You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Ọjọ́ méje ní áńkọ̀bù fi wà lọ́wọ́ mi táwọn agbẹjọ́rò mi kò sì rí nǹkan ṣe si
Ilumọọka ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho ti n fi apa janu pe agbẹjọro oun, Amofin Salami ko yọju si oun fun bi osu meji, to si pe ara rẹ ni agbẹjọro oun.
Sunday Igboho lo n fi apa janu bẹẹ ninu fọnran ohun rẹ to lu ori ayelujara pa nilu Cotonou lorilẹede Benin, nibi to ti wa ni ahamọ.
Igboho, ẹni to kede bẹẹ lasiko ti amofin Salami yọju si lọgba ẹwọn lẹyin ọpọlọpọ ọjọ tun ni n se ni agbẹjọro naa tun n fi oun ba ẹlomiran sọrọ fun bii isẹju mẹẹdogun nigba ti oun yọju si.
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
- Sunday Igboho àti aya rẹ́, Ropo ni ọlọ́pàá Interpol mu ní Cotonou - Agbẹjọ́rò
- Iṣẹ́ wa rèé lábẹ́lẹ̀ láti gba ìdáǹdè Sunday Igboho ní Cotonou - YCE
- 'Ó sàn fún wa kí Sunday Igboho kú sí Cotonou ju kí wọ́n dáa padà sí Nàìjíríà lọ'
- Wo àǹfàní tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fún ìyàwó Sunday Igboho ní Cotonou
- "Ẹ̀yin àgbà amòfin nílẹ̀ Yoruba, ẹ kó lọ sí Cotonou láti gbèjà Sunday Igboho"
Ajafẹtọni naa, to n fi ẹjọ amofin yii sun eeyan kan ninu fọnran oun naa ni idi ree ti oun fi sọ fun pe oun fẹ lọ jẹun, to si ni oun le maa lọ lasiko to n ba ẹni naa sọrọ fun ọpọ isẹju.
Awọn agbẹjọro mi kọ ni Ọlọrun, to ba wu wọn, ki wọn jawọ:
Wayi o, Sunday Igboho ti wa n i apa janu pe awọn agbẹjọro oun ko ni agbara lati gba oun silẹ lọwọ adajọ.
O ni bi gbogbo wọn se pọ to, oju wọn bayii ni adajọ se ni ki wọn maa gbe oun bọ lọgba ẹwọn lai jẹ pe wọn ri nnkan se si.
Igboho fikun pe awọn agbẹjọro naa kii se Ọlọrun nitori wọn ko ni agbara lati sọ fun adajọ pe ko ma gbe oun lọ si ọgba ẹwọn.
"Bi gbogbo awn lọya naa se pọ to, bii mẹwa, soju wọn ni adajọ se n gbe mi bọ ni ọgba ẹwọn, se Lọya nu?
Oju wọn ni wọn fi so ankọbu mọ mi lọwọ fun ọjọ meje, wọn ko ri tu afi igba ti amofin Falola to de, se awọn Lọya nuu?
Kee si se owo kekere ni wọn gba. Eyi to gba miliọnu marun, miliọnu mẹrin, bi wọn se gba owo lọ̀ niyẹn amọ wọn ko le tu ankọbu lọwọ mi.
Lai jẹ pe mo jale tabi se nnkan kan, emi ko bẹru Lọya tabi ẹnikankan. Gbogbo ara ti wọn ba fẹ fi mi da, mo ti wa pẹlu wọn."
Agba amofin mejilelogoji lo n se ẹjọ mi ni Ibadan:
O ni se ko yẹ ki agbẹjọro naa maa yọju si oun loore koore gẹgẹ bi oun se jẹ onibara rẹ ti wọn fi si ahamọ ọgba ẹwọn.
"O wa de ọdọ mi nibi yii, o n fi mi ro ẹjọ, to ba jẹ eeyan nla nibi yii, ko le jẹ eeyan nla to mi, ẹnu ilu yii nikan ni wọn ti mọ oun.
Agbara wọn kọ lo gbe mi debi, agbara Benin si kọ lo mu mi silẹ, o wu Ọlọrun bẹẹ ni. Ọlọrun lo mu mi silẹ funra rẹ, oun lo gbe mi wa sibi, oun naa ni yoo yọ mi nibi."
