You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Usman Alkali Baba: Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá tuntun àtàwọn aṣáájú rẹ̀ látọdún 1999
Aarẹ Muhammadu Buhari yan Usman Alkali gẹgẹ bi ọga agba tutun fun awọn ọlọpaa.
Ṣaaju rẹ, Mohammed Adamu lo jẹ ọga agba awọn ọlọpaa to si ti wa lori alefa lati dun 2019 ti aarẹ ti yan an.
Ọpọlọpọ lo ti dari ileeṣẹ ọlọpaa lati ọdun 1999 si isinsiyii.
wo ohun ti ẹ ni lati mọ nipa wọn.
Musiliu Smith 1999-2002
A bi Smith ni inu oṣu kẹrin ọdun 1946, o lọ si ile ẹkọ Ansarudeen Kọlẹji ni agbègbè Isolo ni ipinlẹ Eko ati fasiti Unilag nibi to tí kawe gboye ninu sociology lọdun 1970.
O darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa lọdun 1972 n'ilu Enugu gẹgẹ bí ASP. O tun ṣe iṣẹ olukọ ni ile iwe àwọn ọlọpaa to wa ni Ikeja ati ti Mubi ni ìpínlẹ̀ Adamawa.
O ṣiṣẹ ni Ikoyi nípìnlẹ̀ Eko, Ilorin nípìnlẹ̀ Kwara kí ó tó lọ sí ìpínlẹ̀ Rivers, Ọdún 1988 lọ di Kọmísọ́nà ọlọ́pàá.
Buhari yóò tẹ̀síwájú láti máa gba ìtọ́jú nílẹ̀ òkèèrè, ẹ kàn ń pariwo lásán ni - Amúgbálẹ́egbẹ́ Ààrẹ
Musiliu Smith di igbakeji oga agba ọlọ́pàá tó n Mójú tó ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano.
Ó lọ kàwé gboyè ẹlẹ́kejì ni Fáṣítì Ibadan lọ́dún 1997.
Smith di òga àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà nínú oṣù karùn-ún ọdún 1999 lábẹ́ ìdarí ààrẹ Olusegun Obasanjo.
Smith kọ̀ láti mójútó ẹ̀sùn tí wọn fi kan gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ìgbà náà Asiwaju Bola Ahmed Tinu pé ó yí ìwé, Smith ni ilé ẹjọ́ kò lè tipátipá mú ọlọ́pàá lati ṣe ìwádìí ẹ̀sùn náà.
Ọjọ́ kíni oṣù kejì, ọdún 2002 ni ẹgbẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà lọ fún idà ṣe sílè, ààrẹ Olusegun Obasanjo sì ni kí o lọ kọ ìwé ìfẹ̀yìtì nínú oṣù kẹta ọdún 2002 tí Mustapha Adebayo Balogun sìbẹ̀ síbẹ̀.
Mustapha Balogun 2002-2006
Fáṣítì ìlú Èkó ni Mustapha Adebayo Balogun pẹ̀lú lọ tó sì kàwé gboyè ìmọ̀ nínú ètò òṣèlú lọ́dún 1972.
Ó wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá ni ọdún 1973,lásìkò tó wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá yìí lo wọ Fáṣítì Ibadan láti kàwé sì nínú ìmọ̀ òfin.
Lẹ́yìn tó tí ṣiṣẹ́ ni onírúurú ẹ̀ka ló lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbà kan ri gẹ́gẹ́ bí ìgbàkejì Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Edo tẹ́lẹ̀rí, Kọmísọ́nà ọlọ́pàá àkọ́kọ́ ni Delta, Rivers àti Abia.
Balogun di igbakeji oga àgbà ọlọ́pàá AIG ẹkùn tí Kano, orí ipò yìí lo wà tó fi di ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà ni ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹta ọdún 2002.
Òpin ọdún 2004 onírúurú ìwé ìròyìn ló kọ́ pé Tafa Balogun kó owó ìlú jẹ tó sì gba onírúurú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ awọn olóṣèlú àti àwọn ọ̀daràn. Wọ́n fún ní ìwé ìfẹ̀yìntì ninu oṣù kíni ọdún 2005 tí àjọ EFCC sì bẹ̀rẹ̀ iwadii lórí rẹ̀
- Ariwo sọọ! Àwọn agbébọn jí ọkọ, ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn gbé l'Ondo
- Àwọn jàndùkú agbébọn pa èèyàn mẹ́jọ, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ní Kaduna
- Tinubu ló lè ṣeé lọ́dún 2023, Pa Fasoranti àti Oba Osemawe Ondo sọ̀rọ̀ sókè
- Ẹ padà wá o ẹ̀yin ẹlẹ́wọ̀n, ẹni tó bá wá wọ́ọ́rọ́wọ́ yóò rí ìdáríjì, ẹni tí kò bá wá ... - Aregbesola
Sunday Ehindero 2006-2007
Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ondo ni Sunday Ehindero láti Oyin-Àkókò, sugbọn ìlú Jos ni a bí sí, ó lọ sí iléèwé Gboluji ni Ondo kí ó tó lò Fáṣítì Ibadan níbi tó ti kàwé gboyè ìmọ̀ òfin.
