Iyabo Ojo: Ẹ yé ṣe àwáwí fún bàbá Ijesha torí pé ó jẹ́ gbajúmọ̀, ohun tí kò dáa, kò dáa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ero awọn osere gbajumọ osere tiata meji lobinrin ti se ọtọọtọ lori isẹlẹ to waye si ọkan lara wọn lọkunrin, James Omiyinka Olanrewaju.

Olanrewaju, ti ọpọ eeyan mọ si baba Ijesha ni ọwọ ọlọpaa tẹ pe o n ba ọmọ ọdun mẹrinla kan lopọ, eyi to ti n se lati igba ti ọmọdebinrin naa wa ni ọmọ ọdun meje.

Ọlọpaa ni lootọ ni osere tiata naa si ti jẹwọ pe bẹẹ ni awọn ẹsun ti wsn fi kan oun ri.

Amọ nigba ti wọn n sọ ero wọn lori isẹlẹ yii ati iha tawọn araalu kọ si, awọn osere tiata meji lobinrin, Iyabo Ojo ati Foluke Daramola ni ero wọn se ọtọọtọ nipa isẹlẹ naa.

Lero ti Iyabo Ojo, o ke si awọn akẹgbẹ rẹ pe ki wọn dẹkun lati maa ṣe awawi fun afurasi naa.

Ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ, Iyabo Ojo ni ohun ti ko dara, ko ni orukọ meji to yẹ ka pe e, biko se aidaa.

Oju ẹni to ba se awawi fun Baba Ijesha, yoo ri ohun ti oju ọm to ba lopọ ri - Iyabo Ojo

O ni "Mo ti ri oriṣiriṣi awọn akọle kan lori ayelujara, nibi ti awọn eeyan ti n da si ọrọ Baba Ijesha, bi awọn kan ṣe n sọ pe ṣe ni wọn ko ba a, lawọn mii n sọ pe ki a ma tii ṣe idajọ rẹ, ki a duro ki awọn agbofinro ati ile ẹjọ ṣe iṣẹ wọn."

"Imọran mi si awọn akẹgbẹ mi ni pe, ki wọn ma ṣe wa awawi kankan fun Baba Ijesha nitori iru iṣẹlẹ bayii ni awọn eeyan kan fi maa n wu iwa ifipabanilopọ, ti wọn a si mu jẹ nitori ẹni ti ọrọ naa kan jẹ gbajumọ lawujọ."

Gẹgẹ bi Iyabo Ojo ṣe sọ, awọn eeyan maa n wa awawi fun awọn afipabanilopọ ṣugbọn ko si awawi kankan fun ẹnikẹni to ba fi ipa ba eeyan lopọ.

Iyabo to sọrọ pẹlu ibinu sọ pe, afipabanilopọ ko ni orukọ meji bi ko ṣe afipabinilopọ, paapaa ẹni to n ba ọmọ kekere lopọ.

Bo tilẹ jẹ o ni oun ko ṣe idajọ Baba Ijesha ṣugbọn o ni "Mo ti gbọ ohun to ṣẹlẹ, o ti n ba ọmọ naa lopọ lati bii lọdun meje sẹyin gẹgẹ bii ọmọ naa ṣe sọ.

Lẹyin naa ni wọn fiwe pe wa sile wọn, ti wọn si dẹ ọdẹ fun pẹlu ẹrọ ayaworan CCTV, o si ko si pampẹ ti wọn dẹ silẹ fun."

Iyabo Ojo sọ pe, ko sẹni to tii le sọ ibi ti ọrọ naa yoo yọri si titi di igba ti iwadii yoo pari, ti ile ẹjọ yoo si ṣe idajọ rẹ.

Amọ o ni ki ẹnikẹni maṣe beere pe ki wọn fi fidio bo ṣe ba ọmọ naa ni ibalopọ lede fun gbogbo agbaye lati wo, nitori ko dara fun ọjọ iwaju ọmọ naa.

O ni ki ẹnikẹni mase ṣegbe lẹyin Baba Ijesha nitori pe o jẹ gbajumọ oṣere, bẹẹ naa lo ni oun koro oju si iwa ti afurasi naa wu, ki ọwọ palaba rẹ to segi.