Igboho ni oun ni awọn agbaagba amofin ni Naijiria, ti oun maa n dari wọn, ti wọn si maa n wa ba oun ninu ile oun, ti oun si maa n ran wọn nisẹ.
"Ẹ wo iye amofin to n lọ se ẹjọ mi ni Ibadan, agba agbẹjọro mejilelogoji lo n lọ duro fun mi, ti n ko si tii fun wọn ni sile kan bayii ti n dan.
Mo dẹ n bori awọn ẹjọ naa ni, ni isẹju isẹju ni mo n bori ijọba apapọ nile ẹjọ nigba to jẹ pe Ọlọrun lo n sisẹ rẹ.
Gbogbo ẹyin baba mi naa ko si dakẹ adura, ti Ọlọrun naa si n gbọ adura yẹn. Mo tun na Malami pa ni ẹjọ kotẹmilọrun to pe.
Nigba to ya lo n sẹ pe oun kọ loun ran sọja tabi wa sile DSS lọ sile mi, ti oun kii si se Fulani tabi Hausa.
Adajọ wa koro oju si pe ki lo de ti wọn lọ sile mi loru, armoured tank ni wọn fi fọ ogiri wọle, ki lo de, n ko paayan, n ko jale, n ko si se nnkan kan."
N ko pa Fulani ri tabi lo ibọn lasiko iwọde Yoruba Nation:
Sunday Igboho ni oun ti oun sọ fun wọn ni pe iya ti wọn si n jẹ Yoruba ti to, awọn ko se mọ, bẹẹ Fulani si n pa Yoruba ni ipakupa lawọn ilu bii Saki, Igboho.
O ni oun wọ inu igbo lọ lati le wọn funra oun ni, ti ijọba ko si ni ẹri lati sọpe ibi ti oun ti pa Fulani ree nitori gbogbo iwọde ti oun n se, oun ko gbe ibọn lọwọ nibẹ.
"Ohun ti mo n sọ fun yin ni pe awa la ni epo, awa la ni gbogbo nnkan, ki lo de to se jẹ pe awa lẹ n fiya rẹ jẹ, awa lẹ n pa.
Gbogbo Naijiria ti daru, a le rin ni alẹ amọ a ko le rin ni alẹ mọ nisinyii, ẹ ko gbọdọ ni ẹ n bọ lati Eko wa si Ibadan mọ lalẹ, Fulani maa pa gbogbo ẹni to wa ninu mọto ni.
Wọn yoo wa ji awọn eeyan gbe lọ sinu igbo, wọn yoo ni ki wọn lọ mu miliọnu lọna ọgọrun naira wa, iru igbesi aye wo la n gbe lọ ni Naijiria yẹn."
Sunday Igboho ni oun ti oun n ba ijọba fa niyẹn, ko si ti pọ ju debi pe wọn yoo wa maa ni ki wọn lọ pa oun nigba ti kii se pe awọn lo ni mi oun lọdọ wọn.
Baba mi loogun bii Sanpọnna, talaka ayeraye si ni amọ o ku:
Sunday Igboho ni oun ko bẹru ẹnikẹni nitori talaka ayeraye ni baba oun, to si ni oogun bii Sanpọnna amọ o ku naa ni.
"Ki n to wale aye, gbogbo irinajo mi ni Ọlọrun ti kọ si ori mi, ki iya mi to bi mi, pe bi maa se rinrin aajo aye mi ree.
Lọjọ ti wọn bi mi, ti wọn n ko mi jade, ti wọn ba sọ fun iya ati baba mi pe ọmọ tẹ bi yi o, yoo lowo, yoo si ni okiki, aye yoo si mọ.
Baba mi yoo sọ pe ọna wo lo fẹ gbe gba pẹlu ile ahoro ti wọn n gbe, ẹ wa wo lonii yii, se awọn wa ni Ọlọrun ni."
Sunday Igboho wa ni ki araye wa wo oun lonii, ki wọn wo oun ti oun da, eyi to fi han pe ọwọ Ọlrn ni ohun gbogbo wa, to fi mọ iku ati aye oun.