa nínú ìpolongo ìbò - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
- ‘’Ohun tí Tinubu fẹ́ fúnmi nìyíí ká ní mo darapọ̀ mọ́ APC...’’
Agbẹjọro agba to n ṣẹjọ lorukọ ASUU Femi Falana ni awọn rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa ni Abuja lati yi idajọ ti o wa nilẹ pada..
Idajọ taa n wi yi leleyi ti ile ẹjọ to n risi ọrọ laarin oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ gbe kalẹ pe ki awọn olukọ pada siṣẹ ki wọn si maa kọ awọn akẹkọọ.
Adajọ Polycarp Hamman lo gbe idajọ yi kalẹ lỌjọru to kọja to si ni ki wọn dawọ iyanṣẹlodi duro titi di igba ti ile ẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ mii lori ọrọ yi.
O ti le ni oṣu meje bayii ti ASUU ti faake kọri pẹlu iyanṣlodi ti ijọba apapọ si wọ wọn lọ ile ẹjọ nigba ti idunadura fori ṣanpọn.
Kini esi ijọba si ọrọ yi
Lati rin jina jina ni esi ijọba apapọ to n waye lori ọrọ bi ASUU ṣe gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ.
Minisita fọrọ oṣiṣẹ Chris Ngige lo si n dawọn lohun lori ọrọ yii pẹlu amọran pe ki wọn bọwọ fun idajọ ile ẹjọ, ki wọn si pada sẹnu iṣẹ.
O fesi yi lasiko to n dahun ibeere lọwọ awọn akọroyin ni ilu New York l'Amẹrika nibi ti ipade apero ajọ isọkan agbaye ti n waye.
O ni ''emi kii ṣe ASUU ṣugbọn agbọye ofin ni pe ti idajọ ile ẹjọ kan ba wa nilẹ, ohun to tọ ni pe ki eeyan tẹle idajọ yi ṣaaju ko to lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun''
''Tori naa ohun taa lero pe o yẹ ki wọn ṣe ni ki wọn kọkọ pada si kilaasi''
Nigige fi kun pe pipada si kilaasi ko tunmọ si pe awọn ko ni tẹsiwaju idunadura. O ni gbogbo ọna lawọn yoo maa fi ṣe idunadura ọhun.
Ki lo fa iyanṣẹlodi naa ni paapa?
Ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti ni Naijiria lawọn n ja ki ijọba ṣe imuṣẹ adehun kan ti wọn buwọlu pẹlu ẹgbẹ olukọ fasiti ni ọdun 2009 ati awọn nkan miran.
Ọkan lara igbegidina ti ko jẹ ki ọrọ ni iyanju ni fifẹnu ko lori ọna ti wọn yoo fi san owo olukọ.
Ijọba sọ pe IPPIS lawọn yoo lo amọ ẹgbẹ olukọ ni awọn fẹ ki wọn lo oju ọna mii eleyi tawọn gbe kalẹ ti orukọ rẹ n jẹ University Transparency Accountability Solution (UTAS).
Die ree ninu awọn ohun ti ẹgbẹ olukọ lawọn n ja fun ti eleyi to ku si wa ninu iwe adehun ti wọn lawọn fẹ ki ijọba gbera n lẹ ki wọn ṣe amuṣẹ rẹ.