Ooduwa Republic: Gani àwọn alálẹ̀ yóò gbe wá, tá bá fi òtítọ̀ jà fún òmìnira

Yoruba ni ọwọ ọmọde ko to pẹpẹ, tawọn agba naa ko si wọ keregbe nitori ọmọde gbọn, agba gbọn la fi da ilẹ ifẹ.

Eyi lo mu ki Aarẹ Ọna Kakanfo nilẹ Yoruba, Iba Gani Adams se n mu da awọn ọmọ Yoruba loju nipa awọn ilana ti wn yoo lo lati gba ominira fun ilẹ Yoruba.

Adams ni awọ̀n ọ̀mọ Yoruba naa ni Ọlọrun yoo lo lati gba ominira ọhun , bawọn to wa ninu ile se ni ipa ti wọn yoo ko, naa lawọn ọmọ Yoruba to wa loke okun yoo ko ipa ti wọn naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gani Adams, lasiko to n kopa lori eto ileesẹ wa BBC Yoruba, tun salaye pe isọri meji ni awọn eeyan pin si, ero wa, bẹẹ naa si ni awọn eeyan wa.

O ni awọn alagbara ọmọ Yoruba wa lawọn orilẹede kaakiri awọn ilu oyinbo to pọ, ti wọn mọ eeyan nla nla ati ninu ajọ isọkan agbaye, United Nations.

"A ni awọn ọmọwe kaakiri ti ọwọja wọn na kaakiri agbaye, koda, awọn miran wa laarin wọn ti wn ko ni kan ilẹkun, ki wọn to wọle tọ Biden, tii se aarẹ orilẹede Amẹrika."

O ni gbogbo wọn ni wọn setan lati ja fun ominira ilẹ Yoruba lai lo ọta ibọn, o fikun pe ati ero, ati eeyan ni yoo wulo fun ominira Yoruba, nigba ti akoko ba to.

O wa laa kalẹ pe ọrọ sise girigiri lori ayelujara kọ ni ọrọ gbigba ominira ta n wi yii, kii si se ọrọ ariwo tabi ọrọ Gani Adams tabi ọrọ Sunday Igboho.

Iba rọ gbogbo ìràn Yorùbá láti ja ìjàgbara láti gba òmìnira, kí wọ́n yé fi òṣèlú ṣe òhunkóhun, pàápàá jùlọ àwọn tó wà ní òkè òkun.

Ẹ jẹ ka se ara wa ni ọkan soso

Aarẹ Gani Adams wa rọ awọn ọba alaye nilẹ Yoruba atawọn eeyan to n tako iyapa kuro ni Naijiria lati ronu wo lẹẹmeji, nitori o le lẹyin, bi oku iya jọjọ.

"Ẹ jẹ ka se otitọ, ka se ara wa ni ọkan soso, ka si fi imọ se ọkan, kawọn alalẹ le gbe wa, ka nifẹ ara wa, ka si mase gba abọde fun iran Yoruba.

Ẹ ma se abosi, ka si ranti iran to n bọ, ẹgbẹ ẹya Yoruba ti pọ ju, tawọn kan si n da nnkan ru, ko si yẹ ka jẹ ki owo tabi oselu da aarin wa ru nitori owo yoo tan, oselu yoo lọ amọ alajọbi ni yoo ku."

Lẹyin ta ba gba ilẹ Oduduwa tan, la to ja fun Kwara ati Kogi

Nigba to n dahun ibeere pe nibo ni ipinlẹ Kogi ati Kwara yoo wa, ti ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ba yapa, Gani Adams ni bi igi ba wo lu igi, ti oke rẹ la kọkọ re kuro.

O ni ẹkun iwọ oorun yoo kọkọ gba ara rẹ silẹ lọwọ iya na, ko to wa mọ ọna ti yoo gba ko awọn eeyan rẹ to n bẹ ni Kwara ati Kogi naa kuro.

