You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Amotekun security network: Gani Adams rọ gómìnà Yahaya Bello láti dá Amotekun sílẹ̀ ní Kogi
Aarẹ Onakakafo ilẹ Yoruba ti rọ gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, lati da ẹṣọ Amotekun silẹ ni ipinlẹ naa.
Aarẹ ni ẹṣọ Amotekun yoo ṣe iranwọ fun ijọba lati koju eto abo to mẹhẹ ni Kogi.
Gani Adams sọrọ yii nibi apero ẹgbẹ Oodua Progressive Union(OPU) ti akori rẹ jẹ Kabba 2022 eyi to waye niluu Lokoja lopin ọsẹ to kọja.
- Àwọn ọlọ́pàá ti parí ìwádìí ikú Timothy Adegoke, ká lọ sílé ẹjọ́ pẹ̀lú afurasí mẹ́fa tí wọ́n mú ló kù báyìí- Agbejoro Timothy
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Deji Akure tó lu aya rẹ̀ lójú títì, tí wọn rọ̀ lóyé, ti jáde láyé
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
- Ọlọ́pàá Ogun mú ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò tó ọdún 20 níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rẹ́bìnrin ọ̀rẹ́ wọn ṣe òògùn owó
Ohun ti Gani Adams sọ ree
''Lootọọ ni pe ko si rukerudo ni ipinlẹ Kogi lọwọ yii, amọ o ṣe pataki lati ri i pe eto abo to munadoko wa.
Mofi asiko yii rọ gomina Kogi lati ṣe idasilẹ ẹṣọ Amotekun gẹgẹ bi o ṣe wa kaakiri awọn ipinlẹ Yoruba.
Ti o ba wu u, gomina le fun ẹṣọ eleto naa ni orukọ to ba fẹ.
Amọ, o dami loju pe eleyii yoo ṣe iranwọ nipa riran ijọba apapọ lọwọ lori ipese abo to peye nipinlẹ Kogi,'' Iba Gani Adams lo sọ bẹẹ.
Aarẹ Onakakafo ko ṣai gboriyin fun gomina Bello lori iṣẹ takun takun to n ṣe lori ọrọ-aje ipinlẹ naa.
Gani Adams ni apero OPU to waye ni Kabba ti jẹ ki ọpọ eeyan to wa nilẹ okeere mọ si nipa ipinlẹ Kogi.
Iṣẹ awọn ẹṣọ eleto abo Amotekun nilẹ Yoruba
Ọgagun ọga awọn Amotekun nilẹ Yoruba, Oloye Adetunji Adeleye ṣalaye lọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun 2021 pe ẹṣọ eleto abo naa yoo bẹrẹ si ni maa kaakiri ibode awọn ipinlẹ Yoruba.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Adeleye sọ pe awọn gomina ti pese ọkọ tawọn maa lo fun iṣẹ yii.
O tun fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe wi pe awọn maa ṣiṣẹ ileeṣẹ aṣọbode.
'Amotekun nikan kọ lo maa ṣiṣẹ yii, awọn ọlọpaa, DSS ati Civil Defence yoo fọwọ sowọpọ pẹlu wa lati le gbogun tawọn adigunle loju popo.
Ṣe ẹ mọ pe idasilẹ Amotekun wa fun iranwọ fawọn agbofinro ni tẹlẹ.
Ofin to gbe wa kalẹ sọ pe ibi ti apa ba ti n ro wọn ni ki a ti ba wọn gbe e soke.
Awọn eṣọ Amotekun to wa ni ipinlẹ Osun yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn to wa ni Oyo, awọn ti ipinlẹ Oyo naa yoo gbera lọ si Ondo, bi a o ṣe maa ṣee niyẹn,'' Oloye Adeleye ṣalaye.
''Amotekun yóò máa ṣọ́ ibodè àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá láti máwọn ọ̀daràn àti ajínigbé.
Igbesẹ yii gbaye lati pese abo to munadoko kaakiri ilẹ kaarọ o jiire.''
Ọgagun ẹṣọ Amotekun ipinlẹ Ondo to tun jẹ alaga awọn ọgagun Amoteukun nilẹ Yoruba, Adetunji Adeleye lo fidi ọrọ yii mulẹ.