Buhari in Lagos: Irọ́ ni pé àwọn eèyàn mi nìkan ni mo ń fi sípò adarí ní Nàìjíríà- Muhammadu Buhari

Aare Muhammadu Buhari to n tukọ Naijiria lo gbera lati Abuja wa se abẹwo si ilu Eko ni guusu Iwo Oorun Naijiria.

Nibe lo ti kopa ninu eto ifọrọwanilẹnuwo aladase pẹlu ileese Amohunmaworan Arise TV.

Nibi ifọrọwanilẹnuwo yii ni Aare Buhari ti salaye bi oun se n yan awọn eeyan sipo ninu ijọba oun.

Aare ni pe oun kọ lati yan ẹni ti ko koju osuwọn sipo rara.

O ni awọn akọsẹmọsẹ to mọ nkan ti o yẹ ni oun n yan sipo lai naani iran tabi ilu tabi ipinlẹ ti ẹni bẹẹ ti wa ni Naijiria,

Buhari ni o di dandan ki onikaluku sisẹ lati fi amuyẹ han pe oun yẹ nipo ki ijọba to yan iru ẹni bẹẹ sipo.

Idahun yii waye nigba ti wọn beere nipa awọn adari ologun ti Buhari n yan lati ẹya kan nikan.

Orí mi wú pé àkòkò ìjọba mi ní àṣeyọrí reluwé ń wáyé - Buhari

Ibùdókọ̀ reluwé Ekò tó tóbi jùlọ ní West Africa di ṣíṣí

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ifilọlẹ oju ọna reluwe oni kilomita 157, to lọ lati Eko si Ibadan.

Nibi eto naa to waye ni agbegbe ibudokọ reluwe Mobolaji Johnson ni Ebute-Meta, ni ipinlẹ Eko, ni Buhari ti fi idunnu rẹ han lori bi awọn araalu ṣe tẹwọ gba akanṣe iṣẹ naa.

Buhari ni ori oun wu to jẹ pe lasiko ijọba oun ni iru aseyọri bayii n waye ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn eeyan jankanjankan wa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ naa ni minisita fun eto irinna, Rotimi Amaechi, minisita fun aṣa ati iroyin, Lai Mohammed ati minisita fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya, Sunday Dare.

Awọn yoku ni Olori ile aṣoju-sofin, Femi Gbajabiamila, gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, Babajide Sanwo-Olu ti Eko, Seyi Makinde lati Oyo ati Dapo Abiodun lati Ogun.

Eto naa ko yọ aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu, Wole Soyinka ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ mii silẹ.

Ọdun 2019 ni Buhari ti ṣe abẹwo si ipinlẹ Eko kẹhin, lasiko to wa a ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ kan lasiko ijọba Gomina Akinwumi Ambode.

Loni ni ipinlẹ Eko yoo gbalejo aarẹ orileede Naijiria, Muhammadu Buhari to n bọ wa ṣe abẹwo ọlọjọ kan sipinlẹ naa.

Ninu ikede kan ti ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ, Bashir Ahmad fi sita loju opo Koo, o ni aarẹ yoo wa ṣe ifilọlẹ reluwe Eko si Ibadan.

Reluwe yii, to wa ni agbegbe Ebutte Meta la gbọ pe wọn bẹrẹ iṣẹ lori rẹ lati ọdun 2017..

Ibudokọ reluwe Mobolaji Johnson yii ni ibudo reluwe to tobi julọ ni iwọ oorun Afrika, to si le gba to ẹgbẹrun mẹfa ero.

Ko si ikede pupọ ti wọn fi to araalu leti nipa abẹwo yii ṣugbọn o ṣeeṣe ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ waye lawọn agbegbe kan Lasiko abẹwo rẹ

Ni Ọjọru ni ọga agba ọlọpaa Naijiria, Alkali Baba Usman ti balẹ si Eko, to si kan si Gomina Babajide Sanwoolu nile ijọba.

Lasiko abẹwo rẹ to ṣe kẹyin si Eko nigba ijọba Gomina Akinwumi Ambode, ijọba kede isinmi fawọn oṣiṣẹ ki wọn baa le tu yaya jade wa pade aarẹ.

Lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹrin ọdun 2019 ni aarẹ Muhammadu Buhari wa silu Eko kẹyin lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi asaaju ẹgbẹ oselu APC nni, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Ko si ikede isinmi kankan lasiko abẹwo eleyi amọ ibẹru ati inira ti wahala sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ le ko ba araalu, jẹ eleyi to mumu lọkan awọn eeyan.