Ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn: Ipá wò ní ''Voodoo'' n kò ní ìgbé ayé àwọn èèyàn Adúláwọ̀?

    • Author, Papa Atou Diaw
    • Role, BBC Afrique

Gbogbo wa lo ṣeeṣe ki a to wo ere fiimu nibi ti wọn ti n fi oogun de eeyan mọlẹ yala nipa ọmọlangidi tabi lilo afọṣẹ.

Awọn nkan taa n ri ninu ere fiimu yi bi ki Abija fi afọṣẹ ati ọfọ koju Fadeyi Oloro, njẹ o jẹ ẹkunrẹrẹ alaye ohun taa n pe ni oogun ibilẹ bii?

Apilẹkọ yi yoo ṣagbeyẹwo oogun tabi ooṣa to gbajumọ ni Benin Republic ti wọn n pe ni Voodoo.

Ileeṣẹ BBC kan si Ọjọgbọn Dodji Amouzouvi to jẹ olukọni lẹka imọ awujọ ni fasiti Abomey-Calavi, nilẹ Benin, lati mọ nipa ẹda iṣẹṣe ati oogun ibilẹ ti wọn pe ni Voodoo ati ohun to tunmọ si gaan.

Ki laa n pe ni Voodoo,oogun abẹnugọngọ?

Bi ooṣa ni Voodoo jẹ, ohun awamaridi rẹ, iṣẹsẹ ilu.

Ooṣa nii ṣe.Ọna kan gboogi tawọn adulawọ n ṣamulo lati fi wa idahun sawọn ibeere to niṣe pẹlu ijẹmọniyan. Ta laa jẹ? Nibo la ti wa, nibo laa n lọ? Ki si ni afojusun wa?

Ibaṣepọ yi jẹ eleyi to n sayẹwo laarin awa eeyan ati aṣẹda to ka ile ka oko, awamaridi,alaye lọrun.

Voodoo kii ṣe ere taa gbe kalẹ ti wọn so nkan mọ lara baa ṣe maa n ri ninu awọn ere sinima.

Voodoo kii ṣe nkan daada kii si ṣe aburu, Ọlọrun ni Voodoo.

Voodo gẹgẹ bi ooṣa kii ṣe ẹsin ibilẹ,kii ṣe aṣa, kii ṣe irori, kii ṣee ṣe ẹgbẹ imulẹ. Yala, Voodoo lo mu aṣa wa, lo da ẹsin silẹ.

Aṣiwi ni ka sọ pe a fi Voodoo we ẹsin.Ẹsin, ẹgbẹ imulẹ gbogbo awọn nkan ta ri yi, latara Voodoo ni wọn ti wa. Agbarijọpọ wọn laa n pe ni Voodoo ni Benin Republic.

Ibaṣepọ wo lo wa laarin Voodoo ati oṣo?

Voodoo ko ni nkankan ṣe pẹlu oṣo tabi ajẹ. O le ni awọn apilẹkọ kan to sọ pe ajọsepọ wa laarin wọn.

Awọn oniwaasu Kristẹni to kọkọ de si ilẹ Afrika nigba naa lọhun lo kọkọ pe igbagbọ ti ko labawọn to yatọ si eleyi tawọn n tẹle yi ni Voodoo.

Ati awọn tilẹ Yuroopu atawọn amunisin lati ilẹ Fraanse, wọn doju ọrọ igbagbọ yi ru gidi gaan.

Tawọn ilẹ Faranse lo buru julọ nitori wọn sọ pe awọn alawọdudu ko le ni aṣa,igbagbọ, ẹsin, itan tabi ẹmi tara wọn.

Ki wọn baa le ri nkan ti wọn n wa nilẹ Afrika ni wọn fi sọrọ yi.

Nigba ti ilẹ Afrika ati ilẹ awọn alawọfunfun koju ara wọn, awọn alawọfunfun lo bori.

