You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Trump news: Biden tun fẹyin Trump gbolẹ ninu atunka ibo to waye ni Georgia
Ijawe olubori Joe Biden tun ti f'ẹsẹ rinlẹ sii pẹlu bo ti ṣe tun fìdí aarẹ Trump janlẹ ninu atunka ibo to waye ni Georgia.
Nipinlẹ mẹta ni wọn ti f'ọwọ rọ ẹjọ ti Trump pẹ lori abajade ibo ti Biden ti kogo ja.
Ninu atunka ibo to waye ni Georgia yi ibo 12284 ní o fi ju ti alatako rẹ ninu ẹgbẹ Republican gẹgẹ bi ofin ayẹwo ti ṣe sọ.
Ọgbẹni Biden sọ pe o da oun loju pe Ọgbẹni Trump mọ pe oun ko ni pegede ninu ibo naa to sì hu iwa ti ko bojumọ latari rẹ.
Biden to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Democrat n palẹmọ lati gba ibura wọlé sipo loṣu Kini ọdun gẹgẹ bi aarẹ ikẹrindinlaadọta orileede Amẹrika.
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
- Ẹ̀tanú pé Olùṣọ́ Genesis kò fẹ́ Laide Williams-Oni ló ṣe rán an lọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan - CCC Genesis Global
- CNN tako Lai Mohammed, a dúro bí iké lẹ́yìn ìròyìn táa gbé jáde nípa Lekki Tollgate
- Ẹ̀ṣọ Gbajabiamila yìnbọn pa fẹ́ńdọ̀ kan l'Abuja, àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ fẹ ṣe iwọde
Apapọ ibo ti Biden fi ya Trump wa ni mílíọ̀nù marun un lé diẹ.
Ni ti ibo Electoral College a n fojú sun pe yoo to 306 sí 232 ti aarẹ Trump.
Electoral College yi ni Amẹrika n lo lati fi yan ẹni tí yoo dipo aarẹ mu.
Ki lọ ṣẹlẹ ni Georgia?
Ni Ọjọbọ lakọwe ipinlẹ Georgia, Brad Raffensperger, sọ pe atunka ibo to waye ko yí iye aṣeyọri ti Biden ṣe ni Georgia pada.
Ninu atẹjade tó fi sita o ni "Atunka ibo manigbagbe to waye ni Georgia tunbọ fidi ọrọ mu'lẹ pe ilana idibo tuntun tá samulo ka to si tun gbe ojulowo esi ibo jade"
O salaye pe "Aṣeyọri eyi jẹ fún iṣẹ ribi ribi t'awọn oṣiṣẹ eto idibo labẹle ati jakejado Amẹrika se lati pari isẹ nla yi lasiko perete"
Atunka ibo yi fihan pe iyato to waye laarin aṣeyọri Biden lẹyin atunka ati ti tẹlẹ ko ju ida
0.73% lawọn agbegbe kọọkan ti ti ọgbẹni Trump ko si to 0.5%.
Lọjọ Ẹti ni wọn yoo fontẹ lu esi naa.
Trump gba iṣẹ́ lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó ní kò sí màgòmágó nínú ìdìbò Ààrẹ Amẹrika
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump, ti jawe lọ rọkun nile fun oṣiṣẹ rẹ kan to tako pe ko si magomago ninu idibo Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ di laipẹ yii.
Trump ni oun gbaṣẹ lọwọ ọkunrin ọhun, ti orukọ rẹ n jẹ Chris Krebs, fun ọrọ to sọ lori aṣemaṣe to waye ninu idibo naa.
Lati igba ti ẹkọ ti n foju mimu han pe Joe Biden ni yoo jawe olubori ninu idibo naa ni ọgbeni Trump ti n funrere pe idibo ọhun lọwọ magomago ninu.
Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ilẹ Amẹrika ti sọ pe idibo Aarẹ ọdun 2020 lo lamilaaka julọ ninu itan orilẹ-ede Amẹrika.
Trump gbaṣẹ lọwọ Krebs lẹyin to ti kọkọ jawe lọ rọkun nile fun adari ileeṣẹ eto abo, Mark Esper lẹyin ti iroyin kan sọ pe Aarẹ Trump ko le fọkan tan mọ.
- Ta ni Kamala Harris obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbá-kejì ààrẹ orílẹ̀èdè Amẹrika?
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
- US election 2020: Bi kò tilẹ̀ wọlé, ẹ wo ayípadà tí Ààrẹ Trump mú bá awọn orilẹede ní àgbáyé
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
Awọn kan tilẹ ti n sọ pe Trump yoo tun gbaṣẹ lọwọ ọga agba ajọ CIA, Gina Haspel ati ọga agba ajọ FBI, Christopher Wray, ko to fi ọọfisi Aarẹ silẹ loṣu kinni ọdun 2021.
Gẹgẹ bi awọn ti Trump ti jawe lọ rọkun jile fun ṣaaju, oju opo Twitter ni Krebs ti gbọ pe iṣẹ ti bọ lọwọ oun.
Lẹyin to gbọ pe Aarẹ ti gbaṣẹ lọwọ rẹ, Krebs sọ loju opo Twitter tirẹ pe oun ko kabamọ kankan, ati pe inu oun dun lati sin orilẹ-ede oun.