Iyabo Ojo ni inu maa n bi oun ti awọn eeyan ba n sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe akoba lasan ni wọn fi iṣẹlẹ naa ṣe fun Baba Ijesha.

Lẹyin naa lo fi epe banu wi pe oju ẹnikẹni to ba ti Baba Ijesha lẹyin yoo ri irufẹ ohun ti oju ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn ni o fi ipa ba lopọ ri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbajumọ oṣere naa ṣalaye pe ko yẹ ki ẹni to ba n ni ibalopọ pẹlu awọn ọjẹwẹwẹ maa gbe laarin ilu pẹlu awọn eeyan mii nitori arun ọpọloọ n ba irufẹ ẹni bẹẹ ja.

Iyabọ Ojo pari ọrọ rẹ pe ẹjọ kii ṣe ti ẹni, ka ma mọọ da, nitori naa ki awọn akẹgbẹ ohun nidi iṣẹ tiata duro de idajọ ile ẹjọ lori ọrọ naa, sugbọn ki wọn dẹkun ati maa ṣegbe lẹyin ohun ti ko tọ.

Foluke Daramola ni ki wọn ye se idajọ Baba Ijesha bi wọn ti se fun Baba Suwe

Ẹwẹ, oṣere tiata Yoruba miran, Foluke Daramola naa ti sọ erongba tirẹ lori iṣelẹ naa.

Foluke ni lootọ ni oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa ṣugbọn ẹgbẹ oṣere tiata ti oun wa ko tii ṣe iwadii tiwọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ "Idi ti a ko ṣe tii sọrọ lori iṣẹlẹ naa ni pe ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹrọ CCTV ka iṣẹelẹ naa silẹ, ṣugbọn ko si ẹni to tii foju ganni fidio naa ati pe ẹnikẹni ninu ẹgbẹ oṣere tiata ko tii wo."

"A ko tii gbọ lati ẹnu ẹni ti ọrọ naa kan tabi lati ẹni aṣoju rẹ kankan."

Foluke ṣalaye pe nigba ti wọn fi ẹsun gbigbe oogun oloro kan agba oṣere, Baba Suwe lọpọ ọdun sẹyin, ọpọ araalu lo bẹrẹ si n ṣedajọ Baba Suwe lẹyin ti ajọ NDLEA sọ pe o ya idi oogun oloro mẹrindinogun lagọ wọn ṣugbọn ti ko si ẹri kanka lati fi ẹsun naa lẹyin.

O ni ko yẹ ki ọkankan ninu awọn ọmọ oṣere tiata bẹrẹ si n ṣe idajọ Baba Ijesha nigba ti ile ẹjọ ko tii ṣedajọ tirẹ.

O fi kun pe ọpọ ojuṣe lo wa lori awọn gbajumọ oṣere, nitori naa ki awọn akẹgbẹ oun ṣe mẹdọ lori iṣẹlẹ naa titi ti awọn agbofinro yoo fi pari iṣẹ wọn.

Foluke pari ọrọ rẹ pe, ọrọ ifipabanilopọ kii ṣe ohun ti eeyan le fi ọwọ yẹpẹrẹmu, lai ro ti irufẹ ẹni ti wọn fi ẹsun naa kan.

Lẹyin naa lo gbadura fun gboggbo awọn ti ọrọ naa kan ki Ọlọrun tu wọn ninu, to si sọ pe ki awọn eeyan duro lati ri fọnra bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ ki wọn to bẹrẹ si n ṣedajọ lọwọ ara wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Iyabo Ojo ati Foluke Daramola yii ni awọn kan ti fi ipa ba lopọ ri, iriri naa kii si ṣe eyii to dara gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ṣaaju.

Ọsẹ to kọja ni Baba Ijesha ko si gbaga ọlọpaa lori ẹsun ibalopọ ọmọ ọdun mẹrinla, ti wọn si sọ pe o jẹwọ pe lootọ ni ouns ̣e si ẹsun ọhun.