You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ghana election: Ààrẹ Akufo-Addo la Mahama mọ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ Ghana fún sáà kejì
Aarẹ orilẹde Ghana, Nana Akufo-Addo ti wọlẹ ibo aarẹ ilẹ fun saa keji.
Ọga ajọ eleto idibo ilẹ Ghana, Jean Mensa lo kede pe Akufo-Addo la alatako rẹ, John Mahama mọlẹ ninu eto idibo naa.
Ọjọ Aje ni eto idibo naa tawọn ọmọ orilẹede Ghana ti tu yaya tu yaya jade dibo waye.
- Ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC jáwe lọ gbéle rẹ fún ìgbákejì alága: Hilliard Eta!
- Arábìnrin lẹ̀dì àpò pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pé kó ó jí òun gbe, ọ̀rẹ́kùnrin gba 700k tán ló bá sálọ
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Bíbéèrè fún ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà sọ ìyàwó ilé dèrò ilé ìwòsàn
- Ẹ ta kété sí àjọṣepọ̀ tí kò bá fún yín láyọ̀ torí ẹ̀mí kò ní ààrọ̀ - Àwọn òṣèré tíátà gbarata lórí ìdájọ́ ikú
- Rárá o, ẹ kò gbọdọ̀ sìnkú akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣe òògun owó - Ìjọba Eko yarí
Ta ni Nana Akufo- Addo to wọle ibo aarẹ Ghana lẹẹkeji?
Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1944 ni wọn bi Akufo-Addo ni Accra tii ṣe olu ilu orilẹede Ghana.
Ọgbẹni Akufo-Addo kii ṣe aimọ fuloko lagbo oṣelu orilẹede Ghana.
O ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro agba orilẹede Ghana laarin ọdun 2001 si ọdun 2003.
Bakan naa ni Akufo-Addo jẹ minisita ọrọ ilẹ okeere laarin ọdun 2003 si 2007 labẹ aṣẹ Aarẹ John Kuffour.
Oun si ni alaga ajọ ECOWAS to n ri si ọrọ aje awọn orilẹede to wa ni iwọ oorun ilẹ Afirika bayii.
Afo-Addo ti kọkọ dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NPP lọdun 2008 ati 2012 ṣugbọn o fidi rẹmi lẹẹ mejeeji.
Lọjọ kẹsan an oṣu kejila ọdun 2016 ni Akufo-Addo tun gbegba ibo aarẹ ninu eyi to ti fẹyin aarẹ Johna Mahama to wa lori oye gbalẹ ti o si wọle.
Mahama naa lo tun fidi rẹmi bayii lẹyin nti Akufo-Addo wọle fun saa keji.