Sunday Igboho: Ẹ̀yin oríadé ẹ dìde, wàhálà ń bọ̀ nílẹ̀ Yorùbá, ọ̀dọ́ 10m fẹ́ jà fún Igboho

Yoruba ni bi wọn ba le ewure titi, to fi sun kan ogiri, yoo pada bu olowo rẹ jẹ ni.

Owe yii ni awọn alatilẹyin ajijagbara fun iran Yoruba kan, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Igboho n pa fun ijọba apapọ.

Bẹẹ ba gbagbe, Sunday Igboho lo ti wa ni ahamọ ọgba ẹwọn nilu Cotonou fun bii osu mẹta bayii, ti ẹjọ rẹ ko si fori sọ ibi kankan.

Bakan naa ni ijọba Naijiria kede lọjọ Ẹti pe oun ti mọ awọn eeyan to n se atilẹyin fun Sunday Igboho lati maa jijagbara.

Lara awọn eeyan to si darukọ pe o n ti Igboho lẹyin ni ọmọ ile asofin agba kan ati eeyan kan ti wọn lo n se onigbọwọ fun ikọ Boko Haram.

Nibayii, asaaju awọ̀n eeyan to jẹ alatẹle Sunday Igboho ti wa kede pe awọn ọdọ to le ni miliọnu mẹwa ti setan lati ja fun asaaju wọn naa.

Alhaji Yusuff Saheed Ajikobi, to n se akoso Sunday Igboho lo sisọ loju ọrọ yii fun BBC Yoruba lasiko ifọrọwerọ kan.

Ajikobi ni awọn ọdọ naa ti setan lati woju ijọba, ki wọn si bẹrẹ si fa wahala lẹsẹ lati pe fun idande Sunday Igboho.

O ni Igboho ko sẹ amọ ti ijọba ba ni o sẹ awọn, se ni ki wọn tete fi ori jin, ki wahala to fọn ina soju.

"Awọn ọdọ yii ni inu n bi tori bi wọn se ti Sunday Igboho mọle lainidi amọ awa la n di wọn lọwọ mu pe ki wọn ni suuru na, ki wọn mase da wahala silẹ.

Awọn ọdọ to jẹ atẹle Sunday Igboho yii ri gbogbo ohun to n lọ nilẹ Igbo lapa ila oorun guusu Naijiria, ti wọn si ti setan lati da irufẹ wahala yii silẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria pẹlu.

Ba si se n mu wọn lọwọ silẹ yii lati mase fa wahala ni wọn ti n ri wa bii ọdalẹ, nitori wọn gba pe iku ya ju ẹsin lọ.

Ijọba ti mu ki aye nira pupọ fun awọn ọdọ, ti wọn ko si fi bẹẹ ni ireti kankan mọ ninu ilẹ Naijiria.

Koda, awọn eeyan wa ko bẹru awọn osisẹ agbofinro mọ ni akoko ta wa yii, ti ohun gbogbo si ti dẹnu kọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbogbo awọn isẹlẹ yii ati bi wọn se fi Sunday Igboho si ahamọ laini ẹsẹ kankan lọrun pato lo n sun awọn ọdọ naa kan ogiri lati ja."

Alhaji Ajikobi wa n ke si awọn oriade nilẹ Yoruba ati awọn oloselu lati tete dide si ọrọ yii ko to pẹ ju.

O ni yoo dara ki wọn rọ ijọba lati tete tu Sunday Igbogbo silẹ ni ahamọ ko to pẹ ju, ko le lọ gba iwosan to yẹ.