"A ni ka kọkọ ko ara wa kuro ni ọfin ta jin si yii na, ka to wa maa ko awọn eeyan wa to wa kaakiri mọra, a kọkọ le ẹyọrọ jinna na, ka to pada wa fi abọ fun adiẹ."

A ko ni ta ẹjẹ silẹ ka to gba orilẹede Oduduwa

Ààrẹ ọ̀nà Kankanfo gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gbaniyu Ige Adams tí kéde pé ómó Yorùbá kò ni tá ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ tábi já ogun kankan títí ọwọ́ wọn yóò fi tèkudà.

Iba Gani Adams sọ èyí lásìkò tó ń ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú BBC News Yorùbá lórí ọ̀rọ̀ Oduduwa Republic tí àwọn ọmọ káàrọ̀-ò-jíire ń pè fún.

Ó ní kí ìjọba má halẹ̀ ogun mọ́ ẹnikẹni, ńiwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ gbogbo ẹ̀yà Yorùbá kò ti wọ inú ilẹ̀ ẹ̀yà míràn, kò sí ǹkan tó le fa ìjà láàrín Yòrùbá àti ẹ̀yà míràn.

Ó ní gbogbo Fulani nilẹ̀ Yorùbá lé dúró sọdọ wa níwọ̀n ìgbà tí wọ́n kò bá gba àbọ̀dè fún ẹ̀yà Yorùbá, àwọn Yorùbá tó bá sì wà ní ilẹ̀ Hausa le dúró síbẹ̀ láì padà wálé.

"Ilẹ Fulani wa ni Sokoto lọhun, Kaduna ni ẹnu aala Middle Belt, ilẹ Yoruba ko wọ inu ilẹ ẹya miran rara, nitori naa, ko le si ija rara."

Gani Adams wa kede fun awọn eeyan to n bẹru pe ogun le waye nitori iyapa pe, ki wọn mase fi ogun halẹ mọ wa rara.

"Ko le si ogun kankan, bẹẹ ni ko si ọrọ pe a gba fisa ka to wọ ilu Kano, irọ ni, se a n gba fisa wọ Ghana ni? Ẹkun iwọ oorun Afirika ni gbogbo wa wa.

"Ọdun mẹfa la fi ja ogun June 12 lai ta ọta ibọn kankan, titi ti akoso ijọba apapọ fi bọ si ọwọ ọmọ Yoruba, nitori naa, ọrọ ogun jija ko le waye.

Amọ to ba jẹ ogun naa ni yoo yanju rẹ, ẹru ko ba mi nitori mo setan lati tẹle iran Yoruba nibi kibi to ba n lọ, n ko ni gbabọde fun ilẹ Yoruba."

Alagbe ni olorin, ọrọ Wasiu Ayinde ko to pọn

Lórí orin ti K1 kọ ránṣẹ́ pé kí Iba Adams jẹ́ kí ọmọ Yorùbá de ipò ààrẹ Nàìjíríà náà, Gani Adams ni olórin ni Wasiu Ayinde ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí K1, àwọn alágbára sì ló má n rán irú wọ́n níṣẹ́.

"Ẹni awa naa maa n ba pade loju agbo, ta maa n nawo fun ni Wasiu Ayinde, awọn olorin si ni Yoruba maa n pe ni alagbe."

Ààrẹ ọ̀nà Kakanfò ní ọ̀pọ̀ ìgbà alágbé ni àwọn olórín, fèrè tí àwọn alágbára bá sì fọn sí wọ́n lẹ́nu, ni wọ́n máa n fọn síta.

"Emí kìí ṣe alágbára, òjíṣẹ́ ni mi, agbára má n gun àwọn alágbára, wọ́n a sì má subú, sùgbọ́n òjíṣẹ́ máá n tẹti si ohùn ọlọ́rún ni láti ṣiṣẹ́ ìlú.

Ohun Ọlọrun ati tawọn to nile aye ni emi yoo tẹle, kii se ohun ti awọn alagbara ba ran awọn alagbe si mi."