Emere celebration: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi àjọ̀dún ẹgbẹ́ Emèrè Onítẹ̀síwájú l'Osogbo

Awọn ẹgbẹ Emere Onitẹsiwaju ti wọn ṣe ajọdun ọdun keji idasilẹ ẹgbẹ wọn nílùú Osogbo.

Ko Si ibo miran ti ajọdun ọhun ti waye ju ile Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon lọ.

Aṣọ leesi funfun balau ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọ nibi ayẹyẹ naa.

Lati gbogbo ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Osun lawọn ọmọ ẹgbẹ Emere Onitẹsiwaju ti pejọ sibi ajọdun ọhun.

Nigba to n sọrọ nibi ajọdun naa, Aarẹ ẹgbẹ Emere Onitẹsiwaju lagbaaye, Iya-osa Oyelola Egbeyemi Elebuibon gboṣuba fun Eledua to jẹ kí ajọdun ṣeeṣe.

Bakan naa ni Iya-oosa tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn oniṣẹṣe to fi mọ awọn adari wọn.

Egbeyemi Elebuibon ni igbelarugẹ aṣa ati ẹsin abalaye lo mu ki awọn pejọ sibi ajọdun naa.

O ni awọn alalẹ ilẹ Yoruba ti fi ìpìlẹ iṣẹ rere le'lẹ fún iran Yoruba

Iya-oosa ṣalaye pe o wa ku sọwọ awọn ọmọ Yoruba lati ri pe aṣa ati ẹsin abalaye ko di ohun igbagbe.

"Ni bayii, awọn eeyan ilẹ Yuroopu, Amerika ati Latin ti bẹrẹ si ni kọ aṣa ati ẹsin Yoruba.

Koda wọn tún n ṣe akitiyan lati fi le awọn ọmọ wọn lọwọ lai tiju nipa rẹ.

O wa ku si awa oni nkan gan an lọwọ láti máa jẹ kí àwon ọmọ ilẹ òkèèrè maa mọ awọn ọmọ wa ni aṣa ati ẹsin Yoruba," Iya-oosa lo ṣalaye bẹẹ.

Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon at'awọn eekan ninu awọn oniṣẹṣe naa wa nibi ajọdun naa.