Wọn bori debi pe wọn sọ wa dẹni tiu ko fẹran ara rẹ, wọn mu wa gbagbe ẹsin, igbagbọ wa eleyi ti wọn tẹnbẹlu pe nkan buruku, nkan eṣu ni.

Wọn mu wa gbagbọ pe eleyi buru pupọ nitori awọn to n sọrọ yi mọ pataki ki eeyan ma gbagbe orisun rẹ.

Wọn mọ pe ọna taa fi le ja ara wa gba ni ka ma gbagbe ipilẹsẹ wa. Wọn mọ pe taa ba fi le moribọ lọwọ iru ero yi, ko le e ṣe wọn lanfaani.

Torinaa wọn de pẹlu ọrẹ,ibọn ati awọn nkan aburu miran...wọn sọfun wa pe Jesu lọna ati iye ati pe nkan to ko dara ni voodo ibilẹ wa, nkan okunkun nkan ti ko dara.

Bi o ba ṣe pe a gba pe ko si aṣa kan tabi iṣẹṣe kan to dara ju ekeji lọ, wi pe awọn aṣa yatọ lati ibi kan si omiran, ki wa lo de tawọn ooṣa ninu aṣa awọn kan yoo ṣe wa dara ju tawọn mii lọ?

Ko jọ ọ rara. A gbọdọ wa ọna taa fi jijọ gbe papọ ni.

Alaye wo lo wa nipa bi Voodoo ti ṣe wa nilẹ Amẹrika?

Owo ẹru ti wọn fi gbe awọn babanla wa lọ si Amẹrika la le fi ṣe alaye bi Voodoo ṣe de ibẹ.

Ni Amẹrika, gbogbo nkan to so mọ Voodoo ṣi wa ni ṣẹpẹ ṣugbọn wọn ti ṣafikun awọn nkan to wa lagbegbe ibi to wa kun un.

Koda nigba miran wọn a maa ṣe awọn nkan mii ti a ko le ro pe o ṣeeṣe.

Bi apẹrẹ wọn da iṣẹṣe Voodoo papọ mọ igbagbọ inu ẹsin Kristẹni debi pe wọn lawọn wooli ninu ẹsin Voodoo lọdọ wọn bi ti Kristẹni.

Alaye ti mo le ṣe fun ọrọ yi ko ju pe ibi gbogbo ni Voodoo ta egbo de.

Awọn ooṣa wo lo wa ninu imulẹ Voodoo?

Ọpọlọpọ ooṣa la le ri ni agbami Voodoo.

Ọkọọkan awọn ooṣa yi lo ni ohun to jẹ agbara ti wọn lọtọ ti wọn mu wa lati ọdọ Eledumare eleyi to yatọ si Ọlọrun tawọn musulumi tabi Kristẹ ni n doju adura kọ.

Bẹẹ la si le bẹ awọn irunmọlẹ tabi ooṣa yi ni iṣẹ ọtọọtọ fun idi ọtọọtọ.

Wọn pọ debi pe tabi naa ka maa sọ nipa wọn yoo gbawa lasiko.

Lafiwe nkan ti a n sọ yi ni ṣoki lawọn ooṣa bi Obatala, Sango, Eṣu ọdara, Ṣanpọnna ati awọn miran to ni ohun ta mọ wọn si.

Bawo ni voodoo ṣe ri lode oni?

Jakejado agbaye lawọn to n tẹle voodoo pọ si .

Ẹsin to kari aaye kale ka oko ni.Igbagbọ ninu Voodoo tabi idari pada si ẹsin yi jẹ ohun ti a maa n ri kaakiri paapa to ba jẹ pe ilẹ adulawọ lo ti ṣẹ wa ni paapa lagbegbe kan Naijiria tabi lorileede Benin.

Nkan to se pataki lo jẹ fawọn to gba Voodoo gbọ ti wọn si fi iru oju bẹẹ wo.

Latara Voodoo ni wọn ti n ri aabo,idagbasoke ati ijẹmọniyan wọn.

Voodoo lo n dari igbe aye wọn to si n fun ni itunmọ.