Adewole Oniluola: Tunde Kelani ni ikú àgbà Àyàn náà tún mú kí ilẹ̀ Yorùbá sọ ohun rere nù

Gbajumọ ayan kan nilẹ Yoruba, to tun n lu ilu fun oloogbe Ayinla Omowura, gbajumọ akọrin Apala, ti jade laye ni alẹ ọjọ Isegun.

Ọdun mẹtadinlọgọrun lo lo loke eepẹ, ko to tẹri gbasọ.

Deede aago mẹwa owurọ ni gbajumọ onilu naa mi kanlẹ nile rẹ ladugbo Keesi nilu Abeokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oniluola jẹ ipe Ọlọrun lẹyin osu kan ti wọn se ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ eyi tawọn eeyan jankanjankan peju si.

Nigba to n fidi isẹlẹ iku baba Oniluola mulẹ fun BBC Yoruba, ilumọọka osere tiata kan, Tunke Kelani salaye pe aago mẹrin irọlẹ oni Ọjọru ni oloogbe naa yoo wọ kaa ilẹ sun.

O ni aarẹ agba lo pa Adewole, ọdun mẹta si lo ku ko pe ọgọrun amọ awọn dupẹ fun Ọlọrun pe o da ẹmi wọn si di akoko yii.

Awọn ipa wo ni Oniluola ko nigba to wa loke eepẹ?

Tunde Kelani ni ko si ẹni ti ko mọ pe oloogbe naa lo jẹ igi lẹyin ọgba fun ẹgbẹ osere Ayinla Omowura, Oniluola yii si lo ni ẹbun ilu lilu julọ ni agbaye.

"Ilu Oniluola ati ajọsepọ rẹ pẹlu Omowura lo jẹ ki Ayinla di ilumọọka, ti awọn mejeeji fi jọ ni okiki papọ.

Adewole nikan lo ku ninu awọn ti wọn dijọ wa ninu ẹgbẹ olorin Ayinla Omowura, gbogbo awọn eeyan yoku ti lọ.

Tunde Kelani ni ko tii pe osu kan ti awọn peju se ayẹyẹ ọjọ ibi fun Oniluola, ti awọn ko si mọ pe ọlọjọ ti n sunmọ.

Ipa wo ni iku Adewole Oniluola yoo ni lori iran Yoruba:

Kelani ni "Isẹlẹ yii n powe fun awa ọmọ Yoruba pe nnkan meremere ti Ọlọrun fun awa ọmọ Yoruba ti n lọ diẹdiẹ niyẹn.

O ni o se ni laanu pe awa taa wa lẹyin wọn ko wo awokọse awọn agbaagba yii lati le sọ pe nnkan ti awa naa ti gbe se ni eleyi.

Bi ere, bi ere awọn eeyan ti Ọlọrun fun ni ẹbun ilu lilu nilẹ Yoruba ti n lọ tan, ko si si awọn eeyan to maa gba ipo wọn."

O fikun pe ohun to jẹ ko se ni laanu pe iran Yoruba tun padanu Adewole ree.

Bakan naa lo ni iku oloogbe naa ti fi opin si saa igbe aye kan nilẹ Yoruba.

O wa gbadura pe Ọlọrun yoo dẹ ilẹ fun ẹni re to lọ naa.