Famine In Horn of Africa: Wo ewu tájọ UN ní ìyàn lè mú bá 13m èèyàn ní ìlà oòrùn Áfíríkà

Ẹka to n risi ipese ounjẹ lagbaye ti ajọ isọkan agbaye, WFP sọ pe eeyan miliọnu mẹtala ni awọn orilẹede kan to wa ni agbegbe ìlà oòrùn Áfíríkà (Horn of Africa) lo n koju ọgbẹlẹ latara ọda ojo ọlọjọ pipẹ.

Aisi ounjẹ ati nkan ọgbin ti ko jade daadaa ti mu ki ọpọ idile sa kuro ni ibugbe wọn gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Bẹẹ si ni wọn lawọn eeyan nilo iranwọ ni kiakia lati le dẹwọ aburu to le tẹyin rẹ wa.

Ọdun mẹta lera ni ọda ojo ti bẹrẹ ti eyi si mu ki iyan ati ọgbẹlẹ to mu, ṣi maa tẹsiwaju.

Nkan oko ko ṣe daada, awọn nkan ọsin n fojojumọ ku bẹẹ si ni eeyan miliọnu mẹtala ni Ethiopia, Somalia ati Kenya wa ninu ebi oun iṣẹ.

Ọwọn gogo ounjẹ naa n ṣẹlẹ si wọn . Aisi ounjẹ tawọn agbe yo wa loko naa wa nibẹ eyi to mu ki awọn eeyan sa kuro nidi iṣẹ agbẹ.

Eyi lo si mu ki wahala wa lọrun awọn ọpọ idile ti ko ri ounjẹ ti wọn yoo jẹ.

Ajọ WFP ti wa sọ pe bi wọn ko ba ri iranwọ ni kiakia ko si bi ewu nla ko ṣe ni ba awọn eeyan lagbegbe wọnyi.

Nitori naa wọn lawọn n beere iranwọ owo to le ni ọọdunrun miliọnu dọla lati koju ọda ati iyan yi.

Leleyi ti wọn yoo kọkọ nilo, wọn yoo fi owo yi pese ounjẹ ati iranwọ owo.

Lọlọjọ pipẹ, iranwọ to ni ṣe pẹlu ṣisẹ eto ti yoo le koju ọda ni awọn agbegbe ti ọrọ yi kan ni wọn yoo fi owo naa pese.

Iyan lagbegbe ila oorun Afirika ko ṣẹṣẹ bẹrẹ:

Ija yala laarin awọn ẹya kan si omiran tabi ikọlu lati ọwọ awọn alakatakiti ẹsin kun nkan to mu ki iyan peleke ni agbegbe Horn of Africa.

Ni Somalia bi apẹrẹ, ija laarin awọn alakatakiti ẹsin Al Shababa to le ni ogun ọdun jẹ ọna kan gbogi ti awọn eeyan ko fi ri iranwọ gba lagbegbe yi.

Ni ti Ethiopia, ija ṣi n waye bayi laarin awọn ọmọ ogun orileede naa ati awọn ẹya Tigray ti eleyi ko si jẹ ki iranwọ de ọdọ awọn ti ebi n pa.

Bawọn araalu ṣe n sa nitori ebi, bẹẹ lawọn mii n tori ikọlu ati aawọ sa asala fun ẹmi wọn.

Akọsilẹ awọn onimọ sọ pe o to eeyan miliọnu mẹwaa kan tabi ju bẹ lọ ti yan ti n se akoba fun lati nkan bi ọgọta ọdun sẹyin.

Ajọ isọkan agbaye UN lo lewaju awọn to n gbiyanju iranwọ fawọn eeyan wn yi ṣugbọn igbiyanju wọn ko fẹ ẹ to tori rẹ ni wn fi lawọn n wa iranwọ si.