You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn 26 kú nígbà tí wáyà iná já lé wọn lórí láàrin ọjà ní DR Congo
Ko din ni eeyan mẹrindinlọgbọn to ku lasiko ti waya ina ja le wọn lori ninu ọja kan ni orilẹ-ede Democratic Republic of Congo.
Ọjọru ni isẹlẹ yii waye ni ilu Kinshasha to jẹ olu ilu orilẹ-ede naa, to si ja le awọn ile ati awọn eeyan to wa naja.
Fidio kan to n lọ lori ayelujara ṣafihan ọpọlọpọ eeyan to jọ oku, ninu omi ẹrọfọ ninu ọja naa.
Botilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ nkan to mu ki waya ina hun já, ajọ ina ẹlẹtiriiki ni DR Congo sọ pe o sẹeṣe ko jẹ pe àrá san lu ara waya naa lo mu ko jabọ si ilẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe agbegbe Matadi-Kibala ni Kinshasa ni iṣẹlẹ buruku naa ti waye, ati pe ọpọlọpọ eeyan lo ku loju ẹsẹ.
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- Àwọn ọmọ ogun America pa olórí ISIS, Ibrahim al-Qurayshi ní Syria
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
- Jide Kosoko, Otunba Dodoede n selédè lẹ́yìn Tafa Oloyede tó kú
- Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n lọ́dún tó lọ
- 'A kò le gba ẹlẹ́wọ̀n kankan wọlé mọ́, kò sí òunjẹ tá a fẹ́ fún wọn'
Awọn ileeṣẹ iroyin ni abẹle sọ pe awọn obinrin to wa ta ọja lo pọju ninu awọn to ku.
Agbẹnusọ ijọba ẹkun Kinshasa, Charles Mbutamuntu sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe "waya naa ja, abala to ni ina lara rẹ si ja sinu kòtò kan to kun fun omi àgbàrá ojo to rọ ni owurọ"
Ọgbẹni Mbutamuntu sọ pe wọn ti ko awọn oku lọ si mọṣuari, ti iwadii si ti n lọ lori iṣẹlẹ ọhun.
Olootu ijọba,