Iṣẹ́ olùkọ́ ló kọ́kọ́ ṣe nílé ìwé kan n'ilu Abeokuta ni ọdún 70s, ọmọ mẹ́rìnlá ni àwọn òbí re bí ti o si ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé. Isẹ agbejọro náà ló padà si
Nínú oṣù kẹrin, ọdún 2004 ó di ìgbàkejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, àsìkò yìí ló mójútó ìwádìí ibi tí wọn tí rí òkú ènìyàn àti orí ni Okija Shrine nípìnlẹ̀ Anambra
Nínú oṣù oṣù Kejìlá ọdún 2006,Sunday Ehindero ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tí ra ọkọ̀ ìjà ọgbọ̀n lati kógun ti ìwà ọ̀daràn ni Èkó, Bayelsa, Delta àti Rivers
Ó ní ọga àgbà ọlọ́pàá tó lọ, Mustafa Balogun padà jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ àti pé ó gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olopaa tó ní àkọsílẹ̀ ọ̀daràn
Ni ọjọ́ Kẹ̀sán, oṣù kẹrin, òdun 2007, òsé mẹ́ta sí ìgbà rí wọ̀n yóò búra wọlé fún ààrẹ Musa Yar'Adua ni ó yàn Nuhu Ribadu tó jẹ́ ọ̀gá EFCC gẹ́gẹ́ bí igbakeji ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
Mike Okiro 2007-2009
A bí Okiro ni ọdún 1949 ni Oguta Ìpínlẹ̀ Imo, ṣùgbọ́n ìjọba ìbílẹ̀ Ogba/Egbema/Ndoni ni ilu
Ègbé má ni, ó jẹ́ Agunechemba I tibEgbema, àti ọmọ ìhà Igbo àkọ́kọ́ tó dé ipò ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
Ó kàwé gboyè èdè gẹ̀ẹ́sì ni Fáṣítì Ibadan ati ikawe gboyè kejì ni Fáṣítì Eko ati Fáṣítì Jos.
Ó wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá ni òdun 1977 to sì di onírúurú ipò mú bí alakoso, DPO àti ìgbà kejì Kọmísọ́nà olopaa ní Eko ati Benue.
Ó ní onírúurú àṣeyọrí lásìkò ré òun pẹ̀lú ló paa láṣẹ kí gbogbo ènìyàn forúkọ silẹ fun gbogbo siimu kaadi.
Ogbonna Onovo 2009-2010
A bí Ogbonna Okechukwu Onovo ni odun nijoba ìbílẹ̀ Akanu nípìnlẹ̀ Enugu, ó lọ Fáṣítì Nsukka níbi tó ti gba òye nínú ètò òṣèlú láàrin ọdún 1972 sì 1976
Ó wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá lọdun 1977 gẹ́gẹ́ bí ASP, títí tó fi dé ipò Kọmísọ́nà ọlọ́pàá lọ́dun àti ìgbàkejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nínú oṣù karùn-ún ọdún 2001
Ó ti ṣiṣẹ́ ni Èkó, Edo, Adamawa Ogun láàrín ọdún 1998 sì 2000.
Ó di igbakeji ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nínú oṣù keta ọdún 2002, ọdún 2007 lo di Adele ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá kí wọn tó yàn Okiro sí ipò ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
Oṣù keje Ọdún 2009 lọ tún jẹ́ adelé ọ̀gá ọlọ́pàá to sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti mú ìwà ọ̀daràn wá sopin ni Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ó gbà ipò náà ni inú oṣù kejò nígbà tí ìgbìmọ̀ àjọ ọlọ́pàá jan lontẹ̀.
Àsìkò ré ni ọ̀gá àwọn Boko Haram kú sí ahamọ́ ọlọ́pàá tí àwọn Boko Haram sì bẹ̀rẹ̀ si ni kojú ìjà sí gbogbo àgọ́ ọlọ́pàá ni àwọn ìpínlẹ̀ àríwá márùn-ún ni Nàìjíríà
Hafiz Ringim 2010-2012
Ààrẹ lo fọwọ́ òsì júwe ilé fún oga àgbà ọlọ́pàá Hafiz Ringim nígbà tí ìgbésùmọ̀mí ń peléke sì ni Nàìjíríà.
