Valentine's Day: Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ilumọọka ni Naijiria naa darapọ mọ gbogbo eeyan lagbaaye lati ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ, Valentine's Day ni oni ọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun 2022 yii.

Oriṣiiriṣii fọto to n ṣafihan aṣọ alara n bara tawọm gbajugba oṣere fi ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ lo lu ayelujara pa.

Aṣọ alawọ pupa tii ṣe awọn ọjọ ololufẹ yii naa lo gbode kan lonii tii ṣe ayajọ awọn ololufẹ.

Bayii ni awọn oṣere tiata ṣe ṣe ayajọ ololufẹ ni Naijiria

Iyabo Ojo

Iyabo Ojo wa lara awọn oṣere to wọ aṣọ pupa alaranbara lati fi ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ.

Iyabo fi awo ran aṣọ to wọ soju opo Instagram rẹ eleyii ti ọpọ ti n sọ nipa rẹ.

Aṣọ rẹwa pupọ, koda niṣe ni Iyabo dabi angẹli ninu aṣọ naa.

Funke Akindele

Gbajugbaja oṣere, Funke Akindele naa ko gbẹyin ninu awọn to n ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ.

Fọto oun ati ọkọ rẹ, JJCskillz ni o fi si oju opo Instagram rẹ.

Funkẹ kọọ soju opo Instagram rẹ pe ifẹ ni akọkọ, oun lo yẹ ko siwaju.

Lateef Adedimeji

Ọrọ ifẹ ni Lateef Adedimeji kọ si oju opo Instagram tiẹ nipa iyawo rẹ Adebimpe to ti di Rahmah bayii.

Lateef ni pẹlu iyawo oun Rahmah, ojoojumọ ni ọjọ ololufẹ foun.

O dupẹ lọwọ iyawo rẹ pe o n tu oun ninu, ati pe o n fi ifẹ han si oun.

Mercy Aigbe

Aṣọ pupa ni Mercy Aigbe naa wọ lati fi ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ.

Niṣe loun n rinrin oge lara ọkọ bọginni kan to gbe silẹ.

Mercy Aigbe ki gbogbo awọn ololufẹ rẹ ki ọjọ ololufe.