Animal census: Ìjọba pàṣẹ pé kí wọ́n ka gbogbo ẹranko igbó àti ẹja inú omi

Eto ikaniyan ni a maa n gbọ, e wo tu ni ti ẹranko kika?

Bi ọrọ yii ti n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi niyii lẹyin ti ijọba orilẹede Kenya paṣẹ pe ki wọn ka gbogbo ẹranko igbo ati ẹja inu omi to wa lorilẹede naa

Igbesẹ yii waye lati le dẹkun bi awọn eeyan kan ṣe n pa awọn ẹran naa ni ipakupa.

Orilẹede Kenya to wa lapa ila oorun ilẹ Afirika ni ọpọlọpọ ẹya ẹranko ti ko wọpọ lagbaaye.

Kiniun ati agunfọn wa lara awọn ẹranko ti awọn eeyan n pa ni ipakupa lorilẹede Kenya.

Orilẹede Kenya nikan ni agbanrere funfun meji to ku lagbaaye wa bayii.

Ọpọ ẹja nla ''whales'' ati ''dolphins'' to fi mọ oriṣiiriṣii ijapa inu omi lo wa lawọn odo lorilẹede Kenya.

Akọroyin BBC, Ferdinand Omondi ṣalaye pe Kenya ti n gbiyanju lati ka awọn ẹranko kan tẹlẹ.

Ṣugbọn igba akọkọ ree ti Kenya yoo ka gbogbo ẹranko inu igbo ati ẹja inu omi.

Igbesẹ yii waye lati daabo bo awọn ẹranko yii ki awọn arinrin ajo afẹ le maa lanfaani lati ri wọn.

Minisita ile iṣẹ ijọba to n ri si irin-ajo afẹ lorilẹede Kenya, Najib Bala ṣalaye pe ''mimọ iye ẹranko ti a ni ni ijọba fi le ṣeto iṣuna fun itọju wọn.''

Ṣugbọn eto naa ko rọrun nitori ẹgbẹẹgbẹrun ẹranko igbo to wa kaakiri orilẹede Kenya.

Ọkan lara ọna ti wọn fẹ lo ka awọn ẹranko yii ni fifi baalu ka wọn lati oke.

Akọroyin BBC, Omondi ni o ṣoro lati mọ iye erin to wa ninu igbo ẹranko ni Kenya.

O ṣalaye pe oju ẹsẹ awọn awọn erin ninu igbo ni wọn fi n ka wọn bayii.

Kika awọn ẹja inu omi naa ṣe pataki lati mọ awọn ibi ti awọn ẹranko inu omi ti nilo idaabobo julọ.