You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dangote, Adenuga àti Rabiu pọ̀ síi pẹ̀lú $5.7bn - Forbes
Ọrọ̀ awọn bilonia to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria tun ti pọ sii pẹlu biliọnu mẹfa owo dọla din diẹ laarin ọdun kan sẹyin.
Iwe iroyin Forbes lo gbe iroyin naa jade pe ninu atẹjade awọn bilonia fun ọdun 2021.
Atẹjade ti Forbes gbe jade lọjọ Iṣẹgun fihan pe Aliko Dangote to jẹ oludari ati ọga agba ileeṣẹ Dangote naa si lo lowo julọ nilẹ Afirika.
- Wo àwọn Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá tó ti jẹ́ látọdún 1999
- Tinubu ló lè ṣeé lọ́dún 2023, Pa Fasoranti àti Oba Osemawe Ondo sọ̀rọ̀ sókè
- Àwọn jàndùkú agbébọn pa èèyàn mẹ́jọ, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ní Kaduna
- Dáa padà! Àwọn alátìlẹ́yìn Buhari fàdúrà jagun lòdì sáwọn tó ń fẹ̀hẹ́nùhàn lé e kúrò ní London
- Asọtẹ́lẹ̀ ikú Yinka Odumakin ti jáde sí wa tẹ́lẹ̀, ẹbí gbàdúrà, àmọ́...- Jacob Odumakin
- Àwọn agbébọn tún dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá ní Imo, wọ́n tú àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀
- Ìdí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó ìdákọ́nkọ́ - Sotayo Gaga
Mẹrinla lara awọn bilonia agbaye ọhun lo wa lati ilẹ Afirika.
Ni bayii, dukia ati ọrọ Dangote ti di $11.5bn lati $8.3bn to wa lọdun 2020.
Dangote bilonia to wa ni ipo kọkanlelọgọsan lori tabili awọn eeyan to lọrọ julọ ni gbogbo agbaye.
Ọrọ ati dukia alaga ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ Globacom ati ile epo rọbi Conoil Plc, Mike Adenuga naa le si lati $5.6bn lọdun 2020 si $6.1bn bayii.
Adenuga lẹni to lowo julọ ṣikeji lorilẹede Naijiria, amọ ipo karun un lo wa nilẹ Afirika nigba to wa ni ipo oji le ni irinwo 440 lagbaaye.
Oludasilẹ ileeṣẹ BUA Group, Abdulsamad Rabiu naa gberu sii pẹlu ọrọ rẹ.
Ohun ini rẹ ti di $4.9bn bayii lati $2.9bn to wa lọdun 2020.
Marun un ninu awọn bilonia lati ilẹ Afirika ti iwe iroyin Forbes gbe jade lo wa lati orilẹede South Africa.
Marun un miran wa lati orilẹede Egypt, nigba ti ẹyọkan jẹ ọmọ bibi orilẹede Algeria.
Ẹwẹ, oludasilẹ ileeṣẹ Amazon, Jeff Bezos si ni ẹni to lowo julọ lagbaaye pẹlu $177bn.
Ọgbẹni Bezos ti wa ni ipo kinni bayii fun ọdun mẹrin gbako.