Baba Ijesha: Agbẹjọ́rò olùjẹ́jọ́ ní ẹ̀rí tí olùpẹ̀jọ́ gbé wá sílé ẹjọ́ kò tọ̀nà lábẹ́ òfin

Igbẹjọ́ Baba Ijesha ń tẹsiwaju loni ọjọ́ kejì oṣù Kejìlá ọdún 2021 nílé ẹjọ gíga to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan alawada naa niluu Eko.

Igbẹjọ ọhun ní wọn sún si oni nítorí pe awọn agbẹjọro Baba Ijesha ko faramọ ẹri ti awọn agbẹjọro olupẹjọ mu wa siwaju ile ẹjọ.

Atako naa lo wa lori akọsilẹ ti wọn gba lẹnu rẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Niwaju adajọ Oluwatoyin Taiwo ni agbẹjọro Baba Ijesha, Kayode Olabiran ti ṣalaye pe awọn ko gba ẹri ti agbẹjọro olupẹjọ gbe wa sile ẹjọ nitori ko ba ofin mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ipo ti olujẹjọ wa lasiko ti wọn n gba ọrọ lẹnu rẹ, kii ṣe eyi to ba oju mu labẹ òfin.

O ni "tí eniyan ba wa ni iru ipo bẹẹ, ko si ni ọkan pipe, iru ẹni bẹẹ si le sọ nnkan ti ko se.

Olabiran wa rọ ile ẹjọ lati mu ẹri naa kuro lara agbeyẹwo ti yoo sọ ibi ti ẹjọ yoo yọri si.

Lasiko igbẹjọ toni, ti ko ju isẹju mejidinlogun lọ, ni agbẹjọro Princess tii se olupẹjọ ti ṣalaye pe onibara oun ko fipa mú Baba Ijesha.

O ni Baba Ijesha gan fi ẹnu ara rẹ sọ fun ile ẹjọ pe awọn ti ọrọ ṣe oju wọn ni adugbo Princess lo fi ọwọ kan oun, kii se agọ ọlọpaa ni wọn ti na oun.

Agbẹjọro naa ni fun idi eyi, ko si idi ti Baba Ijesha ṣe yẹ ki o wa ni ibẹru bojo lasiko ti wọn n gba ọrọ ẹnu rẹ silẹ.

Bakan naa ni agbẹjọro olujẹjọ tun rọ ile ẹjọ pe awọn tun ni ẹlẹ́rìí miiran ti àwọn fẹ mu wa ile ẹjọ lati jẹri si ọrọ to wa nilẹ.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeeji ni adajọ Oluwatoyin Taiwo sọ pe ki awọn olujẹjọ ati olupẹjọ lọ ṣe akojọ gbogbo ẹri wọn.

Adajọ ni ki wọn si pada wa si ile ẹjọ ni ọjọ kẹẹdogun osu Kejila ọdun 2021 lati sọ boya oun yoo gba ẹri naa wọle tabi wọn yoo danu.

Igbiyanju ileesẹ BBC Yoruba lati ba agbẹjọro olupẹjọ sọrọ lẹyin igbẹjọ lo ja si pabo, bi wọn ṣe kọ lati ba awọn Akọroyin sọrọ.