Yinka Odumakin àti ìyàwò rẹ̀ lèè bá ìjọba jà tí wọ́n bá fìyà jẹ mẹ̀kúnù - Vera Okei

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Tẹẹ ba fẹ ri ija ẹgbọn Yinka ni kẹẹ lọ tẹ ẹtọ mẹkunu mọlẹ".

Arabinrin Vera to ni o ti to bii ogun ọdun ti oun ti n ba oloogbe Yinka Odumakin gbe sọ fun BBC Yoruba pe ẹni to ni ibẹru Ọlọrun ti kii sii ṣe oni wahala amọ "ẹni to ba fẹ ri ija wọn, ko yan awọn mẹkunu jẹ, ibaa jẹ ijọba ni tabi ọlọdani".

Vere jẹ aburo iyawo oloogbe Odumakin, Joe Okei- Odumakin. O ṣalaye bi agbo ilw wọn ṣe kun fọfọ fun ero ti wọn n sọ pe "eeyan to ti dara ju bayii ko ko ri bẹẹ".

"Ko si ẹni to wọ ile wọn ti ko ni ba ẹrin jade tori atawọn ati iyawo wọn lo jọ jẹ ajafẹtọ ọmọmiyan".

Bi Joe ṣe pade Yinka Odumakin ninu ẹwọn ti wọn ti bẹrẹ si ni fẹ ara wọn

Vera ṣalaye pe gbogbo eeyan lo mọ ẹgbọn oun ati Yinka Odumakin lọtọọtọ gẹgẹ bi ajafẹtọ ki wọn to fẹ ara wọn ni lọkọlaya.

"Lasiko ijọba Abacha ti wọn mu awọn mejeeji lọtọọtọ sinu ẹwọn, nigba ti wọn n ko wọn lọ ile ẹjọ ni wọn ri ara wọn pe ha ha, arabinrin ti mo maa n gbọ to n ja fẹtọ ree, Joe naa ni haa arakunrin ti a maa n gbọ nipa rẹ ree, bi ọrọ ifẹ wọn ṣe bẹrẹ niyẹn".

O ni nigba naa lọhun, iṣẹlẹ naa ṣoju oloogbe oloye Gani Fawehinmi ti wọn jọ bẹrẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ nigba ti wọn ṣi n fi ẹsẹ rin titi wọn fi di eeyan giga.

"Torinaa, ifẹ yẹn o ti pọ ju, o ti pọ ju amọ ko si nkan ti a le ṣe tori wọn bara jẹ gan ni ileewosan nigba to kọkọ ṣẹlẹ pe Yinka dide o, dideo , a o jọ sọ ọ bayii".

Vera ni o pada gba kamu tori o mọ pe ọkọ oun ti ṣe daadaa ni aye, o ti ko ipa tirẹ.

Titi di asiko ti a ba arabinrin naa sọrọ, o ni aya oloogbe ko tii le jẹ ohunkohun lati igba ti ọkọ rẹ ti dakẹ, "agbara kaka gan ni wọn fi n jẹun nigba ti wọn fi wa nileewosan".

Ki ni Yinka Odumaki ṣe lasiko ija fun Yoruba Nation.

Vera sọ fun BBC pe oun o le sọ pupọ nipa eyi amọ iwọnba ti oju oun ri ni pe lati igba ti oloogbe Yinka Odumakin ti wa lori akete aisan naa lo ti n gbiyanju to n dide lati lọ yanju aawọ laarin awọn ti ọrọ Oduduwa Republic ṣẹlẹ laarin wọnm.

"Ibi ti ootọ ba wa, wọn maa sọ". Arabinrin naa ni o ba Sunday Igboho sọrọ, o ba Ooni sọrọ, o ba Baba Ayo Adebanjo to jẹ baba fun un sọrọ atawọn tọrọ kan ko tio wa di pe ọlọjọ de.

Kí ló pa Yinka Odumakin gangan?

Aburo iyawo oloogbe jẹ ko di mimọ pe ẹlomii ti ko mọ nkankan nigba ti nkan ba wa ṣẹlẹ̀, wọn a maa ṣe bii pe wle wọde niwọn pẹlu ẹni to ku.

O ni ko sohun to jọ pe oloogbe ni iṣoro kidinrin kankan lati ọdun ti oun ti mọ ọ, o ni ara rẹ pe daadaa.

