Ibada EFCC arrest: Àjọ EFCC mú àwọn afurasí oníjìbìtì lórí ayélujára àádọ́ta ní Ibadan

Ajọ to n mojuto iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC ẹka ti Ibadan ni ipunlẹ Oyo ti kede eeyan aadọta ti ọwọ wọn tẹ nilu Ibadan.

Lọjọ Eti, ọjọ kẹrin, osu kẹfa, ọdun 2021 ni wọn ko awọn afurasi naa.

Agbegbe Alaro Sango, Agbaje Ijokodo ati Apete Aladura niluu Ibadan ni ọwọ EFCC ti tẹ wọn.

Adari ẹka iroyin ati ifitonileti fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren lo fi orukọ awọn afurasi naa sita bayii.

Wilson ni awọn mẹrinlelọgbọn ninu wọn ni wọn ti fidi ẹsun naa mulẹ̀ fun pe wọn jẹbi.

Awọn naa ni: Badmus Abeeb, Ibrahim Ahmed, Adeyemo Babatunde, Abdulrashid Ajagbe, Olajide Okiki Peter, Hassan Yusuf Atanda, Yusuf Olasupo Salaudeen, Bello Ahmed Bamidele, Adewale Damilola Tosin, Kolawole Yusuf Olawale, Nicholas Ferdinand, Keshiro Olanrewaju, Falana Victor Dapo, Abogunrin Emmanuel, Bosun Tomiwa Tunde, Shelter Chibundo, Banjoko Idris, ati Adebayo Akorede.

Awọn to ku ninu wọn ni: Awoyinka Afeez Ayodeji, Afonja Olarenwaju, Akingbade Taofeek, Ezekiel Adekunle, Ganiyu Sodiq, Abioye Abiodun, Ogunbayo Daniel, John Timileyin, Ominiyi Daniel, Adeniyi Idris Sodiq, Joseph James, Adeyemi Segun Oluwaseun, Adeleke Rasheed, Saliu Tomiwa Rasheed, Itoro Edet Ime ati Oseni Nasirudeen.

Uwujaren ni EFCC ri awọn ẹru ofin gab lọwọ awọn afurasi to ku naa.

Bakan naa lo ni wọn yoo gbe awọn to ku lọ sile ẹjọ lẹyin ti iwadii ti wọn naa ba ti pari.