Iléẹjọ́ ti pàṣẹ pé kí wọ́n lọ yẹgi fún Mbatumukeke Sodienye tó pa òṣìṣẹ́ Jumia kan ní Port- Harcourt

Ile ẹjọ ni ki wọn yẹgi fun Sodienye Mbatumukeke to pa osisẹ Jumia ni Port-Harcourt.

Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Rivers ti dajọ ẹbi farakunrin kan Sodienye Mbatumukeke to pa awakọ alupupu ileesẹ itaja oju ayelujara Jumia kan.

Adajọ Chigozie Igwe ni o mọọmọ pa Chukwuma Eleje ati pe o si tun jẹbi idigunjale.

Sodienye Mbatumukeke ati Excel Naabee ni wọn jijọ n jẹjọ ẹsun alabala meji isekupani ati idigunjale.

Amọ lẹyin igbẹjọ, adajọ ni Excel Naabee ko jẹbi ẹsun naa amọ iku ni adajọ sọ pe Sodienye yoo fi gbara.

Idajọ adajọ tun sọ pe ki wọn yẹgi fun un titi ti yoo fi gbẹmi mi.

Bi a ko ba gbagbe, losu Kẹta ọdun 2017 ni iroyin gbode nigba ti wọn pa Chukwuma.

Ohun ta gbọ ni pe o gbe ọja tawọn kan ra loju opo Jumia lọ ba wọn sugbọn wọn ko ri oku rẹ ati alupupu to fi n sisẹ.

Nigba ti ọlọpaa yoo se iwadii, wọn ba oku rẹ ninu ''soakaway'' ti wọn ju si.