Nollywood Tonto Dikeh: Ọpọ Obìnrin ní inú wọn kún fún ìbànújẹ lásìkò yìí nítorí wọn kò yó ìfẹ lónà tó yẹ- Tonto Dikeh

Tonto Dikeh to jẹ ojuoge ninu awọn oserebinrin Nollywood ni Naijiria ti sọrọsoke lori ọrọ ifẹ.

O ni ọpọ obinrin ni inu wọn ko dun ti ọkan wan kun fun ibanujẹ lataari ifẹ to ti sọnu.

Tonto ni eyi ko sẹyin nitori pe awọn obinrin ko kọkọ ni ifẹ ara wọn saaju ki wọn to fi ọkan wọn fun ọkunrin kankan.

Tonto Dikeh gba imọran loju opo Instagram ẹ pe ki awọn Obi ati Alagbatọ fi ifẹ han si awọn ọmọbinrin wọn.

O ni ọpọ ni wọn jk onirobinujẹ ọkan latari pe wan ko ri ifẹ lati ọdọ obi wọn, bakan naa ni wọn ko nifẹ ara wọn.

Tonto Dikeh ni oun n fojusona lati bi ọmọbinrin ti oun maa kọ nipa ifẹ ara ẹni saaju ifẹ ẹnikẹni.

O sọ iriri rẹ pe oun la ina kọja ki ọmọbinrin oun ma baa la irufẹ ina kan naa kọja.