You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Usman Alkali Baba: Ó yẹ kí ìjọba bẹ̀rẹ̀ owó oṣù tuntun f'áwọn ọlọ́pàá gẹ́gẹ́ bíi ìlérí wọn lásìkò ìwọ́de EndSARS
Awọn ọmọ Naijiria kan ti sọ pe kii ṣe pipaarọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lo le tun eto abo Naijiria to mẹhẹ ṣe, bikoṣe ki ijọba pese awọn ohun to yẹ fun awọn ọlọpaa, bii owo oṣu to niye lori, ile gigbe, ilera to dara, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Nigba to n sọrọ lori ireti awọn ara ilu lori iyansipo adele ọga agba tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Alkali Baba, ajijagbara kan, Kunle Wizeman Ajayi sọ pe aisi abo ounjẹ ati iṣẹ lo fa eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.
O ni ti awọn eeyan ko ba jẹun kanu, ti wọn ko si ni iṣẹ gidi lọwọ, ko sẹni ti yoo le sun ninu ile rẹ.
- Mọ̀ síi nípa bàbá olówó ọmọ Nàìjíríà yii to ni ọkọ̀ òfúrufú mẹfà àti ohun mèremère tí kò lóǹkà láyé
- Kí ló lè ṣekúpa olùkọ́ fásitì Adekunle Ajasin tẹ́lẹ̀ tó dákẹ́ sínú mọ́tò rẹ̀ yìí?
- Ókú ọmọ tí a rí nínú adágún omi igbó kìjikìji ní UK Jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà - Ọlọ́pàá UK
- Haaland báwo? Mbappe ló dáná sun Bayern Munich ráúráú mọ́lé!
Ajayi sọ pe ọrọ ti ọga agba tuntun ileeṣẹ ọlọpaa naa sọ pe oun yoo mu atunṣe nla ba ileeṣe ọlọpaa naa ni gbogbo awọn to ṣiwaju rẹ maa n sọ lai si iyatọ to dantọ ti wọn maa n mu wa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "oun ti a fẹ gbọ ni pe ki ijọba sọ pe awọn ti n san owo oṣu tuntun fun awọn ọlọpaa gẹgẹ bii ileri ti wọn ṣe fu awọn ọdọ lasiko iwọde #EndSARS."
Kunle Ajayi ni "ibere to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria bere lọwọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa tuntun ni pe, ṣe wọn ti ko awọn ọlọpaa onijẹkujẹ to n tọrọ owo loju popo kuro nibẹ?"
"Ṣe ki n ṣe awọn ọlọpaa funra wọn lo n fi owo ara wọn ra aṣọ iṣẹ si ọrun ara wọn".
Ajijagbara naa ni o di igba ti ijọba ba ka awọn ọlọpaa si eeyan pataki, ki wọn maa tọju wọn daadaa ki awọn eeyan naa to le mura siṣẹ.
O pari ọrọ rẹ pe ọga agba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ko le ṣe aṣeyọri ti wọn ko ba ṣetọju awọn ọlọpaa to wa labẹ rẹ to n ṣo awọn eeyan ilu.
O fi kun pe ijọba apapọ tun gbọdọ pese iṣẹ atawọn ohun amayedẹrun fun awọn ọdọ ti ko niṣẹ lọwọ ti wọn ba n fẹ ayipada rere nipa ti eto abo Naijiria.
- Ẹ padà wá o ẹ̀yin ẹlẹ́wọ̀n, ẹni tó bá wá wọ́ọ́rọ́wọ́ yóò rí ìdáríjì, ẹni tí kò bá wá ... - Aregbesola
- Owó àti dúkìá Dongote, Adenuga àti Rabiu tún yarọ síi pẹ̀lú $5.7bn- Forbes
- Tinubu ló lè ṣeé lọ́dún 2023, Pa Fasoranti àti Oba Osemawe Ondo sọ̀rọ̀ sókè
- Ariwo sọọ! Àwọn agbébọn jí ọkọ, ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn gbé l'Ondo
Wo ìpèníjà tí ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun ní Nàìjíríà yóò kojú
Kii ṣe iroyin mọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan Usman Alkali Baba gegebi adele oga agba olopaa tuntun ni Naijiria.
Ohun ti ọpọ n sọ bayii naa ni awọn ipenija marun un to ga ju ti Alkali Baba yoo maa dojukọ lori ipo tuntun naa.
Asiko iyansipo ọga agba ọlọpaa Usman Alkali Baba bọ si asiko ti ipenija ọrọ abo lorilẹede Naijiria n peleke sii.
Ojojumọ ni iṣẹlẹ ijinigbe iṣigun ji maluu, ikọlu laarin agbẹ atawọn darandaran pẹlu ikolu awọn ileeṣẹ ọlọpaa ati ọgba ẹwọn ni ipinlẹ Imo lẹnu lọwọlọwọ yii.
