You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Russia-Ukraine Crisis: Onímọ̀ nípa iṣẹ́ ológun lágbàyéé wòye pé ó ti ń rẹ Russia lórí ìkọlu rẹ̀ torí ọ̀pọ̀ àṣìṣe rẹ̀
Orilẹede Russia ni jẹ ọkan lara orilẹede to ni ikọ ologun to tobi, to si lagbara julọ.
Amọ ọpọ onimọ nipa isẹ ologun lo ti n da siọ ikọ ologun ilẹ Russia bayii nitori isesi wọn ti wọn ni ko kunju iwọn loju ogun nilẹ Ukraine.
Ọpọ igbesẹ ikọlu ti wọn gbinyanju lati gbe lo kuna, ti agba ologun kan ninu ajọ NATO si sọ fun BBC pe awọn igbesẹ Russia ti fihan pe wọn ko se aseyọri nidi afojusun wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ohun tí mo fẹ́ rèé tí ìkọlù sí Ukraine yóò bá dópin - Putin
- Bí orísùn ìkùnsínú ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin Ebele Obiano àti Bianca Ojukwu rèé
- Ológun ní kí aya mi bọ́ aṣọ kúrò lára, pa ọmọ mi mẹ́rin àtàwọn alátìlẹyìn mi - El Zakzaky
- Wo àwọn gómìnà ọgbọ̀n tó ti kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn àjẹbánu àti àṣìlò ipò
- Sé lóòtọ́ọ́ ní ọlọ́pàá yìnbọn mọ́ àgùnbánirọ̀ n'Ibadan?
- Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ - Onímọ
- Báwo ní àláfíà ara Iyabo Oko, ipò wo ní ìlera rẹ̀ wà?
- Nàíjíríà ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, mo gbà pé ìpàdé àpérò gbọdọ̀ wà - Ọba Tejuosho
Eyi lo mu ki BBC maa beere pe nibo ni Russia ti kuna, ta si fọrọ wa awọn asaaju onimọ nipa isẹ ologun lagbaye sọrọ lati mọ ọpọ asise ti Russia se, ti ikọ oogun rẹ fi di nnkan yẹpẹrẹ.
Awọn afojusu ti ko tọ:
Asise akọkọ ti Russia se ni o foju tẹmbẹlu agbara ologun ilẹ Russia, tii se orilẹede to kere si jọjọ ni gbogbo ọna.
Ọgọta biliọnu dọla ni Russia n ya sọtọ fun eto isuna ileesẹ ologun rẹ lọdọọdun nigba ti Ukraine n ya biliọnu mẹrin pere fun isuna ologun rẹ.
Lọpọ igba si ni Putin ti maa n fẹnu yangan nipa awọn eto igbalode to n pese fawọn ologun Russia lai mọ pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun, ni wọn.
Agbara ikọ ologun Russia ati Ukraine ki ogun to de:
Ukraine:
Apapọ iye ologun 1,096,600
Awọn abarapa 196,600
Awọn to wa nipamọ 900,000
Ọkọ ijagun 987
Ọkọ ijagun ofurufu 124
Ọkọ ofurufu to se ikọlu 57
Ọkọ ijagun ologun pajawiri 831
Eroja Ijagun 1,818
Russia:
Apapọ iye ologun 2,900,000
Awọn abarapa 900,000
Awọn to wa nipamọ 2,000,000
Ọkọ ijagun 3,417
Ọkọ ijagun ofurufu 1,391
Ọkọ ofurufu to se ikọlu 407
Ọkọ ijagun ologun pajawiri 7,272
Eroja Ijagun 5,899
Ọkan lara awọn ologun ilẹ Gẹẹsi sọ fun BBC pe ọpọ owo idokowo Russia lo ti na lori rira ohun ijagun ati ayẹwo rẹ.
Ni ibẹrẹ ogun naa, Russia ni anfaani to dara si oju ofurufu tọpọ ologun rẹ si ti sunmọ bode ọmọ ogun ofurufu Ukraine.
Ọpọ eeyan lo lero pe wọn yoo tete gba akoso ofurufu naa amọ ko se bẹẹ, ti awọn ọmọ ogun ofurufu Ukraine si n raaye daabo bo ara wọn.
Adanu nla ohun eelo ologun ati aisi koriya:
Ọmọ ologun to to 190,000 lo bẹrẹ ikọlu ni Ukraine, ti ida mẹwa ninu wọn si ti jalaisi, ti orilẹede Ukraine si n kede pe oun ti pa ẹgbẹrun mẹrinla 14,000, ninu wọn.
Bakan naa lawọn onimọ ologun ni ẹri ti foju han pe o ti n rẹ awọn ologun Russia, ti ọkan wọn si ti n rẹwẹsi nipa ikọlu naa.
"Ikọ ologun naa ni otutu ti mu, o ti rẹ wọn, ti ebi si n pa wọn nitori wọn ti wa ninu yinyin lati aimọye ọsẹ ni Belarus, ko to di pe ikọlu naa bẹrẹ.
Ipese awọn eroja ti wọn nilo:
Ọpọ eroja ti ikọ ogun Russia nilo ni ko si, koda, epo gan tan ninu ọkọ ijagun wọn, ti ounjẹ ati ohun elo ijagun wọn si ti buse.
Ọpọ ọkọ wọn lo ti taku, ti wọn si gbe kalẹ nigba ti awọn tirakitọ Ukraine gbe wọn kuro nibẹ.
Awọn onimọ ologun ni Russia ti yin ibọn ati ado oloro bii ẹẹdẹgbẹrun eyi to nira fun wọn lati ra omiran rọpo.
Idi ni pe Amẹrika ti sekilọ fun China ti Russia tọ lọ pe ko ran oun lọwọ.
Amọ wọn ni lai naani ipenija to n koju ogun Russia, o seese ki Putin ma yẹsẹ lori ipinnu rẹ, ti yoo si tun se akọtun ikọlu miran si.
Bakan naa ni wọn woye pe bi o tilẹ jẹ pe Ukraine n ja fitafita lati koju ogun Russia amọ lai jẹ pe wọn ri iranwọ ohun ijagun, iwọnba ni wọn le se.