Fashola ṣàlàyé ọ̀nà tuntun tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà gbé kalẹ̀ tí o fi lè di onílé

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria yoo bẹrẹ tita awọn ile alakọra labẹ eto ikọle ọlọpọyanturu ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria, National Mass Housing Programme.

Gẹgẹ bi minisita fọrọ iṣẹ ode ati ileegbe, Babatunde Raji Fashọla ṣe sọ, awọn ile naa yoo bẹrẹ lati ori miliọnu meje ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (N7.2 million).

Minisita Fashọla ṣalaye lasiko ti wọn n ṣi oju opo ayelujara fun eto ikọle naa nilu Abuja pe eyi yoo fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lanfani ati ra ile laisi iyanni ni pọsin tabi ṣegbe rara.

Bakan naa lo tun ṣalaye lori eto mohunmaworan abẹle kan pe iriri ti ko ṣee fi sẹnu rẹrin eyi tawọn ọmọ Naijiria ti doju kọ labẹ irufẹ eto yii tẹlẹ lo mu ki wọn gbe e lọ sori ayelujara.

O ni awọn ile yii wa kaakiri orilẹede Naijiria pẹlu afikun pe eyi ti owo ori rẹ pọ julọ ni miliọnu mẹrindinlogun ati ẹgbẹrun lọna aadọwa Naira. (N16.19 million).

Bakan naa ni Minisita Fashọla ṣalaye pe awọn ile bii ẹgbẹrun marun un ni wọn ti n kọ ti wọn si ti fẹrẹ pari kaakiri Naijiria.