- Wo àwọn Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá tó ti jẹ́ látọdún 1999
- Mọ̀ síi nípa bàbá olówó ọmọ Nàìjíríà yii to ni ọkọ̀ òfúrufú mẹfà àti ohun mèremère tí kò lóǹkà láyé
- Ókú ọmọ tí a rí nínú adágún omi igbó kìjikìji ní UK Jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà - Ọlọ́pàá UK
- Wo bí afurasí ọmọ ọdún 16 àti 17 ṣe pa ọmọ ọdún 11 láti fi ṣe ètùtù ọlà
- Sotayo Gaga bẹ́ "speaker" ọdún tó ti ṣegbéyàwó àti ohuin tó fi pamọ́
To ba ri bẹẹ, ki wa l'awọn ipenija to wa nikalẹ fun ọga agba ọlọpaa naa?
Eekan majẹobajẹ kan lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria atawọn agbegbe aṣalẹ ilẹ Afrika, Mallam Kaniru Adamu yannana awọn ipenija marun un ti oga ọlọpaa tuntun, Usman Alkali Baba yoo koju.
1. Mimu atunṣe ba ajọṣepọ laarin olopaa ati araalu
Ọpọ aigbọraẹniye ati aini igbẹkẹle ninu ọlọpaa lo wa laarin awọn araalu eyi to nii ṣe pẹlu awọn iṣẹlẹ atẹyinwa pẹlu bi awọn ọlọpaa kan ti sẹ fi iya jẹ alaiṣẹ tabi fi ẹtọ araalu dun wọn at'awọn iwa ritẹ ẹtọ araalu mọlẹ.
Ọga ọlọpaa tuntun yii gbọdọ gbe igbesẹ to loorin lori mimu.atunṣe ba eyi.
O gbọdọ gbe igbesẹ atunto to yanranti laarin ileesẹ ọlọpaa ki araalu lee mọ pe omi tuntun ti ru ẹja tu tun ti wọ inu rẹ.
Bi a ko ba ni gbagbe iwode EndSARS to waye lọdun to kọja ninu eyi tawọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaajulọ awọn ọdọ ti tu sita lati fi ẹhonu wọn han lori iwa familete n tutọ tawọn ọlpọpaa kan n hu.
2. Bakan naa lo tun gbọdọ mojuto igbayegbadun awọn ọlọpaa abẹ rẹ paapaa lori owo oṣu wọn, ayika ti wọn ti n ṣiṣẹ, awọn owo ajẹmọnu gbogbo to tọ si wọn nitori nnkan o ṣe ẹnure fawọn ọlọpaa.
Ọpọ si n woo pe oṣeese ko jẹ idi ti pupọ ninu wọn fin hu iwa kotọ kaakiri.
Bi a ba fẹ ki ọlọpaa o duro daadaa, igbeaye wọn naa gbọdọ duro daadaa.
3. Ipese awọn ohun ija to ku oju iwọn.
O gbọdọ ṣe amulo ẹdawo idagbasoke ileeṣẹ ọlọpaa, Government'sTrust fund lati fi pese awọn ohun ija to yẹ.fawọn ọlọpaa lati fi ṣe iṣẹ wọn bi o ti tọ ati bo ti yẹ.
4. Dida iyi ọlọpaa pada.
Yoo ni lati ji giri ṣiṣẹ si dida ogo ati ọla iṣẹ ọlọpaa laorilẹede Naijiria pada.
Eyi yoo lee mu ki wọn le ṣe iṣẹ wọn ni ibamu pẹlu ilakalẹ iwe ofin orilẹede Naijiria ki wọn si lee pese abo to yẹ labẹle.
Lọwọ ti a wa bayii, eniyan fẹrẹ lee sọ pe awọn ologun lo n ṣe.iṣẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria bayii.
Nitoeinaa, ọga agba tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria gbọdọ da ogo ati ọla pada si iṣẹ ọlọpaa lẹyẹ o ṣọka.
Eyi ni yoo fun ijọba ni ifọkanbalẹ lati da wọn da iṣẹ abo abẹle laipe awọn ṣọja sii.
5. Gbigba ọpọlọpọ eniyan si iṣẹ ọlọpaa.
Ọga ọlọpaa tuntun, Usman Alkali Baba gbọdọ rii daju pe iye ọlọpaa to to lati mojuto abo Naijiria ni wọn gba sí iṣẹ.
Nitori ọpọlọpọ ileeṣẹ alaabo lo n ṣe awọn iṣẹ to fara pẹ iṣẹ ọlọpaa bii ajọ ẹṣọ oju popo ati ajọ abo ara ẹni labo ilu (civil defence) pẹlu.
Nitorinaa, ipenija kan to tun wa fun un ni lati wa ọna ati mu ki ajọṣepọ to dan mọran waye laarin awọn ẹka ileeṣẹ alaabo wọnyi.
Lakotan, Mallam Kabiru Adamu ṣalaye pe bi awọn ileeṣẹ alabo wọnyi ba lee pa dukuu aarin wọn ti si ẹgbẹ kan naa, ki wọn si fọwọsowọpọ, ohun ija nla ni iṣọkan wọn yoo jẹ lati koju awọn ipenija abo lorilẹede Naijiria.