Èyí wáyé leyin ti Boko Haram pá ènìyàn 185 nípìnlẹ̀ Kano, òun àti àwọn igbakeji ré mefeefa lo bá a lọ
Mohammed Abubakar Dikko 2012-2014
Mohammed Dikko Abubakar,
lọ di oga agba àjọ ọlọ́pàá leyin Suleman Abba lọ́dun 2012
Ọmọ bíbí Gusau tó wà ní ìpínlẹ̀ Sokoto tẹ́lẹ̀ sugbọn tó ti di oluilu Zamfara báyìí.
Ó ṣiṣẹ́ bí bí komisona ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Kwara kí ó tó di AIG
Ọ̀pọ̀ lọ máa ń pe ni MD Abubakar
Suleiman Abba 2014-2015
A bí ní ọdún 1959, ó sì di adelé ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria ni ọdún 2014 nígbà tí ààrẹ Goodluck Jonathan yàn, sugbọ́n ó bọ̀ sórí ipò náà ni inú oṣù kọkanlá ọdún 2014
Ó wọ isẹ ọlọ́pàá ni ọdún 1984, ó jẹ Kọmísọ́nà ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Eko àti Rivers
Kí o to di oga àgbà ọlọ́pàá lọ tí je AIG eku Abuja, wọn gbé ìwé lọ rokun nílé fún ní inú osù kẹrin ọdún 2015 ni díẹ̀ kí ìdìbò ọdún 2015 wáyé.
Solomon Ehigiator Arase 2015-2016
A bí ní ọdún oṣù kẹfà 1956, ní ìjọba ìbílẹ̀ Owan west ìpínlẹ̀ Edo
Ó lọ sí Fáṣítì Ahmadu Bello tó sì kàwé gboyè imọ nípa eto òsèlú, ààrẹ Goodluck Jonathan lo yàn sípò lọ́dun 2015 lẹ́yìn tí wọn yọ Abba níṣẹ́, kí Arase to gba iṣẹ́ ọ̀hún òun ni olórí ìwádìí idakọnkọ́ tó ga julọ ninu ilé iṣẹ̀ ọlọ́pàá.
Arase feyinti lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá nínú osu kẹfà ọdún 2016
Ibrahim Idris Kpotun 2016-2019
Ìlú Kutigi ni a ti bí Idris níjọba ìbílẹ̀ Lavun nípìnlẹ̀ Niger, a bí ní ọdún 1959.
Ó wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọdún 1984 leyin tó parí ni Fáṣítì Ahmadu Bello ni Zaria. Bákan náà ló gboyè imọ nínú ètò ọ̀gbìn àti ìmọ̀ òfin ni Fáṣítì Maisuguri.
Kí o tó jẹ́ oga àgbà ọlọ́pàá lọ tí jẹ́ AIG tó ń rí sí ìgbòkègbodò isẹ ọlọ́pàá l'Abuja. Bákan náà ló ti dárí àwọn olọ́páà kò gboregbe ni Nasarawa gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà ọlọ́pàá.
Mohammed Abubakar Adamu 2019-2021
A bí ní ọdún 1961, lẹ́yìn tí Ibrahim Kpotum kúrò nibẹ, Ààrẹ Muhammadu Buhari ló yàn gẹ́gẹ́ oga àgbà ọlọ́pàá Ogun nínú osu kini odùn 2019
Ọmọ Lafia ni ìpínlẹ̀ Nasarawa ni Adamu. Ṣáájú ni ààrẹ Buhari tí fi kún àsìkò rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kí ó tó fà á yọ bí jìgá lànà òde yìí, tó fi Usman Baba rọ́pò
Usman Alkali Baba 2021
Abi Usman Alkali Baba ní oṣù kẹta ọdún 1963 tí ààrẹ Muhammadu Buhari yàn ni ọjọ́ kẹfa oṣù kẹrin ọdún 2021 gẹ́gẹ́ bí adelé ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà.
Ọmọ bíbí Gaidam nípìnlẹ̀ Yobe ni, ilé ẹ̀kọ́ olukoni onípò kejì ló kọ́kọ́ kà ni Potiskum Yobe.
Kí o tó té síwájú lọ Fáṣítì Bayero ni Kano tó sì jáde ní ọdún 1985 bákan náà ló lọ fùn ikẹ̀kọ́ gboyèkejì ni Maiduguri lọ́dún 1997.
O wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá lọ́dun 1988 kí ó tó di Kọmísọ́nà ọlọ́pàá lọ́dún 2013. Ní ọdún 2014 wọn gbé lọ sí ìpínlẹ̀ Delta gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà olopaa.
Ó ti ṣiṣẹ bí ìgbàkejì ọ̀gá ọlọ́pàá eka tí CID ni Abuja rí, ó tún jẹ́ igbakeji Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ìlú Abuja tẹ́lẹ̀.
Bákan náà ló ti ṣiṣẹ̀ ni Kaduna, Ebonyi, Yola, Jos àti Gombe rí. Òun AIG zone 5 to ń mójú tó Edo, Bayels, àti Delta.