You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Regent, youngest king: Ọbalayé tó kéré jùlọ nílẹ̀ Yorùbá, Oloyede Akinghare gbadé nípínlẹ̀ Ondo
Lẹyin ọdun mẹta ti baba rẹ, Adeyẹmọ Adeyẹọba waja, Ọmọọba Oloyede gun ori itẹ gẹgẹ bii Kabiyesi Arujale Ojima ti ilu Okelusẹ ni ijọba ibilẹ Ọsẹ, ni ipinlẹ Ondo.
Laarin ọdun 2012 si 2019 ni Ọba Adeyẹmọ Adeyẹọba fi wa lori itẹ ki wọn to gbe ade le ọmọ rẹ ọkunrin, Ọba Oloyede Akinghare keji, to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun lori.
Gomina Rotimi Akeredolu gbe Ọpa aṣẹ oye fun Ọba Oloyede.
Ọba Oloyede Akinghare II ni yoo jẹ Oba karundinlaadọta ti yoo jẹ ni ilu Okelusẹ lẹyin ti awọn to tẹ ilu naa do gbera kuro ni ilu Ifẹ pẹlawọn akẹgbẹ rẹ to tẹ ilu Ọwọ ati Benin do.
Oye idile ni oye ọba ni ilu Okelusẹ akọbi ọmọ ọkunrin ọba to ba wa lori itẹ si ni o maa n joye naa.
Oun si ni abigbẹyin baba rẹ nitori o ni awọn ẹgbọn mẹta to jẹ obinrinbi o tilẹ jẹ pe.
Ọjọ karundinlogun, oṣu karun, Ọdun 2003 ni wọn bi Kabiyesi Ọba Akinghare, iwe karun un girama lo si wa bayii nillewe kan nilu Arigidi Akoko.
Gẹgẹ bi ohun ti awọn onitan n sọ, Kabiyesi Akinghare ni ọba laye ti ọjọ ori rẹ kere julọ ni ilẹ Yoruba.