Domestic Violence: Ọlópàá mú ìyàwó ilé tó bínú gún ìbátan ọkọ rẹ̀ lọ́bẹ pa nítorí pé o fọ̀ dígí rẹ̀

Iyawo ile kan to n gbe ladugbo Apogidonoyo street, Jafa Agbado, ipinlẹ Ogun ti ko si gbaga awọn agbofinro lori ẹsun pe o gun ibatan ọkọ rẹ lọbẹ pa.

Arabinrin Cynthia Olukiowu, ni alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe wọn mu lọjọ Karun oṣu keji pe o gun arakunrin Habeeb Aremu lọbẹ pa.

Afurasi ẹni ọgbọn ọdun yii, gẹgẹ bi atẹjade lati ileeṣẹ ọlọpaa se sọ, gun Habeeb lọbẹ lọrun lori ija to waye laarin wọn.

Ki lo se okunfa isẹlẹ naa:

Iwadii fi han pe digi Cynthia kan ti o sọ pe Habeeb mọọmọ fọ, lo da ija silẹ to fi pa arakunrin ẹni ọdun mejidinlogun naa.

Ija iwọ lo fọ digi mi yii lo di ranto, ti Cynthia si wọ ile idana lọ lati lọ mu ọbẹ to fi gun oloogbe naa lọrun.

Igbe ara adugbo ati ipe sọdọ ọlọpaa lo jẹ ki wọn sare mu Cynthia, ti wọn si sare gbe Habeeb, ti ẹjẹ ti bo lara lọ si ile iwosan.

Nigba ti wọn yoo fi de ile iwosan, dokita fidi rẹ mulẹ pe o ti jade laye ti wọn si ti gbe oku rẹ lọ si ile iwosan nla to wa ni Ifọ, lati se ayẹwo ohun to ṣeku pa.

Ẹwẹ, Kọmisana ọlọpaa CP,Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe ẹjọ yi lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ fẹkunrẹrẹ iwadii.