Aworan ti awọn kan n pin ka pe ẹsẹ rẹ wu, o ni asiko kan wa to lọ fun ipade to sun to ṣubu latori bẹẹ́di ti ẹsẹ rẹ si kọ ibikan to wa padanu ẹjẹ. Egbo kekere to wa nibẹ lo jẹ ki ẹsẹ rẹ wu o si ni ẹsẹ naa ti fa bayii.

Vera ni itọ ṣuga nikan loun mọ to si ti n tọju rẹ amọ ko ni aisan kidinrin kankan. Sibẹ o ni o yẹ ki awọn eeyan maa bọwọ fun ẹni to ba ku.

Ni ti coronavirus, aburo iyawo oloogbe ni ko tilẹ jọ gbogbo nkan to wa nilẹ rara.

"A ti kọ atẹjade ninu eyi to wa pe ẹẹmeji ni ẹgbọn Yinka ṣe ayẹwo to si fihan pe ko ni aarun Covid-19. Kii ṣe covid-19 lo pa wọn, itan taa ti gbagbe gan ni ọrọ ayẹwo covid-19 ti wọn ṣe".

Ẹ̀yà ara bí ẹ̀mí mi ló kú - Joe Okei, ìyàwó olóògbé Yinka Odumakin Bi Yinka àti Joe

Iyawo oloogbe adari ẹgbẹ Afenifere, Yinka Odumakin to jade laye to dagbere fayue lowurọ ọjọ Ẹti, Joe Okei-Odumakin ti ṣapejuwe iku ọkọ rẹ gẹgẹ bi eyi to jẹ ibanujẹ fun un to si ni pataki ninu ẹya ara ohun lo ti kuro yii.

Bakan naa awọn eekan lorilẹede Naijiria ko ko iyan oloogbe yii kere rara gẹg bi ọrọ ibanikẹdun ṣe n jade latẹnu Aarẹ orilẹede Naijiria titi kan awọn eeyan nla nla mii bi Aṣiwaju Bola Tinubu, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, Ọjọgbọn Banji Akintoye, Minisita ọrọ Abẹnu, Rauf Aregbesola atawọn mii ti ko le gbagbe ajọṣepọ ti wọn ni pẹlu oloogbe nigba aye rẹ.

Ẹwẹ, iyawo oloogbe, Ọmọwe Okei-Odumakin sọ ninu ọrọ rẹ pe ni ẹka fun itọju to ti kọja keremi ni ileewosan fasiti ipinlẹ eko (LASUTH) ti wn ti n tọju ọkọ rẹ fun aisan Covid-19 to ni lo ti dagbere faye.

Bo tilẹ jẹ pe aya oloogbe ni ọkọ oun ti jajabọ lọwọ arun Coronavirus naa.

O ni wọn yoo kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ fun gbogbo eniyan bo ba ti to akoko.

Awọn ọmọ Naijiria to n daro oloogbe Odumakin

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ba idile oloogbe Yinka Odumakin kẹdun ipapoda rẹ. Aarẹ ṣapejuwe Odumakin gẹgẹ bi ẹni to mọ iṣẹ rẹ ggẹ bi iṣẹ ati ẹni ti eeyan lee nigbagb ninu rẹ to si ko ipa gidi lawujọ.

Aarẹ ni Odumakin lo jẹ agbẹnusọ fun oun gẹgẹ bi Ọgagun Buhari lọdun 2011 nigba to du ipo aarẹ labẹ akoso ẹgbẹ oṣelu Congress for Progressive Change nigba naa lọhun.

Bakan naa, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu ṣapejuwe oloogbe Odumakin gẹgẹ bi "Akin" ọkunrin tó máa ń sọ̀rọ̀ sókè láti gbárùkù ti ohun tó gbàgbọ́. Ó sì jẹ̀ olólùfẹ́ orílẹ̀èdè.

Loju opo Twitter rẹ, o ni o ti ku amọ ko ku lọkan awọn araalu nitori iṣẹ takuntakun to ṣe niga aye rẹ.

Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams ni adanu nla ni iku rẹ jẹ si "Orilẹede Yoruba". O ni alabaṣiṣẹpọ pataki to ṣee fkan tan ni Odumakin jẹ.

Ninu atẹjade ọdọ Naijiria kan to mu u bii olutọsọna rẹ, Yera Moses Olafare to jẹ oluranlọwọ fun Ooni Adeyeye ni "... ẹyin lẹ ra foonu "blackberry ti mo kọkọ lo fun mi..."

"Ẹ koro oju si igbesẹ kan ti mo gbe lọdun 2012 lai ṣe agabagebe, lọdun 2016, ẹ sọrọ daadaa nipa mi fun Kabiyesi".