You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ẹjọ́ gba béèlì akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College márùn ún tó ń jẹ́jọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni
Awọn akẹkọọ marun ti ọlọpaa mu lori iku akẹkọọ ile ẹkọ girama Doyen College nilu Eko, Sylvester Oromoni ti foju ba ile ẹjọ bayii.
Wọn gbe awọn akẹkọọ marun un naa lọ si ile ẹjọ lori ẹsun igbimọpo ṣiṣẹ ibi ati ṣiṣekupa Sylvester Ọrọmọni.
Lẹyin ọpọ atotonu ile ẹjọ Majisireeti agba to wa ni Yaba nilu Eko gba beeli ọkọọkan wọn pẹlu Miliọnu kan naira.
- Ṣé oyún ní Aisha Buhari ni àbí àìsàn jẹjẹrẹ tàbí kí ló fa ẹ̀jọ́ lórí ikún aya Aàrẹ Buhari?
- Damola Olatunji fojú balé ẹjọ́, wọ́n ní ó dúnkokò mọ́ ọlọ́pàá, wọ́n tún ka àwọn ẹ̀sùn míì si lẹ́sẹ̀
- Ìdí rèé tí Buhari fi kọ̀ láti buwọ́lu àbá àtúnṣe ètò ìdìbò Nàìjíríà
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
- Àbùkù ńlá ni ikú Sylvester Oromoni jẹ́ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó- ìyàwó Gómìnà Sanwo-Olu
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
Ni ọjọ kẹsan an, oṣu kejila ọdun yii ni wọn ko awọn akẹkọọ naa si ahamọ awọn majesin, Juvenile home lori ẹsun naa.
Adajọ Majisireeti agba Ọlatunbọsun Adeọla to gbọ ẹjọ naa fi aye silẹ fun beeli wọn pẹlu oniduro meji-meji.
Adajọ Majisireeti agba Adeọla ṣalaye pe ọkan lara awọn oniduro akẹkọọ kọọkan gbọdọ jẹ obi wọn, ti wọn si gbọdọ ṣe iwe adehun lati tẹle ilana naa.
Bakan naa lo tun paṣẹ ki wọn gba gbogbo iwe irinna silẹ okeere wọn si ile ẹjọ, ki wọn si ṣe ifidimulẹ ootọ adirẹsi ile ti wọn ba fi silẹ wọn ko si gbọdọ rin jinna kọja kilomita meji si ile ti wọn n gbe nigba gbogbo.