Sunday Igboho: Ìkọlù tí ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe sí Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba''

Ọba Ẹlẹrinmọ ti Ẹrinmọ Ijẹsha ni ilu Ekiti, Oba (Dr) Michael Ajayi, Arowatawaya II ti ni inu awọn lọbalọba ko dun si iṣẹlẹ ikọlu si Sunday Igboho to waye laipẹ yii.

Oba (Dr) Michael Ajayi, Arowatawaya II lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ ni nkan to ba ṣẹlẹ si ọmọ Yoruba ẹyọkan, gbogbo wọn ni o ṣẹlẹ si.

O ni awọn lọbalọba ko dakẹ rara, nitori labẹlẹ ni wọn gbe igbeṣẹ lati rii pe opin de ba gbogbo wahala yii.

''Mi o ro pe a dakẹ rara, ọmọ ẹni kii buru ka fi fun ẹkun pa jẹ''.

''Nkan to ba ti ba ẹnikan, o ba gbogbo wa naani, inu wa ko dun si''.

Bakan naa ni Ọba Ẹlẹrinmọ ti Ẹrinmọ Ijẹsha ni nkan ti awọn ẹṣọ alaabo pẹlu atilẹyin ijọba apapọ ṣe si Sunday Igboho ko bojumu rara.

Oba Micheal ni awọn ko fi igba kan gbọ pe wọn fi iwe ipe ranṣẹ si Sunday Igboho, wọn kan dede ṣekọlu si ni oru mọju ni.

O ni awọn ni igbagbọ wi pe awọn aṣoju wọn ni ile aṣofin lorilẹede Naijiria naa n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe iya ko jẹ ọmọ ilẹ Yoruba kankan ni ọna aitọ.