Channels TV: Ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels ti sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó ní DSS ti gbé òṣìṣẹ́ wọn

Iroyin to lu ayelujara pe ni irọlẹ Ọjọbọ ni pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti gbe awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ amohunmaworan Channels TV to n tukọ eto Sunrise Daily.

Iroyin naa sọ pe igbesẹ yii ko ṣẹyin ifọrọwerọ pẹlu gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom eleyii to bẹnu atẹ lu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari papaa julọ lori eto abo to mẹhẹ.

Ile iṣẹ amohunmaworan Channels TV ti sọ pe iroyin ofege lasan ni.

Wọn ni ko si oṣiṣẹ Channels ti ajọ DSS gbe ṣugbọn ajọ to n ṣakoso igbohun safẹfẹ lori radio ati ẹrọ amohunmaworan, NBC ranṣẹ pe awọn to n tukọ eto Sunrise Daily lati ṣe ipade pọ.

Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ naa si pada si ẹnu iṣẹ wọn lẹyin ipade pẹlu ajọ NBC niluu Abuja.

Ẹwẹ, ajọ DSS naa ṣalaye ni Ọjọbọ pe ko si ohun to jọ pe ajọ naa mu awọn oṣiṣẹ Channels TV meji.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ DSS, Peter Afunaya fi sita, o ṣalaye ajọ naa ti gbọ iroyin to n tan kalẹ lori ayelujara pe awọn ti mu oṣiṣẹ Channels Tv meji.

''Irọ funfun balau ni eleyii, o ṣi le ṣi awọn eeyan lọna.

Ẹyin ti ẹ n gbe iroyin ayederu kaakiri, ẹ jawọ lapọn ti ko yọ,'' Afunanya lo sọ bẹẹ.