Sunday Igboho: OPC ní ọ̀gá ọlọ́pàá, Operation Burst àti Civil Defence wà pẹ̀lú àwọn

Akọwe ipolongo fun ẹgbẹ OPC new Era, Adesina Akinpelu ti salaye bi irinajo Sunday Igboho se lọ silu Igangan lọjọ Ẹti.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori irinajo Igboho naa, Akinpelu fidi rẹ mulẹ pe kii se Igboho nikan kọ lo da lọ silu Igangan lọjọ Ẹti.

Akọ̀we ipolongo OPC New Era naa ni gba gba gba ni ẹgbẹ naa wa lẹyin Sunday Igboho nitori ka rin, ka pọ, yiyẹ nii yẹ ni.

Akinpelu fikun pe "Awa ẹgbẹ OPC New Era, The Reformed OPC, Agbekoya, Ẹgbẹ ọdọ Oodua Liberation, Oodua Alliance ati ẹgbẹ ọdọ nilu Igangan la gbaruku ti Sunday Igboho lọ silu Igangan lọjọ Ẹti.

Bakan naa lo ni awọn duro ni agọ ọlọpaa ẹkun Eruwa lasiko ti awọn n lọ silu Igangan lọjọ Ẹti, ti ọga agba ọlọpaa lẹkun naa si kọwọrin pẹlu awọn lọ si agbegbe naa.

"Koda, a se alabapade awọn osisẹ aabo ara ẹni laabo ilu, Civil Defence ati awọn ologun, a sọkalẹ ninu ọkọ wa, ta si salaye fun wọn pe alaafia la n ba lọ.

A sọ fun wọn pe a n lọ sọ fun Seriki Fulani to wa nilu Igangan pe ko kilọ fawọn Fulani to n paayan pe ki wọn fi agbegbe naa silẹ.

Wọn gba wa laaye lati lọ silu naa, taa si bawọn eeyan ilu naa sọrọ, ta si fi wọn lọkan balẹ pe ko ni si ewu mọ lati akoko naa lọ."

Adesina Akinpelu fikun pe ọkada aadọta lo tẹle awọn latilu Eruwa, ọkada naa si di ẹgbẹrun kan nigba tawọn de Igbo Ora, nigba ti wọn yoo si fi wọ ayete, iye awọn ọkada naa ko lonka mọ.

O ni deede aago mẹta ọsan lawọn de Igangan lọjọ Ẹti, ti awọn si kuro ni aago mẹfa kọja ogun isẹju nirọlẹ, ti ko si si jagidijagan kankan.

O ni ọkọ Sunday Igboho lo lewaju awọn, tawọn si fi ọrọ werọ pẹlu awọn ọmọ ologun to wa loju popo.

Akinpelu ni "Gbogbo ikọ OPC to wa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lo n ti Igboho lẹyin, a si n se atilẹyin fawọn baba wa lẹkun yii.

Ki wọn si to le ri Igboho gbe, gbogbo ikọ ajijagbara nilẹ Yoruba ni wọn yoo kọkọ gbe na, bẹẹ si ni kii se gbogbo Fulani ni Igboho ni ki wọn ko aasa wọn, awọn to jẹ ọdaran laarin wọn ni."

Ki ni ero ẹgbẹ Yoruba lori asẹ ọga ọlọpaa lati mu Sunday Igboho si ahamọ:

Wayi o, awọn ẹgbẹ kan to jẹ tọmọ wọn ẹgbẹ kan to jẹ tọmọ Yoruba, Yoruba Council of Elders ati Oodua Peoples Congress, OPC ti tako asẹ ọga ọlọpaa lati mu Oloye Sunday Igboho.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọga agba ọlọpaa ti pasẹ fun Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Oyo lọjọ Ẹti lati lọ mu Igboho wa silu Abuja.

Asẹ naa lo waye nitori bi Igboho se pasẹ fawọn ọdaran kan laarin ẹya Fulani to n gbe lagbegbe Ibarapa lati ko aasa wọn, ti wọn ko ba dẹkun ipaniyan, ijinigbe ati ifipabanilopọ.

Awa kọ lo dana sun ile Seriki Fulani:

Akinpelu, nigba to n salaye lori isẹlẹ to waye nilu Igangan ninu eyi ti wọn ni awọn eeyan kan dana sun ile Seriki Fulani, Akinpelu ni awọn ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.

Akinpelu ni "lootọ ni inu n bi awọn ọdọ ilu naa, ti wọn si fẹ fi ẹhonu han, amọ a kilọ fun wọn pe wọn ko gbọdọ fa laasigbo kankan lẹsẹ, ki ijọba maa baa mu wọn."

Akipelu ni lẹyin ti Sunday Igboho ati ikọ rẹ kuro nilu naa, awọn pada lọ sọ fawọn ọlọpaa pe awọn ti setan, ti awọn si pada silu Ibadan.

O ni awọn ko mọ nipa ohunkohun to sẹlẹ mọ lẹyin rẹ.

Ki ni YCE sọ lori iwa ọdaran tawọn kan ninu ẹya Fulani n hu?

Wayi o, ẹgbẹ apapọ fawọn agbaagba nilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders, YCE, ti kesi aarẹ Muhammadu Buhari lati bawọn ọmọ orilẹede yii sọrọ lori wahala awọn ọdaran Fulani.

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ naa, Dokita Akin Olajide, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni iwa ika tawọn ọdaran kan ninu ẹya Fulani n hu ti pọ ju.

O fikun pe ihuwasi ati ọrọ tawọn amugbalẹgbẹ aarẹ kan n hu tabi sọ jade kan n bu epo p€triroolu si aawọ naa ni.

O ni ọpọ eeyan lawọn ọdaran Fulani ti ran sọrun ọsan gangan, wọn n fi tipa bawọn obinrin sun, ti wọn si tun ba ọpọ ire oko awọn agbẹ jẹ.

Olajide wa fi ọwọ gbaya pe iru awọn iwa ọdaran bẹẹ ko le tẹsiwaju, to si gba ijọba nimọran lati tẹẹ jẹjẹ nidi ete rẹ lati gbe Sunday Igboho si ahamọ.